Audu Ogbeh

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Audu Ogbeh
Minister of Agriculture and Rural Development
In office
11 November 2015 – 28 May 2019
ÀàrẹMuhammadu Buhari
Minister of StateHeineken Lokpobiri
AsíwájúAkinwumi Adesina
Arọ́pòSabo Nanono
National Chairman of the Peoples Democratic Party
In office
2001–2005
AsíwájúBarnabas Gemade
Arọ́pòAhmadu Ali
Federal Minister of Communications
In office
1982–1983
ÀàrẹShehu Shagari
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Audu Innocent Ogbeh

28 Oṣù Keje 1947 (1947-07-28) (ọmọ ọdún 76)
Otukpo, Northern Region, British Nigeria (now in Benue State, Nigeria)
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress (2015–present)
Other political
affiliations
(Àwọn) olólùfẹ́married 1975
Àwọn ọmọ5, including Ogwa Iweze
Alma mater
Occupation
  • Politician
  • farmer
  • playwright

Audu Innocent Ogbeh tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù keje ọdún 1947, jẹ́ ònkọ̀tàn, òṣìṣẹ́ àgbẹ̀ àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti mínísítà fún ètò ọ̀gbìn ní láàrín ọdún 2015 sí ọdún 2019 orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí lábẹ́ ìṣèjọba ààrẹ ajagun-_fẹ̀yìntì Muhammadu Buhari. [1][2] Òun ni Alága àgbà fún ẹgbẹ́ ìṣèlú He was chairman of the Peoples Democratic Party (PDP) láàrín ọdún 2001 títí di ọdun 2005. Ó ṣisẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mínísítà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́kejì láàrín ọdún 1982 sí 1983. Bákan náà ni Audu ti ṣe àpilẹ̀kọ àwọn ìwé eré oníṣe pàtinúdá márùnún, ní èyí tí wọ́n sì ti fi ìkan nínú àwọn ìwé eré oníṣe rẹ̀ Epitaph of Simon Kisulu ṣeré lórí ìtàgé ní ní gbọ̀ngàn Muson Center ní ọdún 2002.[3]

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ogbeh ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1947 ní Ó wá láti apá ẹ̀yà Idomaìpínlẹ̀ Benue . Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ King's Collegeìpínlẹ̀ Èkó ní àárín ọdún 1967 sí ọdún 1969, ó tún kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Ahmadu Bello University, ní ìpínlẹ̀ Zaria láàrín ọdún from 1969 sí ọdún 1972 àti ilé-ẹ̀kọ́ University of Toulouse, ní orílẹ̀-èdè Faransé láàrín ọdún 1973 sí ọdún 1974. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìkọ́ni ní ilé-ẹ̀kọ́ Ahmadu Bello University, Zaria ní ìlú láarín ọdún 1972 sí ọdún 1976, ó sì tún ṣe adarí ẹ̀kọ́ ìfọmonìyàn ṣe ní ẹ̀kọ́ Murtala College of Arts, Science and Technology láti ọdún 1977 sí ọdún 1979.[1]

Ipa rẹ̀ nínú ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1979, ó díje sípò aṣòfin ní Ìpínlẹ̀ Benue lábẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ òṣèlú National Party of Nigeria (NPN), tí ó sì di igbákejì adari ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Ìpínlẹ̀ náà lásìkò rẹ̀. Ní ọdún 1982 ni wọ́n yànán gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn èyí nj wọ́n tún yàn án sípò Mínísítà tí ó ń rí sí ìdàgbà-sókè ìpèsè Irin ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó kúrò ní ipò ní inú oṣù ìkejìlá ọdún 1983 nígbà tí ìjọba ìdìtẹ̀-gbàjọba tí ó gbé ajagun-fẹ̀yìn-tì Muhammadu Buhari dépò. [1]

Wọ́n yàn án sípò alákòóso àgbà fún ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí ó rọ́pò olóyè Barnabas Gemade ní ọdun 2001. Ó lo ipò yí fún ọdún márùnún nígbà tí ó kúrò nibẹ̀ ní ọdún 2005 lẹ́yìn tí bínú fipò sílẹ̀ látàrí yíyọnu tí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Olusegun Obasanjo ń yọnu si lásìkò ìṣèjọba tirẹ̀ lórí ọwọ́ tí ó fi mú aápọn tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Anambara nígbà náà.[1] Aufu fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yí múlẹ̀ nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wipé òun mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí òun kò fẹ́ kí wàhálà ó bẹ́ sílẹ̀ láàrín ẹgbẹ́ ni, àti wípé ó ti wu òun kí òun padà sí ẹnu iṣẹ́ àgbẹ̀ [4]

Iṣẹ́ rẹ̀ yàtọ̀ sí ìṣèlú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní inú oṣù ìkejìlá ọdún 2005, Audu kọ̀wé fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ [5] Ní ọdún 2009, òun ni alága àti olùdarí Efugo Farms, tí ó wà ní ìlú Makurdi. Ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Eisenhower Exchange Fellowships Incorporated, tí ó wà ní ìlú Philadelphia, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà [6]

Àwọn itọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 Tokunbo Adedoja (11 January 2005). "The Man Ogbeh". OnlineNigeria. Archived from the original on 27 February 2012. Retrieved 21 March 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "18 former ministers who didn't make Buhari's new list". Retrieved 2019-07-31. 
  3. Fuidelis Njoku. "Reliving Apartheid On Stage." P.M. News (Lagos) 17 Apr. 2002
  4. Jide Ajani; Sufuyan Ojeifo; Bolade Omonijo; Paul Odili (January 11, 2005). "Why I resigned, by Audu Ogbeh". Vanguard. Retrieved 2010-03-21. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]Àdàkọ:Cbignore
  5. CHRISTIAN ITA (December 18, 2005). "Ogbeh, Rimi, Na'Abba others resign from PDP at last". Online Nigeria. Archived from the original on 21 July 2011. Retrieved 2010-03-21. 
  6. Kazeem Akintunde; Belinda Mbonu (19 July 2009). "In The News: Audu Innocent Ogbeh". Newswatch. Retrieved 2010-03-21.  Unknown parameter |name-list-style= ignored (help)