The Origin: Madam Koi-Koi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
The Origin: Madam Koi-Koi
Fáìlì:The Origin Madam Koi-Koi.jpg
AdaríJay Franklyn Jituboh
Olùgbékalẹ̀Jay Franklyn Àdàkọ:Plain list Dale Falola
Àwọn òṣèréIreti Doyle Àdàkọ:Plain list Chioma Chukwuka Àdàkọ:Plain list Martha Ehinome Àdàkọ:Plain list Omowumi Dada Àdàkọ:Plain list Jude Chukwuka Àdàkọ:Plain list Nene Aliemeke Àdàkọ:Plain list
Déètì àgbéjádePart One -
  • 31 Oṣù Kẹ̀wá 2023 (2023-10-31) (Netflix)
Part Two -
  • 7 Oṣù Kọkànlá 2023 (2023-11-07) (Netflix)
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish

The Origin: Madam Koi-Koi jẹ́ fíìmù 2023 alápá méjì tó jẹ mọ́ ìbẹ̀rù, èyí tí Jay Franklyn Jituboh àti Dale Falla ṣagbátẹrù rẹ̀.[1] Fíìmù alápá mẹ́jì náà ni wọ́n ti ń ṣàfihàn lórí Netflix láti 31 October 2023. Fíìmù náà ní àwọn gnajúmọ̀ òṣèré bí i Ireti Doyle, Martha Ehinome, Nene Aliemeke, Chioma Chukwuka, Deyemi Okanlawon, Omowunmi Dada, Ejiro Onojaife, Chuks Joseph, Kevin T. Solomon, Temidayo Akinboro, Iremide Adeoye àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2]

Ìtàn ní sókí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àsìkò ìtàn náà jẹ́ ọdún 1971 sí 1991, ó sọ̀rọ̀ nípa ìtàn Amanda (Martha Ehinome), èyí tó jé ọ̀dọ́mọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé kan. Ó ń ní ìdojúkọ láti fara mọ́lé ní ilé-ìwé tuntun yìí, nítorí ó ń ní àwọn àlá ìbẹ̀rù kan lálaalẹ́, èyí sì mu kí o pọ̀kànpọ̀ pé nǹkan kàyéfì kan ń ṣẹlẹ̀ ní ilé-ìwé náà. Alábàágbé Amanda àti ọ̀rẹ́ rẹ̀, ìyẹn Edna (Nene Nwanyo) kìlọ̀ fun láti yẹra fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó gbajúgbajà nítorí ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ wọn á kàndí nínú iyọ̀. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, wọ́n gbọ́ pé wọ́n fipa bá Ibukun (Ejiro Onajaife) lò pọ̀, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn pẹ̀lú àwọn gbajúgbajà akẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Idowu (Iremide Adeoye) tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi ète tan Ibukun sínú páńpẹ́ kan. Àwọn ènìyàn àjèjì kan sì pa á, lẹ́yìn tí ó ń le lo.[3][4][5]

Ìṣàgbéjáde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Abẹ́òkútaÌpínlẹ̀ Ògùn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n ti ya fíìmù The Origin: Madam Koi-Koi. Ìyafọ́nrán náà tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Wọ́n ṣe ìgbéjáde apá kìíní náà ní ayẹyẹ Halloween ti ọdún 2023, nígbà tí wọ́n sì ṣàgbéjáde apá kejì ní November 7, 2023.[6][7]

Àṣààyàn àwọn akópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Martha Ehinome gẹ́gẹ́ bí i Amanda
  • Jude Chukwuka gẹ́gẹ́ bí i Baba Fawole
  • Ireti Doyle gẹ́gẹ́ bí i Mother Superior
  • Nene Aliemeke gẹ́gẹ́ bí i Edna
  • Omowunmi Dada gẹ́gẹ́ bí i Madam Koi Koi
  • Chuks Joseph gẹ́gẹ́ bí i Lashe
  • Chioma Chukwuka gẹ́gẹ́ bí i Sister Ruth
  • Deyemi Okanlawon gẹ́gẹ́ bí i Theophilus
  • Baaj Adebule gẹ́gẹ́ bí i Oscar[8]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Oloruntoyin, Faith (2023-10-23). "'The Origin: Madam Koi Koi' lands official release date on Netflix". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-05. 
  2. Oloruntoyin, Faith (2023-10-23). "'The Origin: Madam Koi Koi' lands official release date on Netflix". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-05. 
  3. "REVIEW: The Origin: Madam Koi-Koi - Daily Trust". dailytrust.com. Retrieved 2023-11-05. 
  4. Adeyinka, Ayomitide (2023-10-24). "Netflix Announces Production of The Origin: Madam Koi Koi » YNaija". YNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-05. 
  5. Oloruntoyin, Faith (2023-10-23). "'The Origin: Madam Koi Koi' lands official release date on Netflix". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-05. 
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02
  7. Eleanya, Frank (2023-11-01). "The Origin: Madam Koi Koi, Nollywood’s first Netflix horror series raises nostalgia". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-05. 
  8. "Jituboh’s Riveting Tale Introduces ‘Madam Koi Koi’ to the Global Halloween Scene - THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-05.