Tchidi Chikere

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tchidi Chikere
Ọjọ́ìbí10 October 1975
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́English Language, University of Calabar
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Calabar
Iṣẹ́Actor . Producer . Director
Olólùfẹ́Nuella Njubigbo
Àwọn ọmọ3
AwardsAfrica Magic Viewers award, 2012 Golden Icons Academy Movie Awards

Tchidi Chikere (tí a bí ní October 10, 1975), jẹ́ òṣèrékùnrin, olùdarí eré, aṣàgbéjáde eré, olùdarí orin inú fíìmù àgbéléwò, òǹkọ̀tàn àti akọrin. Ó ní ju fíìmù àgbéléwò ọgọ́rùn-ún (100) lọ, àti àwo-orin méjì.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Chikere wá láti ìlú Amuzi Ahiazu Mbaise, ní Ipinle Imo. Òun ni ọmọ àbígbẹ̀yìn àwọn òbí rẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní University of Calabar. Nígbà tó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ eré, ó sì tún darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ orin mẹ́ta. Ní kété tí ó parí National Youth Service rẹ̀, ó rin ìrìn-àjò lọ sí UK, ó sì ṣe àtẹ̀jáde ìwé àkọ́kọ́ rẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fíìmù ní pẹrẹu.

Ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Chikere ní ọmọ mẹ́ta pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn òṣèrébìnrin Sophia Tchidi Chikere. Ìgbéyàwó náà dópin ní ọdún 2012.[2] Lọ́wọ́lọ́wọ́, òṣèrébìnrin Nuella Njubigbo ni ìyàwó rẹ̀.[3] Ìgbéyàwó ìbílẹ̀ náà wáyé ní March 29, 2014, ní ìlú ìyàwó rẹ̀, ní Ipinle Anambra. Ìgbéyàwó alárédè sì wáyé ní Catholic Church of Transfiguration, VGC, Ìpínlẹ̀ Èkó, ní June 9, 2018.

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìṣàfihàn nínú fíìmù àgbéléwò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún FÍìmù Ipa Ọ̀rọ̀
2003 Throwing Stones with Rita Dominic
2011 Paparazzi: Eye in the Dark with Van Vicker, Chet Anekwe & JJ Bunny
2012 When Heaven Smiles with Van Vicker (Directed by Tchidi Chikere & George Kalu)
2016 Slave Dancer with Princess Brun Njua
2021 Our Jesus Story

Àwọn fíìmù tó jẹ́ olùdarí àti aṣàgbéjáde eré fún[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ọdún FÍìmù Ọ̀rọ̀
2003 Blood Sisters starring Oge Okoye, Genevieve Nnaji, Omotola Jalade Ekeinde
2008 Stronger Than Pain starring Nkem Owoh, Kate Henshaw
2011 Gold Not Silver starring Ken Erics
2012 Paint My Life/Tempest starring Daniel K Daniel
2013 Dumebi starring Mercy Johnson
2017 Professor John Bull starring Daniel K Daniel (TV series)
2018 Pink Room hosts are Nuella Njubigbo, Uriel Oputa, Anita Joseph, Bidemi Kosoko, Nichole Banna, Ese Eriate & Vida Modelo (Talkshow)

Àtòjọ àwọn orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Show Me Heaven
  • Love Injection
  • Again and Again
  • Club Zone
  • Open Streets
  • Obelomo

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Medeme, Ovwe (2023-04-18). "After two attempts, Nollywood producer Tchidi Chikere announces third marriage". Premium Times Nigeria. Retrieved 2023-10-09. 
  2. Ikeji, Linda (2023-04-17). "Movie director Tchidi Chikere reveals he is married for the third time". Linda Ikeji's Blog. Retrieved 2023-10-09. 
  3. "Movie director Tchidi Chikere ties the knot for the third time". P.M. News. 2023-04-17. Retrieved 2023-10-09.