Tosin Ajibade

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tosin "OloriSuperGal" Ajibade
Ọjọ́ìbíOluwatosin Ajibade
17 Oṣù Kejì 1987 (1987-02-17) (ọmọ ọdún 37)
Nigeria
Ẹ̀kọ́Lagos State University, Pan-Atlantic University
Iṣẹ́New Media Entrepreneur, Blogger, Digital Content Strategist, Writer
Websiteolorisupergal.com

Tosin "OloriSuperGal" Ajibade (Oluwatosin Ajibade; tí a bí ní ọjọ́ kẹta-dín-lógún oṣù kejì ọdún 1987) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí a mọ̀ fún ojú òpó wẹ́ẹ̀bù eré ìdárayá àti ìgbésí ayé rẹ̀, OloriSuperGal.com àti láìpẹ́ ààyè ayélujára tirẹ̀, TosinAjibade.com. Ó tún jẹ́ olùṣètò 'New Media Conference ' tí ó ń wáyé ní ọdọọdún ní Nàìjíríà.

Ẹ̀kọ́ Rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tosin Ajibade gba òye ti 'bachelors' nínú ètò ìṣirò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkó. Lẹ́hìn náà ó gba Ìwé-ẹ̀rí ní 'Media Enterprise' láti Ilé-ìwé ti 'Media and Communications' Ilé-ẹ̀kọ́ gíga, Fásítì Pan-Atlantic, Nàìjíríà. [1]

Iṣẹ́ Ayélujára[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tosin Ajibade jẹ́ mímọ̀ fún ìgbésí ayé rẹ̀ àti ojú òpó wẹ́ẹ̀bù eré ìdárayá, OloriSuperGal.com ní Nàìjíríà àti ẹ̀dá South Africa kan. [2] Tosin bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ bí àtẹ̀jáde ní ọdún 2009. Ó ṣẹ̀dá búlọ́ọ̀gì rẹ̀ ní ọdún 2010. Ní ọdún 2011, wọ́n gbà á wọlé ní BlackHouse Media gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso wẹ́ẹ̀bù wọn ṣùgbọ́n ó fi sílẹ̀ ní ọdún 2012 láti dojúkọ́ búlọ́ọ̀gì. [1] Ní àkokò tí ó bẹ̀rẹ̀ ní búlọ́ọ̀gì rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ tó níṣe pẹ̀lú ẹ̀rọ ayélujára púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí The Net NG, Acada ​​Magazine àti Laff Mattaz ti Gbenga Adeyinka the 1st.[3]

Ní ọdún 2014, Tosin Ajibade ti wà ní àkójọ láàrín àwọn ọgọ̀run àwọn obìrin YNaija tí ó ní ipa jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti pé búlọ́ọ̀gì rẹ̀ ni a kà lónìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn olókìkí àti gbajúmọ̀ jùlọ ní Nàìjíríà.

Ó jẹ́ olùṣètò ti àpéjọ 'New Media Conference' tí ó wáyé ní ọdọọdún ní ọdún 2015, 2016, 2017, 2018 àti 2019. Àtojọ náà fojú sí àwọn agbára ẹ̀rọ ayélujára tuntun, pàápàá ní àwọn 'online/digital possibilities. [4]

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Àwùjọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ajibade ti lo búlọ́ọ̀gì rẹ̀ láti pe àkíyèsí sí àwọn ọ̀rọ̀ àwùjọ pàápàá bí ó ṣe kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Àpẹẹrẹ tí ó hàn gbangba ni ìtàn ikọlù ìbálòpọ̀ ti ilé-ìwé Queen's College kan, ọmọ Ilé-ìwé Èkó nípasẹ̀ olùkọ rẹ̀ tí ó gbé jáde àti pé nítorí náà ìròyìn náà dé gbogbo etí ó sì gba àkíyèsí àwọn aláṣẹ tí ó yẹ. [5]

Àmì-ẹ̀yẹ Àti Yíyán[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2015, Tosin jẹ́ orúkọ nínú àtòjọ ọgọ́run àwọn obìnrin tí ó ní ipa jùlọ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ YNaija. Ní ọdún 2016, ó gba Ààmì-ẹ̀yẹ àwọn ẹ̀bùn Future Awards ti Áfíríkà fún New Media. [6]

Àtẹ̀jáde Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tosin Ajibade jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé méjì, Láti Social Misfit sí Social Media Hero (2018) [7] and The Influencer Blueprint Archived 8 June 2020 at the Wayback Machine. (2020).[8] àti The Influencer Blueprint.

Àwọn Ìtọ́ka Sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 Bamgbola, Oyindamola. "#DigitalDivaSeries – Olori Supergal, Super Blogger And Social Media Strategist". ID Africa. Archived from the original on 14 February 2017. https://web.archive.org/web/20170214003835/http://www.idafrica.ng/digitaldivaseries-olori-supergal-super-blogger-and-social-media-strategist/. Retrieved 16 June 2016. 
  2. Woman, NG. "Want To Be A Superblogger? Tosin 'Olorisupergal' Ajibade's Advice Will Do You Some Good!". Woman Nigeria. Archived from the original on 12 November 2017. https://web.archive.org/web/20171112025002/http://woman.ng/2015/07/do-you-want-to-be-a-superblogger-tosin-olorisupergal-ajibades-advice-will-do-you-some-good. Retrieved 10 June 2016. 
  3. Twitter, Social media junkie at Techpoint I’m always open to new experiences Follow us on; Facebook, like TechPoint ng on (2017-08-14). "In conversation with Tosin Ajibade, founder of Olorisupergal". Techpoint.ng. Retrieved 2017-08-16. 
  4. Ovih, Lawson. "New Media Conference to chart growth in Standards". Business World. Archived from the original on 30 May 2016. https://web.archive.org/web/20160530012251/http://businessworldng.com/new-media-conference-to-chart-growth-in-standards/. Retrieved 16 June 2016. 
  5. Kofoworola, Belo-Osagie. "Queen's College girls protest alleged sexual harassment". The Nation. http://thenationonlineng.net/queens-college-girls-protest-alleged-sexual-harassment/. Retrieved 17 June 2016. 
  6. The, Nation. "Olorisupergal makes Nigeria's 100 Most Influential Women list". The Nation Newspaper. http://thenationonlineng.net/olorisupergal-makes-nigerias-100-most-influential-women-list/. Retrieved 13 June 2016. 
  7. Wanjiru, Njino (2018-10-29). "Olori Supergal Talks About Her New Book 'From Social Misfit To Social Hero'" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 June 2020. Retrieved 2020-06-08. 
  8. "Influencer Blueprint". Tosin Ajibade (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 June 2020. Retrieved 2020-06-08.