Barbara Soky

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Barbara Soky
Ọjọ́ìbíBara Sokoroma
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́òṣèré . akọrin
Àwọn ọmọ1

Barbara Soky (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ jẹ́ Bara Sokoroma ) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti akọrin tẹ́lẹ̀rí tí ó di gbajúmọ̀ lẹ́hìn kíkópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mirror in the Sun. Ó sinmi iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipa ní àwọn ọdún 80 àti 90, kí ó tó padà sí ní bá iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ lọ nísẹ̀yín. Ó ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ hàn nínu àwọn sinimá àgbéléwò Nollywood àti àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù.[1]

Iṣẹ́ òṣèré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkọ́kọ́ ipa gbòógì tí Soky kó wáyé nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Inside Out èyí tó jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ lóri ìkànnì NTA. Soky tún ti kópa pẹ̀lú Adiela Onyedibia nínu eré You Can't Take Your Wife to New York, eré kan tó dá lóri aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tó fẹ́ ìyàwó aláìkàwé kan. Lẹ́hìn tí eré Inside Out parí, Soky gbéra láti Ìpínlẹ̀ Rivers lọ sí Ìlú Èkó níbití ó ti padà wá kópa nínu eré Mirror in the Sun tí Lọlá Fàní-Káyòdé ṣe. Ipa rẹ̀ tí ó kó nínu eré kan gẹ́gẹ́ bi Yínká Fáwọlé ṣokùn fa kíkàn òkìkí rẹ̀ tó sì di ìlúmọ̀ọ́ká, débi pé ó padà wá ṣe ìpolówó ọjà fún ilé-iṣẹ́ Jik. Soky jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkópa àkọ́kọ́ ti eré Ripples láti ọdún 1988 sí 1993.[2][3]

Lẹ́hìn ìsinmi ọlọ́dún mẹ́tàlá rẹ̀ nídi iṣẹ́ òṣèré, Soky padá sí ìdi iṣẹ́ òṣèré pẹ̀lú kíkópa nínu eré Amaka Igwe kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Solitaire gẹ́gẹ́ bi Nkoyo Broderick, obìrin kan tó pinnu láti dáàbò bo ọrọ̀ ẹbí rẹ̀.[4]

Iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1986, Soky ṣe àgbéjáde àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní Going Places láti ilé iṣẹ́ Mercury Records.[5]

Àwọn ìyẹ́sí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2013 Soky gba àmì ẹ̀yẹ ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ 2013 Nollywood Movies Awards fún iṣẹ́ takuntakun rẹ̀ nínu fíìmù Bridge of Hope.[6] Ní ọdún 2014 ó tún rí yíyàn fún àmì ẹ̀yẹ yìí kan náà níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards fún ti ipa rẹ̀ nínu fíìmù Brothers Keeper.

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Soky bí ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Maxine.[7]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Wicked people put my life in jeopardy.........Barbara Soky". modernghana.com. Retrieved 14 August 2014. 
  2. "Acting’s my calling, so I am back and better –Barbara Soky". mydailynewswatchng.com. Archived from the original on 4 September 2014. Retrieved 14 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "My Regrets as an actress - Barbara Soky". nationalmirroronline.net. Archived from the original on 12 December 2012. Retrieved 14 August 2014. 
  4. Barbara Soky is Back
  5. Barbara Soky Going Places
  6. "#NMA2013: Nollywood Movies Awards 2013 (Winners – Complete Full List)". 360Nobs.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-10-13. Retrieved 2019-09-26. 
  7. [1]