Idowu Philips: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò
Ìrísí
Content deleted Content added
Macdanpets (ọ̀rọ̀ | àfikún) →Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Ní Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀: Fixed typo Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù |
(Kò ní yàtọ̀)
|
Àtúnyẹ̀wò ní 14:57, 16 Oṣù Ọ̀wàrà 2019
Ìdòwú Philips tí orúkọ gbajúmò rẹ̀ ń jẹ́ Iya Rainbow (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1942) jẹ́ gbajúgbajà oṣèrébìnrin ọmọ Nàìjíríà.[1]
Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Ní Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀
Ìjẹ̀bú-Òde ní ìpínlè Ògùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a bí Idowu Philips sí. Ó jé akọ́ṣẹ́mọṣẹ́bìnrin elétò ìlera, Nọ̀ọ́sí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ kí ó tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré olóògbé Hubert Ogunde tí ó kú lọ́dún 1990. Lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀, Augustine Ayanfemi Philips, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tíátà olóògbé Hubert Ogunde fúnra rẹ̀, Iya Rainbow náà darapọ́ mọ́ ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú gbogbo ara. Ó ti kópa pàtàkì nínú oríṣiríṣi eré orí ìtàgé àti sinimá àgbéléwò. Lára àwọn eré tó ti kópa pàtàkì ni; Àpáàdì, Ẹrú, Àjẹ́ Nìyà Mi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọmọ márùn-ún ni ó bí. [2] [3]
Àwọn Ìtọ́kasi
- ↑ "Idowu Philips Biography : Net Worth, Age, Husband, Children, Controversies & Movies". BioNetworth – Celebrity Biography , Life History, Profiles, Job Vacancies And Top 10's. 1942-10-16. Retrieved 2019-10-16.
- ↑ "Idowu Philips biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1942-10-16. Retrieved 2019-10-16.
- ↑ "Veteran actress, Idowu Philips, Iya Rainbow celebrates her 76th birthday with beautiful photos". Within Nigeria. 2018-10-16. Retrieved 2019-10-16.