Liz Da-Silva

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Liz Da-Silva
Ọjọ́ìbíElizabeth Omowunmi Tekovi Da-Silva
10 Oṣù Kàrún 1978 (1978-05-10) (ọmọ ọdún 45)
Obalende, Ipinlẹ Eko
Orílẹ̀-èdèTogo ati Naijiria
Iṣẹ́Osere
Ìgbà iṣẹ́2004–Iwoyi
Àwọn ọmọ1

Elizabeth Ọmọ́wùnmí Tekovi Da-Silva (tí a bí ní Oṣù Kẹẹ̀fà Ọjọ́ 10, Ọdún 1978) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Tógò tí ó maá n sábà kópa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nínu fíìmù Yorùbá ti Nàìjíríà. Ní ọdún 2016, wọ́n yan Da-Silva fún àmì ẹ̀yẹ City People Movie Award fún ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ (ẹ̀ka ti eré Yorùbá) níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards.[1] Ní ọdún 2018 bákan náà, ó gba àmì ẹ̀yẹ fún òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Best of Nollywood Awards.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Da-Silva sí ọwọ́ àwọn òbí tí n ṣe ará Tógò ṣùgbọ́n tí wọ́n n gbé ní Nàìjíríà. A bi ní agbègbè tí a mọ̀ sí Obálendé ní Ìpínlẹ̀ Èkó níbití àwọn òbi rẹ̀ gbé, níbẹ̀ ló sì ti lo ìgbà èwe rẹ̀. Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú àwọn oniròyìn kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó ṣàlàyé pé Ìlú Èkó dà gẹ́gẹ́ bi ilé òun, ó sì sọ nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà pé òún wá láti ilé olórogún.[3] Da-Silva lọ sí Ireti Grammar School fún ètò-ẹ̀kọ́ ìwé mẹ̀wá rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ B.Sc.[1][4]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan Da-Silva ṣàlàyé pé òún bẹ̀rẹ̀ sí nìfẹ́ sí láti darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ fíìmù ti Yorùbá ti Nàìjíríà ní àkókò tí òún wà ní ilé-ìwe girama. Nígbà náà lòwún bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínu àwọn eré ti ilé-ìwé. Da-Silva nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú àwọn oniròyìn The Punch ṣàlàyé pé òún kó ipa àkọ́kọ́ ní ilé-iṣẹ́ fíìmù Yorùbá ti Nàìjíríà ní ọdún 2004 nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ìyábọ̀ Òjó.[5] Da-Silva di gbajúmọ̀ òṣèrè lẹ́hìn tí ó kó àwọn ipa gbòógì nínu fíìmù méj̀i kan; àkọ́lé àkọ́kọ́ ni Wákàtí Méta látọwọ́ Wale Lawal àti fíìmù kan ta pe àkọ́lé rẹ̀ ní Omidan látọwọ́ Ìyáboọ̀ Òjó.[6][3]

Da-Silva ní ọdún 2012 ṣe àkọ́kọ́ ìgbéréjáde rẹ̀ pẹ̀lu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mama Insurance, èyítí ó ṣe ìfihàn Ayò Mógàjí, Lánre Hassan,Ìyábọ̀ Òjó, Rónkẹ́ Òjó, àti Doris Simeon .[7][8]

Ìgbé ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Da-Silva jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ bíbí àti ọmọ orílẹ̀-èdè Tógò nípasẹ̀ àwọn òbi rẹ̀. Da-Silva ti ṣàlàyé Ìpínlẹ̀ Èkó bí ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sì ní àdìsọ́kàn láti ní ìṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní Tógò. Da-Silva Ní ọdún 2013 yípadà láti Krìstẹ́nìIslam.[8][9][10]

Àwọn Àmì-ẹ̀yẹ Àti Yíyàn Rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Year Award Category Result Ref
2018 City People Entertainment Awards Best Supporting Actress of the Year (Yoruba) Wọ́n pèé
Best of Nollywood Awards Best Supporting Actress –Yoruba Gbàá

[11]

Ipa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Da-Silva lórúkọ, Bukky Wright gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe rẹ̀ nínú ilé iṣẹ́ fíìmù Yorùbá ní Nàìjíríà ó sì sọ pé òun ti nípa lórí, ọ̀nà ìṣèré rẹ̀ ní pàtàkì. [12]

Àwọn Fíìmù Rẹ̀ Tí A Yàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ore l’ore Nwoto (2007)
  • Omidan
  • Desire
  • Itanje
  • Mama Insurance
  • Alebu kan
  • Mawo’badan
  • Tasere
  • Mama insurance

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 Kehinde, Seye (2018-09-10). "Top Actress, LIZ DA SILVA Goes Into Fashion •Calls Her Label TEKOVI D'TAILOR". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-18. 
  2. "BON Awards 2018: Mercy Aigbe, Tana Adelana shine at 10th edition". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-12-09. Retrieved 2019-12-18. 
  3. 3.0 3.1 Published. "Actors should have a back-up plan — Liz Da Silva". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-18. 
  4. "Liz Da Silva: 13 things you must know about the sexy Nollywood actress". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-12-06. Retrieved 2019-12-19. 
  5. Nigeria, Information (2018-03-23). ""Why I’m still single"- Actress, Liz Da-Silva". Information Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-19. 
  6. Nigeria, Information (2018-04-18). ""The Secret Things I Did To Remain Relevant In Nollywood"-Popular Yoruba Actress, Liz da Silva Explodes". Information Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-19. 
  7. "Marriage failures begin on newspaper pages—Liz Da Silva". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-06-09. Retrieved 2019-12-19. 
  8. 8.0 8.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :22"
  9. Legit.ng (2013-07-04). "Actress, Liz Da Silva Converts To Islam Because Of Baby". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-19. 
  10. "Liz Da Silva converts to Islam". The Eagle Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-07-06. Retrieved 2019-12-19. 
  11. "BON Awards | Nominees for the Best of Nollywood Awards, 2018" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 19 December 2019. Retrieved 19 December 2019. 
  12. "Liz Da Silva: 13 things you must know about the sexy Nollywood actress". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 6 December 2015. Retrieved 19 December 2019.