Kọ́lá Òyéwọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Kọ́lá Òyéwọ̀ (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù kẹta ọdún 1946) jẹ́ àgbà òṣèré sinimá àgbéléwò àti olùkọ́ ilé ìwé Ifáfitì ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò lóríṣiríṣi. Sinimá kan gbòógì tó gbé ìràwọ̀ rẹ̀ jáde ní "Orogún Adédigba" Bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ tíátà náà ló ń ṣíṣe olùkọ́. Ó ti jẹ́ olùkọ́ ní ifáfitì Ọbáfẹ́mi Awolọ́wọ̀ tí wọ́n ń pè ní Obafemi Awolowo University, O.A.U., ní Ilé-Ifẹ̀, Redeemer's University, ní ìlú Ọ̀tà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, bẹ́ẹ̀ náà ní Elizade University Ilara-Mokin, ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.[1] [2] [3]

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Olóyè Kọ́lá Òyéwọ̀ sí ìlú Ọ̀bà-Ilé ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lỌjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù kẹta ọdún 1946. Àkọsílẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìgbà èwe rẹ̀ farasin, ṣùgbọ́n ó kàwé gboyè nínú iṣẹ́ tíátà àti lítíréṣọ̀ a lóhùn èdè Yorùbá ní ifáfitì Ọbáfẹ́mi Awolọ́wọ̀ ní Ilé-Ifẹ̀ lọ́dún 1995. Ó tẹ̀ síwájú ní ifáfitì ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti kàwé gboyè dìgírì kejì àti oyè ọ̀mọ̀wé dọ́kítà nínú iṣẹ́ tíátà.[4]

Àtòjọ àwọn sinimá àgbéléwò tí Kọ́lá Òyéwọ̀ tí kópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Sango (1997)
  • Super Story (episode 1)
  • The Gods Are Not To Blame
  • Saworo Ide
  • Koseegbe (1995 [5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Kola Oyewo biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1946-03-27. Retrieved 2019-11-29. 
  2. "Kola Oyewo Archives - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2019-11-29. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "Veteran actor, Kola Oyewo is 70 years old today - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 2016-03-27. Retrieved 2019-11-29. 
  4. Julius-Adeoye, Rantimi (2015-08-03). "The Actor and the Character: A Study of Kola Oyewo As James Adubi in Family Ties". The Stage and The Screen: Perspective on Arts Production in Contemporary Nigeria. https://www.academia.edu/40956603/The_Actor_and_the_Character_A_Study_of_Kola_Oyewo_As_James_Adubi_in_Family_Ties. Retrieved 2019-11-29. 
  5. "Kola Oyewo". MUBI. Retrieved 2019-11-29.