Cynthia Erivo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Cynthia Erivo
Erivo níbi ayẹyẹ Tribeca Film Festival lọ́dún 2018
Ìbí8 Oṣù Kínní 1987 (1987-01-08) (ọmọ ọdún 37)
Stockwell, London, England
Iṣẹ́Actress, singer, songwriter

Cynthia Onyedinmanasu Chinasaokwu Erivo ( /əˈrv/;[1] tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹjọ oṣù kìíní ọdún 1987 jẹ́ Òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò, olórin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè England, ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ Nàìjíríà pọ́ńbélé. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmìn-ẹ̀yẹ, pàápàá jù lọ àmìn-ẹ̀yẹ Emmy, Tony, àti Grammy, bẹ́ẹ̀ náà Wọ́n tí yàn án fún Academy Awards

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn òbí Erivo jẹ́ ọmọ bíbí Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí wọ́n lọ gbé ní agbègbè StockwellLondon orílẹ̀-èdè United Kingdom.[2] Her mother is a nurse.[3] Ó kàwé ní La Retraite Roman Catholic Girls' School. Erivo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ gíga yunifásítì nínú ìmọ̀ èrò orin ní University of East London; lẹ́yìn ọdún kan tí ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, ó kọ̀wé láti kopa nínú,[4] wón kó ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní Royal Academy of Dramatic Art.[5]

Iṣẹ́ tíátà rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Erivo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 2011 nínú eré ìtàgé tí wọ́n pè ní The Umbrellas of Cherbourg, bẹ́ẹ̀ ó kọ́kọ́ farahàn nínú ẹ̀rọ tẹlifíṣán ní Englandnínú ètò tí wọ́n pè ní Chewing Gum lọ́dún 2015. Ó di gbajúmọ̀ nínú ipa tó kó nínú sinimá Broadway, The Color Purple láti ọdún 2015 sí 2017, àkókò yìí ló gbàmìn-ẹ̀yẹ Tony Award for Best Actress in a Musical ní 2016 àti Grammy Award for Best Musical Theater Album, pẹ̀lú àwọn àmìn-ẹ̀yẹ mìíràn. Ó bẹ̀rẹ̀ sinimá àgbéléwò lọ́dún 2018 nígbà tó kópa nínú sinimá Widows àti Bad Times at the El Royale. Erivo kópa Harriet Tubman nínú sinimá Harriet lọ́dún 2019, lórí ipa yìí, ó gbàmìn-ẹ̀yẹ Academy Award fún Òṣèrébìnrin tó dára jù lọ àti orin ara ẹni tó dára jù lọ. Lọ́dún 2020, Erivo kópa nínú sinimá àgbéléwò tí wọ́n pè ní The Outsider.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Cynthia Erivo Explores ASMR". W. 12 October 2018. Retrieved 20 April 2019. 
  2. Wolf, Matt (17 July 2013). "A Star Is Born! Meet Cynthia Erivo, Who Plays Celie in John Doyle's London Premiere of The Color Purple". Theatre.com. Retrieved 19 June 2016. 
  3. "Cynthia Erivo Reveals How She Accessed Sadness to Portray Harriet Tubman". O, The Oprah Magazine. 28 October 2019. Retrieved 16 August 2020. 
  4. John, Emma (27 July 2015). "Move over Whoopi! How Cynthia Erivo made The Color Purple her own". The Guardian. Retrieved 13 December 2015. 
  5. Bosanquet, Theo (19 November 2014). "Leading Ladies: Cynthia Erivo 'I want to do everything'". What's On Stage. Retrieved 13 December 2015.