Àbí Ọlájùwọ́n

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Use mdy dates

Àbí Ọlájùwọ́n
Personal information
BornOṣù Keje 6, 1988 (1988-07-06) (ọmọ ọdún 35)
Houston, Texas
NationalityỌmọ Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà
Listed height6 ft 4 in (1.93 m)
Listed weight236 lb (107 kg)
Career information
High schoolMarlborough School
(Los Angeles, California)
CollegeOklahoma (2006–2010)
NBA draft2010 / Round: 3 / Pick: 28k overall
Selected by the Chicago Sky
Pro playing career2010–2013
PositionCenter
Number21, 34
Coaching career2014–present
Career history
As player:
Àdàkọ:WnbayChicago Sky
2010SEAT-Lami-Véd Győr
2011CSM Satu Mare
Àdàkọ:WnbayTulsa Shock
2011–2012Hapoel Rishon LeZion
2012ŽKK Novi Zagreb
2012BC Castors Braine
2012Esportivo Ourinhos
2012Heilongjiang Chenneng
2013Caja Rural Zamarat
As coach:
2014–2016Cal State Fullerton (assistant)
2016–2018Eastern Michigan (assistant)

Àbí Ọlájùwọ́n tí apèjá orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Alon Abísọ́lá Arisicate Àjọkẹ́ Ọlájùwọ́n, tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù keje ọdún 1988 jẹ́ akọ́ni àti agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà. Ó jẹ́ Ọmọbìnrin gbajúmọ̀ agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n, Hakeem Olajuwon. Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀, Abísọ́là Ọlájùwọ́n, ó jẹ́ ọmọ atàpáta-dìde, ọmọ tí wọ́n bí sínú ọlá, tí ọlá náà ju àwọn ju àwọn ọ̀tá lọ̀.[1]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga àti kọ́lẹ́ẹ̀jì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ọlájùwọ́n sí Houston, ní Ìpínlẹ̀ Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó wà nínú ìkọ̀ tí wọ́n ń gbá bọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n fún ilé-ìwé gíga California àti ní, ó sìn rànwọ́nlọ́wọ́ láti gba àmìn-ẹ̀yẹ mẹ́ta léraléra nínú ìdíje apá iwọ̀-oòrùn Amẹ́ríkà. Ọlájùwọ́n gbàmìn-ẹ̀yẹ ti McDonald's All-American lọ́dún 2006,[1] Ó tún wà lára àwọn tí wọ́n gbà àmìn-ẹ̀yẹ tó pọ̀ jùlọ tí wọ́n jáde ní ilé-ìwé gíga.[1][2] Ó gbá bọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n fún University of Oklahoma, ní àsìkò yìí Nancy Lieberman, aṣàyẹ̀wó bọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n tí ilé-iṣẹ́ ESPN sọ wípé, dídarapọ̀ Ọlájùwọ́n sí ìkọ̀ rẹ̀ fún ìdíje tí ọdún 2006 sí 2007 yóò mú kí wọ́n ṣe àṣeyọrí fún ìdíje NCAA.[3]

Lọ́dún 2010, ó kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ìròyìn láti Oklahoma University.[4]

Àṣàyàn iṣẹ́ rẹ̀ ní Oklahoma University[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Source[5]

Legend
  GP Games played   GS  Games started  MPG  Minutes per game
 FG%  Field goal percentage  3P%  3-point field goal percentage  FT%  Free throw percentage
 RPG  Rebounds per game  APG  Assists per game  SPG  Steals per game
 BPG  Blocks per game  PPG  Points per game  Bold  Career high
Ọdún Ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n GP Àmìn ayò FG% 3P% FT% RPG APG SPG BPG PPG
2006-07 Oklahoma 17 37 48.4% 0.0% 58.3% 1.5 0.1 0.2 0.1 2.2
2007-08 Oklahoma 19 36 40.0% 0.0% 88.9% 3.2 0.1 0.4 0.1 1.9
2008-09 Oklahoma 27 37 31.7% 0.0% 55.0% 2.2 0.1 0.3 0.1 1.4
2009-10 Oklahoma 38 401 50.6% 0.0% 61.7% 7.3 0.5 0.5 0.9 10.6
Career 101 511 47.8% 0.0% 62.1% 4.2 0.2 0.4 0.4 5.1

