Ejiro Amos Tafiri

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ejiro Amos Tafiri
Tafiri lọ́dún 2016
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Iṣẹ́
  • Aránṣọ
Gbajúmọ̀ fún
  • lṣẹ́ aṣọ ríran ìgbàlódé
Àwọn ọmọ2

Ejiro Amos Tafiri jẹ́ gbajúmọ̀ aránṣọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ aránṣọ, E. A. T. tí ó dá sílẹ̀ láti máa ránṣọ ìgbàlódé àwọn obìnrin.[1]

Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ejiro jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Delta, ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí Ìpínlẹ̀ Èkó.[1] Láti kékeré lọ́mọdún mẹ́ta ló ti nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ aránṣọ nípasẹ́ ìyá rẹ̀ àgbà tí wọ́n jẹ́ aránṣọ .[2] Àwọn òbí rẹ̀ fẹ́ kí kàwé gboyè Dókítà òyìnbó, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ó lọ kàwé gboyè nínú ìmọ̀ aṣọ àti aṣọ rírán ní Yaba College of Technology.

Ọdún 2010 ni Ejiro dá ẹ̀yà ìránṣọ̀ tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pé ní È. A. T.[1] Lọ́dún 2015, ẹ̀yà ìránṣọ̀ rẹ̀ E.A.T, tí wọ́n tún sọ ní “The Madame”, ṣe àfihàn níbi ìpàtẹ aránṣọ ìgbàlódé tí wọ́n ṣe ní ọ̀sẹ̀ ìpàtẹ aránṣọ ìgbàlódé ní Port Harcourt àti Kenya.[3]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 Kemi Amushan. "Ejiro Amos Tafiri: The E. A. T. Brand". The Guardian. Retrieved 25 July 2016. 
  2. Olamide Olanrewaju. "My First encounter with fashion was at 3" - Fashion Designer". Pulse .ng. Retrieved 25 July 2016. 
  3. Jennifer Obiuwevbi. "Glam Overdose! Ejiro Amos Tafiri’s 2015 Luxury Resort Collection – “The Madame”". Bella Naija. Retrieved 25 July 2016.