Àṣà Ìsọmọlórúkọ Nílẹ̀ Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àṣà Ìsọmọlórúkọ Nílẹ̀ Yorùbá ́ jẹ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà láti sọ ọmọ tuntun lórúkọ. Láyé àtijó, ọjọ́ keje ní Yorùbá máa ń sọmọbìrin lórúko, tí wọ́n sì máa ń sọmọkùnrin lórúkọ lọ́jọ́ kẹsàn-án. Ṣùgbọ́n, ẹ̀sìn àjèjì kiriyó àti ìmàle tí yí èyí padà, ọjọ́ kẹjọ là ń sọmọ lórúkọ nílẹ̀ Yorùbá lóde òní. Oríṣiríṣi orúkọ ni Yorùbá máa ń sọmọ. Yòóbá ní orúkọ àmútọ̀runwá àti orúkọ àbísọ. [1]

Orísìírísìí Orúkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Orúkọ Àbísọ
  • Orúkọ Àmúntọ̀runwá
  • Orúkọ Ìnagijẹ

Orúkọ àbísọ nílẹ̀ Yorùbáj[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orúkọ àbísọ ni àwọn orúkọ Yorùbá tí wọ́n máa ń sọmọ tí ó yàtọ̀ sí orúkọ àmútọ̀runwá. Àpẹẹrẹ orúkọ àbísọ Yorùbá ni: Babátúndé, Olúwaṣẹ́gún, Ìyabọ̀, Abídèmí, Àbẹ̀bí, Fọlọ́rúnṣọ́, Akinọlá, Ìgbẹ́kẹ̀lé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àsikò tí wọ́n bá bímọ sí nígbà mìíràn ló máa ń ṣe atọnà irú orúkọ tí wọ́n yóò sọ ọmọ tí wọ́n bá bí ní àkókò náà. Babátúndé jẹ́ ọmọkùnrin tí bàbá òbí rẹ̀ kan bá kú lásìkò tí wọ́n bí i SÍ, Ìyábọ̀ tàbí Yétúndé ni orúkọ ọmọbìnrin tí ìyá àwọn òbí rẹ̀ kan kú lásìkò tí wọ́n bí i, Abíọ́nà ni ọmọ tí wọ́n bá bí sí ọ̀nà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2]

Orúkọ àmútọ̀runwá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni àwọn orúkọ tí Yorùbá máa ń sọ ọmọ nípa wíwo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bá rọ̀ mọ́ ìbí ọmọ tuntun òun.[3] Bí àpẹẹrẹ, Yorùbá á máa sọ ọmọ méjì tí ìyá kan náà bí lọ́jọ́ kan náà ni Táyéwò àti Kẹ́hìndé, Ọmọ tí wọ́n bá bí lẹ́yìn ìbejì á máa jẹ́, Ìdòwú tàbí Àlàbá, Ọmọ tí wọ́n bá bí ti o bá fi apòkọ́rùn á máa jẹ́ Àìná, Ọmọ oníka mẹ́fà á máa jẹ́ Ìgè, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[4]

Pàtàkì wíwo àkọsẹ̀jayé ọmọ tuntun nílẹ̀ Yorùbá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láyé àtijó, bí wọ́n bá bímọ nílẹ̀ Yorùbá, àwọn òbí ọmọ náà a lọ dáfá láti wo àkọsẹ̀jayé rẹ̀. [5]. Àkọsẹ̀jayé ni wíwo bí ọjọ́-iwájú ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí yóò ti rí. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé, nípa àkọsẹ̀jayé wíwò, wọn yóò mọ bí wọn yóò ṣe tọ́ ọmọ náà ní àtọ́yè.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Naming Ceremony in Yoruba Culture". IleOduduwa.com the Source. 2017-02-01. Retrieved 2019-11-17. 
  2. "The Importance of Names in Yoruba Culture". African Clothing and Fashion Attire for Men and Women. 2007-01-15. Retrieved 2019-11-17. 
  3. Omipidan, Teslim Opemipo (2017-02-02). "Oruko Amutorunwa (Pre-Destined Names) In Yorubaland - OldNaija". OldNaija. Retrieved 2019-11-17. 
  4. "Naming Ceremony (Iso Omo Loruko) » Facts.ng". Facts.ng. 2014-11-10. Retrieved 2021-06-12. 
  5. Samuel, Olaleye Kayode. "ÀKỌSE ̣̀JAYÉ: TREND AND STATUS IN YORÙBÁ COMMUNITIES OF SOUTH WESTERN NIGERIA". Semantic Scholar. Retrieved 2019-11-17.