Ìgbìyànjú rẹ̀ nínú iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Chicago Sky yan Ọlájùwọ́n sí ipò méjìdínlọ́gbọ̀n nínú àwọn tó mọ bọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n gbá jùlọ ní àgbáyé ní ìdíje lọ́dún 2010. [6] Lẹ́yìn èyí, ó dára pọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n ní orílẹ̀ èdè Hungary, SEAT-Lami-Véd Győr,[7] àti ti Romania.[8]

Ní 2011 Ọlájùwọ́n padà sí WNBA, tí ó sìn tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn fún ikọ̀ Tulsa Shock, ibẹ̀ ló ti díje fún sáà ìdíje ọdún 2011 season.[9]

Nígbà ìsinmi, ó gba bọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n fún Hapoel Rishon LeZion (Israel), ŽKK Novi Zagreb (Croatia),[10] BC Castors Braine (Belgium).[11] Ìkọ̀ Tulsa Shock dàá sílẹ̀ lọ́dún 2012.[12] Lẹ́yìn èyí, ó gba bọ́ọ̀lù fún Esportivo Ourinhos (Brazil),[13] àti Heilongjiang Chenneng (China).[14]

Ọlájùwọ́n gba ìsinmi lẹ́nu gbígbá bọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n ní ìkọ̀ orílẹ̀ èdè Italy, Caja Rural Zamarat.[15]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 Michael Kinney, A name to remember: Abi Olajuwon Archived October 8, 2007, at the Wayback Machine., December 6, 2006
  2. Tony Sellars, Olajuwon wants to make her own name Archived November 1, 2006, at the Wayback Machine., scout.com, February 9, 2006
  3. Terps top preseason Top 25, espn.com, accessed January 30, 2007
  4. http://www.emueagles.com/coaches.aspx?rc=1239 "Abi Olajuwon - Assistant Coach." Official Website of the Eastern Michigan Eagles. Accessed December 10, 2017.
  5. "NCAA Statistics". web1.ncaa.org. Retrieved 2017-08-28. 
  6. "Olajuwon waived by Sky". ESPN.com. July 2, 2010. Retrieved October 18, 2016. 
  7. "SEAT Lami Ved Gyor adds Olajuwon to their roster". www.eurobasket.com. August 24, 2010. Retrieved October 18, 2016. 
  8. Nenciu, Andru; Fabian, Ciprian (March 1, 2011). "Fiica unei legende a NBA a ajuns la Satu Mare! Numele ei: "Născută în bogăţie şi iubită de toţi" :)". ProSport (in Èdè Romania). Retrieved October 18, 2016. 
  9. Bailey, Eric (July 21, 2011). "Tulsa Shock release Marion Jones, sign former Sooner Abi Olajuwon". NewsOK.com. Retrieved October 18, 2016. 
  10. "Novi Zagreb adds Abi Olajuwon". www.eurobasket.com. January 13, 2012. Retrieved October 18, 2016. 
  11. Detroz, Christian (February 21, 2012). "Abi Olajuwon rejoint les Castors de Braine". Basketfeminin.com (in Èdè Faransé). Retrieved October 18, 2016. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  12. Moss, John (April 22, 2012). "Tulsa Shock Waive Former Sooner Abi Olajuwon". KTUL.com. Retrieved October 18, 2016. 
  13. Balassiano, Fábio (October 12, 2012). "Filha de lenda da NBA, Abi Olajuwon chega a Ourinhos para a Liga de Basquete Feminino". UOL Esporte (in Èdè Pọtogí). Retrieved October 18, 2016. 
  14. "Abi Olajuwon agreed terms with Heilongjiang". www.eurobasket.com. December 11, 2012. Retrieved October 18, 2016. 
  15. "Abi Olajuwon joins Caja Rural". www.eurobasket.com. July 13, 2013. Retrieved October 18, 2016.