Jump to content

Ààlọ́ Ìjàpá, Àgbò àti Igbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Apààlọ́: Ààlọ́ o!

Ègbè Ààlọ́: Ààlọ̀!

Apààlọ́ : Ààlọ́ mi dá fìrìgbagbóò ó dálérí, Ìjàpá, tìrókò, ọkọ Yáńníbo,

Tí ń lọ láárín ẹ̀pà,

Tí ìpàkọ́ rẹ̀ ńhàn fìrìfìrì,

O ní ọpẹ́lopẹ́ pé òun ga!

Ní àtijọ́, ní ìlú Ìjàpá, igbá títà lowó lórí, àgbẹ̀ tí o bá gbin igbá ti di ọlọ́rọ̀. Ìjàpá wo ara rẹ̀ títí lọ́jọ́ kan pé òun náà yóò gbin igbá láti di àgbẹ̀ to lórúkọ láì ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ nítorí pé ọmọdé n gbìn igbá àgbà ń gbìn igbá wọ́n sì ń rí towó ṣe[1].

Alábahun bá he ọkọ̀ àti àdá rẹ̀ ó di oko kan tí o jìnà sí abúlé rẹ̀. O ṣán oko tó tó yàrá kan ní títóbi. Ó gbin ìdí igbá kan síbẹ̀, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ,Ó padà sí ilé. Ìjàpá kò padà lọ sí oko igbá náà mo títí ọdún fi yí po. Òun fi àwọn tó ń lọ sóko dápará.

Nígbàtí ọdún jọ, onígbá nka'gbá wọ́n gbádùn, wọ́n náwó, Ìjàpá náà bá múra ọgbà oko lọ kí ó lọ kórè oko igbá re. Bí ó ṣe dé bẹ̀, ó ni Ha! ìwọ igbá burúkú yìí ẹyọ kan lóso, àwọn ẹgbẹ́ rẹ ń so ogún, wọ́n so ọgbọ́n. O ma kúkú yọ̀lẹ kò burú, okan náà tilẹ̀ tóbi dáadáa, ng o gbe o tà bẹ ó mú owó wa. Kí Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ kí ó gbé ìgbá. Ìgbá ba sọ̀rọ̀:

Igba: Ìjàpá o ṣé, mo mọ pé ọ̀lẹ ni mi gbogbo ẹgbẹ́ rẹ to gbin igbá ló ń roko mo, kí igbá wọn l'alaafia àti oúnjẹ gidi jẹ ṣùgbọ́n tí ẹ kò rí bẹ́ẹ̀.Èmi ni yìí láti ẹ̀ṣin to ti fi mí síbí ẹ̀ẹ̀mélòó lo bẹ̀ mí wo. O dé o fẹ́ kórè.[2] Enu ya Ìjàpá nígbàtí igbá sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n síbẹ̀ síbẹ̀ o pinnu láti ta igbá náà ni wón igbá tó jẹ́ pé òun lòun gbin. Kí ó bẹ̀rẹ̀ gbé igbá, àfi gbáà igbá fò ó kan Ìjàpá ní kò, Ìjàpá ṣubú lulẹ̀ yakata. Kí o dìde máa sá lọ, igbá ba yi tẹ̀le gírígírí gírígírí, kítá kita, Ìjàpá bá ń ké ẹ gbà mí lọ́wọ́ igbá, ó forin s' enu pé [3]

Igbá nl'Ahun

Teregúngún màjàgúngún tere

Igbá o lọ́wọ́

Teregúngún màjàgúngún tere

Igbá o lẹsẹ̀

Teregúngún màjàgúngún tere (Èémeji) Gbogbo eranko tó pàdé lónà ló fi se ẹlẹ́yà àyàfi àgbò nìkan ló ran Ìjàpá lọ́wọ́ láti bá kan Igbá pa. Àgbò se bẹ́ẹ̀, ó kan igbá pa, tí ó sì fọ́ sí wẹ́lẹ́. Ìjápá kó lára àkúfọ́ igbá fún Àgbò sùgbọ́n àgbo kojale pé òun kò fẹ́. [4].

Ẹ̀kọ́ Ààlọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlọ́ yìí kó wá pé: ká má máa ṣe ọ̀lẹ àti wípé ohun tí a bá gbìn là ó kà.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. https://dokumen.tips/documents/akojopo-alo-ijapa-babalola.html/[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales