Laolu Akande

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Laolu Akande
Akande ní National Press Club Washington DC, US
Ọjọ́ìbíIbadan, Nàìjíríà
Iṣẹ́Akọ̀ròyìn, òǹkọ̀wé

Laolu Akande jẹ́ akọ̀ròyìn, olóòtú, ọ̀mọ̀wé àti olùkọ́. Lọ́wọ́lọ́wọ́, òun ni agbẹnusọ fún igbákejì ààrẹ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Prof. Yemi Osinbajo, SAN.[1][2][3][4] Ṣáájú kí ó tó di agbẹnusọ fún igbákejì ààrẹ, Akande ń jábọ̀ ìròyìn fún Empowered Newswire, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn kan tó wà ní orílẹ̀èdè Amerika, ó tún jẹ́ North America Bureau Chief fún The Guardian ní ìlú New York, ní America.[5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú IbadanÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọ́n bí Akande sí. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Omolewa, àti Loyola College, ní Ibadan. Ó parí A-Levels ní ilé-ẹ̀kọ́ gihga ti Oyo State College of Arts and Sciences, ní Ilé-Ifẹ̀. [6] Ó kàwé gboyè ní yunifasiti ti Ibadan ní ọdún 1990, ó sì tún gboyè Masters ní Yunifasiti kan náà ní ọdún 1992.[7]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún 1989 ni Akande bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn kíkọ, ní ọdún 1989, nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn The Guardian gẹ́gẹ́ bíi ajábọ̀ ìròyìn.

Akande jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ News Magazine team nihgbà tí wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 1993, gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé àgbà. Ó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Tempo publication nígbà tí ìjọba ológun fagi lé The News fún ìròyìn rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kí òmìnira tó dé.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Buhari Names Deputy Chief of Staff, Media Aide for Vice President Osinbajo". 4 September 2015. Archived from the original on 18 August 2021. Retrieved 27 March 2023. 
  2. "2023 Presidential Polls: Osinbajo remains best man for the job - Laolu Akande, spokesman". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-06-04. Retrieved 2022-06-30. 
  3. "Ignore speculations on Osinbajo announcing presidential bid after APC convention, Laolu Akande tells Nigerians". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-07. Retrieved 2022-06-30. 
  4. "2023: Osinbajo'll build on Buhari's gains -Aide". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-12. Retrieved 2022-06-30. 
  5. "Enahoro, Soyinka To Begin US PRONACO Confab Next Week". www.nigeriavillagesquare.com. Archived from the original on 2019-03-27. Retrieved 2023-03-27. 
  6. Empty citation (help) 
  7. "6 Things You Should Know About Osinbajo's Spokesperson, Laolu Akande". 23 June 2015.