Ladi Kwali

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìkòkò orù tí Ladi Kwali fọwọ́ ṣe (YORYM-2004.1.919)
Ladi Kwali
Ladi Kwali
Ladi Kwali
Ọjọ́ìbíLadi Kwali
Àdàkọ:Birth year
Kwali, Nigeria
Aláìsí12 August 1984(1984-08-12) (ọmọ ọdún 58–59)
Iṣẹ́potter

Ladi Kwali, OON, MBE (c.1925– August 12, 1984)[1] jẹ́ amọ̀kòkò àti onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ladi Kwali ni wọ́n bí ní abúlé kan tí ó ń jẹ́ Kwali ni agbègbè Gbwari ní apá òkè ọyà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ìlú tí ìkòkò ṣíṣe ti jẹ́ iṣẹ́ òójọ́ fún àwọn obìrin wọn.[2] Ladi kọ́ bí wọ́n ṣe ń Mọ ìkòkò láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọdé lọ́dọ̀ ìkan lara àwọn mọ̀lẹ́bí bàbá rẹ̀. Ìlànà coiling ni wọ́n ń ló láti fi Mọ ìkòkò nígbà náà. Ladi ni ó ti lo ìṣeẹ́ ọwọ́ rẹ̀ yí láti fi ṣe àwọn ohun èlò ilé bíi: ìkòkò orù, ìkòkò àmù, ìkòkò ọbẹ̀ láti inú amọ̀ tí wọ́n pò pọ̀. Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ yí ni ó ṣe ọ̀ṣọ́ oríṣiríṣi sí pẹ̀lú àwọn àwòrán onírúurú bíi akekèé, alàgbà, ọ̀ọ̀nì, ejò, àyà ẹja àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3] Gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ tí a mẹ́nu bà wípé ó ma ń ṣe sí ara àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ yí ni ó ma ń fi dárà lẹ́yìn tí ó bá ti sun amọ̀ náà nínú iná tí ó sì ti di ìkòkò ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń ṣe ìkòkò ní Kwali. Ọnà ìṣe ìkòkò Ladi ni ó mu di gbajú-gbajà àmọ̀-kòkò nílé àti lókè òmun. [4] Púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ni ìkan lára àwọn Ọba àwọn Hausa ní ìlú Àbújá ìyẹn Alhaji Suleiman Barau,[5] ń sábà ma ń fowó rà nígbà ayé rẹ̀.

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ladi ni ìlú Kwali tí ó jẹ́ abúlé kékeré kan kanẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Kwali ní ìlú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1925, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn oniọ̀tàn kan jiyàn wípé ọdún 1920 ni wọ́n bi. [6]). Ladi dàgbà sí agbolé tí wọ́n ti mú iṣẹ́ ìkòkò mímọ lọ́kùnkúndù fún awọ ọmọ obinrin wọn. [6] Mallam Mekaniki Kyebese, tí ó jẹ́ àìtẹ̀lé sọ wípé "púpọ̀ nínú àwọn íkòkò tí Ladi bá mọ ni àwọn ọlọ́jà tí .a ń wá ràá ṣáájú kí ó tó kò wọnọ sọ́jà, nítorí ẹ̀bùn ìṣọwọ́ mọ ìkòkò tìrẹ̀ yàtọ̀ láàrín àwọn amọ̀kòkò ìgbà náà."[6]

Ìkòkò tí Ladi Kwali mọ tí ó sì fi ọ̀ṣọ́ dárà sí; W.A. Ismay Studio Ceramics Collection, York Art Gallery

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Michael Cardew, tí ó jẹ́ aṣojú ìjọba Britain fún àw ọn ohun tí ó jẹ mọ́ ètò okòwò ati ọrọ̀-ajé pàá pàá jùlọ iṣẹ́ ọnà ìkòmò mímọ ní ọdún 1951, dá ilé iṣẹ́ ìkòkò mímọ sílẹ̀ ní ìlú Suleja ní inú oṣù Kẹrín ọdún 1952. [7] In 1954, Ladi Kwali joined the Abuja Pottery as its first female potter.[8]Ilé-ẹ̀kọ́ yí ni Ladi ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo òyìgì tí a mọ̀ sí (wheel), gílésìnì, bí wọ́n ṣe ń pèsè sagar ati bí wọ́n ṣe ń lo slip, tí ó sì ti ibẹ̀ di olùkọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kú.[7] Gẹ́gẹ́ bí ìkòkò mímọ ṣe jẹ́ ìṣeẹ́ abínibí fún àwọn obinrin ní Kwali,ìlú tí wọ́n ti bí Ladi, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni ó di àwòdami ẹnu àti ohun ọ̀ṣọ́ ilé. [9]Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ni wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ ní ibi ìdíje iṣẹ́ ọnà jákè-jádò agbáyé bíi: international exhibitions of Abuja pottery ní ọdún 1958, 1959, àti 1962, ìdíje tí ọ̀gbẹ́ni Cardew gbé kalẹ̀. Ní ọdún 1961, Kwali patẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní ibi ìpatẹ iṣẹ́ ọnà ní" Royal College, Farnham, and Wenford Bridge ní ìlú Britain.[2] Bákan náà ni ó tún patẹ iṣẹ́ rẹ̀ ní ibi ìpàtàẹ iṣẹ́ ọnà ní ìlú Farasé àti Germany. Ní ọdún1972, òun ati onígbọwọ́ Cardew rin ilẹ̀ Amẹ́ríkà kọjá nígbà tí wọ́n ń pátá iṣẹ́ ọwọ́ Ladi káàkiri agbáyé. Wọ́n fi iṣẹ́ ọwọ́ Ladi han ní ilé ọ̀ṣọ́ ti Berkeley Galleries ní ìlú London.[10] Wọ́n sọ ilé-iṣẹ́ ọnà àti ìkòkò mímọ tí ó wà ní ìlú Àbújá ní Ladi Kwali Pottery ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1980.

