Siẹrra Léònè
Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Siẹrra Léònè Republic of Sierra Leone | |
---|---|
Motto: "Unity - Freedom - Justice" | |
Orin ìyìn: High We Exalt Thee, Realm of the Free | |
Olùìlú àti ìlú tótóbijùlọ | Freetown (1,070,200) |
Àwọn èdè ìṣẹ́ọba | Geesi |
Orúkọ aráàlú | Sierra Leonean |
Ìjọba | Constitutional republic |
Julius Maada Bio | |
Mohamed Juldeh Jalloh | |
Independence | |
• from the United Kingdom | April 27 1961 |
• Republic declared | April 17 1971 |
Ìtóbi | |
• Total | 71,740 km2 (27,700 sq mi) (119th) |
• Omi (%) | 1.0 |
Alábùgbé | |
• UN 2007 estimate | 5,900,000 (103rd1) |
• Ìdìmọ́ra | 83/km2 (215.0/sq mi) (114th1) |
GDP (PPP) | 2005 estimate |
• Total | $4.921 billion (151st) |
• Per capita | $903 (172nd) |
Gini (2003) | 62.9 very high |
HDI (2007) | ▲ 0.336 Error: Invalid HDI value · 177th |
Owóníná | Leone (SLL) |
Ibi àkókò | UTC+0 (GMT) |
Àmì tẹlifóònù | 232 |
ISO 3166 code | SL |
Internet TLD | .sl |
1 Rank based on 2007 figures. |
Siẹrra Léònè ( /siːˈɛrə liːˈoʊn/) (Krio: Sa Lone), lonibise bi Orile-ede Olominira ile Siẹrra Léònè, je orile-ede ni Iwoorun Afrika. O ni bode mo Guinea si ariwa ati ilaorun, Liberia ni guusuilaorun, ati Okun Atlantiki ni iwoorun ati guusuiwoorun. Sierra Leone ni aala ile to 71,740 km2 (27,699 sq mi)[1] ao si ni olugbe ti idiye re je egbegberun 6.5. O je Imusin Britani tele, loni o ti di orile-ede olominira albagbepo to ni awon igberiko meta ati Western Area; awon wonyi na si tun je pipin si agbegbe merinla.
Sierra leone ni ojuojo olooru, pelu ile ayika to je orisirisi lati savannah de rainforests.[2] Freetown ni oluilu, ilu totobijulo ati gbongan okowo re. Awon ilu pataki yioku na tun ni Bo, Kenema, Koidu Town ati Makeni.[1]
Geesi ni ede onibise nibe,[3] ti won unlo ni ile-eko, ibise ijoba ati latowo awon amohunmaworan. Mende ni ede gbangba ti won unso ni guusu, beesini Temne ni ede ti ariwa. Krio (ede Krioli lati inu ede Geesi ati opo awon ede Afrika to si je ede abinibi fun awon Krio Sierra Leone) ni ede akoko ti awon bi 10% olugbe unso sugbon bi 95% ni ede na ye.[4] Botilejepe oun je lilo kakiri Sierra Leone, ede Krio ko ni ipo onibise kankan nibe.
Sierra Leone lonibise je ile fun awon eya eniyan merinla, ikookan won ni ede ati asa ti re. Awon eya eniyan titobijulo meji ni won wa, awon wonyi ni awon Mende ati awon Temne, ikokan won je 30% olugbe. Awon Mende poju ni agbegbe Guusu-Apailaorun Sierra Leone beesini awon Temne poju si ni Apaariwa Sierra Leone. O ti pe ti awon Mende ti un bori ninu oselu ni Sierra Leone. Opo awon omo-orile-ede je kiki elesin Musulumi, botilejepe won ni awon elesin Kristi bi 35%. Niyato si opo awon omo-orile-ede Afrikan miran, Sierra Leone ko ni isoro eya tabi esin bo se wa nibo miran.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Encarta Encyclopedia. "Sierra Leone". Sierra Leone. http://encarta.msn.com/encyclopedia_761563681/Sierra_Leone.html. Retrieved 19 February 2008. Archived 28 February 2008 at the Wayback Machine.
- ↑ The World Guide. "Sierra Leone Geography". Archived from the original on 12 January 2009. Retrieved 19 February 2008.
- ↑ "Sierra Leone Overview". United Nations Development Programme Sierra Leone. Retrieved 3 June 2008.
- ↑ "Sierra Leone: Krio and the Quest for National Integration". SOAS (in English). University of London. Retrieved 5 September 2014.