Felix idubor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Felix Idubor
Ilẹ̀abínibí Nigerian
Movement Benin, Tourist Art Contemporary African Art

Felix Idubor (1928–1991) jẹ́ agbẹ́gilére Nàìjíríà láti ìlú Benin, ìlú kan tí ó ní ìtàn tí ó lọ́ọ̀rìn nípa ìmọ̀ọ́ọ́ṣe iṣẹ́-ọnà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ kékeré àwọn oníṣẹ́-ọnà ní àárín 1950 àti 1960 tí wọ́n ṣe igbéǹde ìdálẹ́kọ̀ọ́ mímọ̀ nípa iṣẹ́-ọnà ìṣe Áfíríkà ní dídé àti ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ ènìyàn àyíká. Wọ́n máa ń gbé e wò ní àwọn ìgbà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ iṣẹ́-ọnà ìgbàlódé Nàìjíríà . Ní 1966, ó ṣí ilé-ìṣàfihàn iṣẹ́-ọnà ìgbàlódé àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà sí òpópónà Kakawa, Èkó.

Ó yege gan-an nínú gbígbẹ́ àṣè, ó sì ní àṣẹ láti máa gbẹ́ àṣè fún àwọn ilé-iṣẹ́ ńláńlá àti àwọn ènìyàn bí àpẹẹrẹ ilé ilé-ìfowópamọ́ Cooperative ní Ìbàdàn àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Èkó.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbésí-ayé àti ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Felix Idubor sínú ìdílé àgbẹ̀ ní ìlú Benin. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́gilére ní àti kékeré, ṣùgbọ́n ó rí àwọn àtakò kan láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ tí ó lérò pé gbígbẹ́ ilé rẹ kì í ṣe iṣẹ́ tí í mówó wọlé. Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Benin ṣùgbọ́n ó gba ìsinmi nínú ìwé kíkà nígbà tóyá láti lè gbájúmọ́ ohun tí ó rò pé ó jẹ́ iṣẹ́ àdámọ́ rẹ̀, gbígbẹ̀gilére. Àkórí iṣẹ́-ọnà rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó yàn dálé àwọn ẹyẹ tí wọ́n gbẹ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti ara Ìrókò igi tí ó pọ̀ ní Benin.[1] Ó tún lo àwọn igi láti ara ìrókò gẹ́gẹ́ bí i ohun èlò iṣẹ́ ní àwọn iṣẹ́ gbígbẹ́gilére ó sì yege nínú ọ̀nà tí ó yàn. Nígbà tí yóò fi pé ẹni ọdún ẹ̀tàdínlọgún, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Edo College ní Benin pẹ̀lú ìwọ̀nba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àìgbẹ̀fẹ̀..[2]

Ní òpin àárín 1950, ó jẹ́ ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ní Royal College of Art, London lẹ́yìn tí iṣẹ́ rẹ̀ gba ìyìn pàtàkì nígbà ìṣàfihàn kan tí ó wáyé papọ̀ pẹ̀lú ìrìn àjò Queen Elizabeth's sí Nàìjíríà.

  1. Y. A. Grillo; Juliet Highet. 'Felix Idubor', African Arts, Vol. 2, No. 1 (Autumn, 1968), p. 34.
  2. Grillo and Highet p. 31.