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ àti àṣeyọrí rẹ̀ lọ́kan-ò-jọ̀kan[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ladi gba amì-ẹ̀yẹ MBE (Member of the Order of the British Empire) ní ọdún 1962.[11]

Wọ́n fu ní amì-ẹ̀yẹ ọ̀mọ̀wé ní ilé-ẹ̀kọ́ fásitì ti Ahmadu Bello University ní Zaria lọ́dún 1977[12]

Ní ọdún 1980, ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, apápọ̀ ìgbìmọ̀ ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà fi amì-ẹ̀yẹ Nigerian National Order of Merit Award (NNOM) da lọ́lá,[13] the highest national honour for academic achievement.[12] Ó tún gba amì-ẹ̀yẹ ti ti Order of the Niger (OON) ní ọdún 1981.[12] Ìjọba apápọ̀ tún fi àwòrán rẹ̀ sí ẹ̀yìn ogún náìra N20 owó ilẹ̀ Nàìjíríà láti lè máa fi ṣe.ìrántí rẹ̀ títí láé.[12] Wọ́n tún sọ ojú ọ̀nà kan tí ó wà ní ìlú Àbújá ní orúkọ rẹ̀ Ladi Kwali Road.[12] Ilé ìtura ti The Sheraton Hotel, tí ó wà ní ìlú Àbújá náà sọ gbọ̀gan kan tí ó tóbi jùlọ níbẹ̀ sọrí Ladi Kwali.[12]

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "15 Facts about Ladi Kwali: The Pottery Woman on N20 Note - ThisTrend Blog". 2017-03-17. Archived from the original on 2017-03-17. Retrieved 2018-08-06.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. 2.0 2.1 Vincentelli, Moira (2000). Women and Ceramics: Gendered Vessels. Manchester, UK: Manchester University Press. pp. 58–76. ISBN 978-0719038402. https://archive.org/details/womenceramics00moir/page/58. 
  3. Cardew, Michael (April 1972). "Ladi Kwali: The Potter from England Writes on the Potter from Africa". Craft Horizons (32): 34–37. 
  4. Thompson, Barbara (6 February 2007). "Namsifueli Nyeki: A Tanzanian Potter Extraordinaire". African Arts 40 (1): 54–63. doi:10.1162/afar.2007.40.1.54. ISSN 0001-9933. 
  5. "History of Ladi Kwali, the Famous Nigerian Potter". Abuja Facts. 8 February 2015. Archived from the original on 7 January 2016. Retrieved 18 January 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. 6.0 6.1 6.2 Okunna, E. (1 January 2012). "Living through two pottery traditions and the story of an icon: Ladi Kwali". Mgbakoigba: Journal of African Studies 1. ISSN 2346-7126. http://www.ajol.info/index.php/mjas/article/view/117190. 
  7. 7.0 7.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :2
  8. Ladi Kwali, Nigerian Potter, retrieved 18 January 2016 
  9. Reed, Lucy (1 January 2002). "Review of Women and Ceramics: Gendered Vessels". Studies in the Decorative Arts 9 (2): 159–163. doi:10.1086/studdecoarts.9.2.40663018. JSTOR 40663018. 
  10. Archive, Aberystwyth Ceramics Collection and. "Ladi KWALI (Nigeria) The Ceramic Collection Ceramic Collection and Archive – Aberystwyth University of Wales 27 March 2016". ceramics-aberystwyth.com. Archived from the original on 7 April 2016. Retrieved 27 March 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  11. "Supplement to the London Gazette". 25 May 1962. https://www.thegazette.co.uk/London/issue/42686/supplement/4352. 
  12. 12.0 12.1 12.2 12.3 12.4 12.5 "History of Ladi Kwali, the Famous Nigerian Potter | Abuja Facts". www.abujafacts.ng. Archived from the original on 7 January 2016. Retrieved 27 March 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. "Nigerian National Order Of Merit Award", Frontiers News, 5 December 2013.

Àdàkọ:Authority control