Dodo ikire

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán dòdò Ìkirè

Dòdò Ìkirè jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ láti ìlú Ìkirè ní Gúúsù-ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ilẹ̀ Nàìjíríà. Láti ilẹ̀, àjẹkù ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ni wọ́n máa ń lò ṣùgbọ́n ní òní, àwọn ènìyàn ti ń lo èròjà ọ̀tun fi ṣe é tíí ṣe: ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tí ó ti pọ́n torí-tìdí, ata, epo àti iyọ̀. Dòdò Ìkirè dúdú, ó sì tún yí roboto tàbí onígun òkòtó. Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dòdò, èyí tí wọ́n ti bó èèpo rẹ̀, tí wọ́n gé tí wọ́n sì dín dáadáa ni wọ́n ń pè ni dòdò ní àwọn apá ibìkan ní Nàìjíríà. Akọni fi hàn pé Dòdò Ìkirè wáyé láti ara àyẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ aláìní, iyá arúgbó láti ìlú tí wọ́n ńpè ní ìkirè. Ìkirè jẹ́ ìlú kan ní gúúsù ìlà-oòrùn agbègbè Nàìjíríà láàrin ìlú Ìbàdàn sí ìlú Ilé-ifẹ̀, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[1] Ìyá arúgbó yìí kòní oúnje àyàfi ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àpọ́nrà, èyí tí óbá tiká lára rẹ̀ dànù, àmọ́ ó pinu láti se ọ̀pọ̀ míràn kí ó sì pin fún àwọn aláàdúgbò rẹ̀.[2] Àpẹ̀yìndà rẹ̀ ni ohun tí amọ̀ sí dòdò ìkirè, orúkọ tí ó wáyé láti ìlú tí ó ti sẹ̀ wá. Wọ́n máa ń sáábà tà á ní Gúúsù-ìlà oòrùn apá Nàìjíríà.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Dodo Ikire: A town’s plantain delicacy to motorists, travelers". Tribune Online. 2017-08-29. Archived from the original on 2018-08-09. Retrieved 2018-12-11. 
  2. "Dodo Ikire goes Chic – a great idea to work with overripe plantains". Dooney's Kitchen – Promoting and Redefining New Nigerian Food. 2015-04-08. Archived from the original on 2018-12-25. Retrieved 2018-12-11.