Rebecca Adébímpé Adékọ́lá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Rebecca Adébímpé Adékọ́lá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ìrètí jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ Yorùbá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó di olóògbé ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2002, (27th September 2002). Kí ó tó di olóògbé, ìrètí jẹ́ ọ̀kan lára ìlúmọ̀ọ́kà òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò, pàápàá jùlọ sinimá-àgbéléwò èdè Yorùbá. Lára àwọn sinimá-àgbéléwò tí ó ti gbajúmọ̀ ni, Edúnjọ́bí, Ayé Àwa Obìnrin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn sinimá-àgbéléwò mìíràn. Ọ̀pọ̀ èèyàn lérò pé Rebecca Adébímpé Adékọ́lá jẹ́ ìbátan pẹ̀lú Ọdúnladé Adékọ́lá, ògbóǹtarìgì òṣèré sinimá àgbéléwò òde òní, ṣùgbọ́n wọn kò tan rárá, orúkọ wọn kàn wulẹ̀ ṣe kongẹ́ ni. Lára àwọn ọmọ Rebecca Adébímpé Adékọ́lá ni Tọ̀míwà Adékọ́lá. [1] [2] [3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]