Onitsha Market

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Òpópónà Ọjà Onitsha

Ọjà Onitsha tí a tún mọ̀ ní Ọjà Onitsha àkọ́kọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọjà tí ó tóbi júlọ ní ìwọ̀-òòrù Áfíríkà èyí tí ó dá lóríi bí ó ti tóbi tó àti oríṣiríṣi ọjà tí ó wà níbẹ̀.[1][2] Ọjà yí fìdí kalẹ̀ sí ìlú Onitsha, olú-ìlú ìṣòwò ti Ìpínlẹ̀ Anámbra ní gúúsù ìla-òòrùn Naijiria. Ẹgbẹ́ oníṣòwò ọjà Onitsha tí àdàpè rẹ ńjẹ́ OMATA, èyítí ìgbàgbọ wà pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́jà tí ó gbajúmò ní àgbáyé ni ó ńṣe àkóso ọjà yí. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ní ìmọ̀ nípa gbígbé ọjà wọlé láti ìla-òòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wón ní olórí ọfiisi wọn ní inú ojà yìí. Àpapọ̀ àwọn oníṣòwò ní agbègbè náà máa ńmú ó kéré jú àwọn ẹrù bíi méfà tí tọọnu wón jẹ́ ogójì (àwọn àpótí tí ẹsè wọn tó ogójì) àwọn ẹrù lọ́dọọdún. Díẹ̀ nínú àwọn olúgbéọjá wọlé pàtàkì máa nkó ọjà tí ó lé díẹ̀ ní ọgọ́rùn ún tí àwọn tọọnu wọn jẹ́ ogójì wọlé ní ọdún kan. Àwọn ọjà wọnyí pẹlú ohun-ọ̀ṣọ́ aṣọ, ilé, ilé-iṣẹ́ àti ohun èlò ọfiisi.

Ó wà níbí ààlà odo Niger lọ sí ìwọ̀-oorun àti Fegge látipàṣẹ òpópónà Osumaru láti ìlá-oorun wa. Àwọn àjọ ojúlalákàn fi ń ṣọ orí tí ọjà Onitsha gangan tí ó sì jẹ́ wípé wón ń ṣiṣẹ́ lábé ọ̀wọ́ àwọn olópàá Nàìjíríà ni wón ń ṣọ́ ọjà yii. A lè ṣe àpèjúwe ọjà yi dáradára gégé bíi ilé agbára ìṣòwò tii ìwò-oorun Áfíríkà. Ó jẹ́ ọjà tí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣòwò tí wón wà ní agbègbè ECOWAS ma ń wá fún káràkátà tí ó fi mọ́ Accra, Abidjan, Douala, Niamey àti Cotonou àti àwọn ibòmíràn ní àgbáyé tí a bá níkí á ménuba díẹ̀.

Òpòlopò orísirísi nkán ni wón ń pèsè ní ọjà Onitsha. Pẹ̀lú pé ààbò tí ó dára wa nínú ọjà yí, òpòlopò àwọn jàgùdà àti àwọn elétàn ni wón ṣì wà nínú ọjà yí lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Nigeria's expert copy-cats
  2. Onyeakagbu, Adaobi (2021-06-24). "Top 10 famous markets in Nigeria and what they are famous for". Pulse Nigeria. Retrieved 2021-08-05. 
  3. Victor, Chigozie; Ilo, Ihuoma (2021-06-17). "Onitsha Main Market Under Threat Of Insurgency, Traders, Residents Cry". HumAngle Media Limited. Retrieved 2021-08-05.