Nkem Owoh

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nkem Owoh
Nkem Owoh at the African Movie Academy Awards in Bayelsa State, Nigeria, 2008
Ọjọ́ìbíNkem Owoh
7 Oṣù Kejì 1958 (1958-02-07) (ọmọ ọdún 66)
Amagu, Udi Town, Eastern Region, British Nigeria (now in Enugu State, Nigeria)
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànNwabuoku
Iléẹ̀kọ́ gígaFederal University of Agriculture, Abeokuta
Iṣẹ́Actor
Olólùfẹ́Ngozi Owoh

Nkem Owoh (tí wọ́n bí ní ọjọ́ 7 oṣù February, ọdún 1958) jẹ́ òṣèrékùnrin àti apanilẹ́rìn-ín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2008, ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti African Movie Academy lábẹ́ ìsọ̀rí "Òṣèrékùnrin tó jẹ́ olú ẹ̀dá-ìtàn tó dára jù lọ", fún àwọn ìkópa rè nínú fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bí i "Stronger than Pain".[1]

Ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ipinle Enugu, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n bí Nkem Owoh sí. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama rẹ̀, ó lọ sí Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. Láti ìgbà tó ti wà ní Yunifásiti náà ni ó ti ń kópa nínú fíìmù ṣíṣe.[2]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó tún gbajúmọ̀ fún orin kan tó kọ, tí àkọ́lé rè jẹ́ "I Go Chop Your Dollar", èyí tó sọ̀rọ̀ nípa lílu ènìyàn ní jìbìtì.[3] Àjọ Economic and Financial Crimes Commission gbẹ́sè lé orin náà.[4] Ní ọdún 2007, àwọn ọlọ́pàá mú Owoh ní ìlú Amsterdam, ní Netherlands nítorí àbájáde ìwádìí olóṣù méje tí wọ́n ṣe.[5] Wọ́n mú Owoh ní ibi t́ ti ń kọrin ní ayẹyẹ kan, níbi tí àwọn ọlọ́pàá ti kó ènìyàn 111, nítorí wọ́n fura sí wọn pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ jìbìtì, àmọ́ wọ́n padà tú u sílẹ̀.[6][7] Ní oṣù kọkànlá ọdún 2009, àwọn ajínigbé gbé Owoh ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní apá Ìlà-oòrùn ilẹ̀ náà.[8] Àwọn ajínigbé yìí bèèrè 15 million naira.[9] Wọ́n padà tú Owoh sílẹ̀ nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ san 1.4 million naira.[10][11]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "AMAA 2008: List of Nominees and Winners". Archived from the original on 2020-10-13. Retrieved 2023-09-07. 
  2. "Biography of Nkem Owoh". Archived from the original on January 23, 2010. Retrieved 2009-11-11.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Jan Libbenga (2007-07-02). "'I Go Chop Your Dollar' star arrested". The Register. 
  4. "Police Arrest Nkem Owoh in Holland". NigeriaMovies.net. 2007-07-04. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2023-09-07. 20
  5. Empty citation (help) 
  6. "Police Arrest Nkem Owoh in Holland". NigeriaMovies.net. 2007-07-04. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2023-09-07. 20
  7. "'I Go Chop Your Dollar' star arrested". Archived from the original on 16 July 2018. Retrieved 27 November 2009. 
  8. Nkem Owoh (Osuofia) Kidnapped[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  9. "Breaking News Osuofia (Nkem Owoh) Kidnapped". Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2023-09-07. 
  10. "Jubilation in Nollywood as Osuofia is freed". Archived from the original on 19 November 2009. Retrieved 27 November 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  11. "'Scam comic' kidnapped in Nigeria". BBC News. 2009-11-10.