Àdírẹ́ẹ̀sì IP

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdírẹ́ẹ̀sì Prótókóòlù Íntánẹ́ẹ̀tì (Àdírẹ́ẹ̀sì IP) ni àlẹ̀mọ́ ìtò-nọ́mbà tí ó jẹ́ yíyànsílẹ̀ fún ẹ̀rọ kọ̀ọ̀kan tó sopọ̀ mọ́ ẹ̀rọ-àsopọ̀ kọ̀mpútà kan tó únlo Prótókóòlù Íntánẹ́ẹ̀tì fún ìbánisọ̀rọ̀.[1][2] Àdírẹ́ẹ̀sì IP kan únṣe ìṣẹ́ mẹ́jì pàtàkì: ìṣe ìdámọ̀ ẹ̀rọ-agbàlejò tàbí ìfojúkojú ẹ̀rọ-àsopọ̀ àti ìṣe àdírẹ́ẹ̀sì ibùdó.

Internet Protocol version 4 (IPv4) ṣe ìtumọ̀ àdírẹ́ẹ̀sì IP kan gẹ́gẹ́ bí nọ́mbà oní 32-bit.[2] Sùgbọ́n, nítorí bí Internet ṣe ti tóbi tó àti ìdínkù àwọn àdírẹ́ẹ̀sì IPv4 tó wà, ọ̀nà tuntun mìíràn fún IP (IPv6), tó ún lo 128 bits fún àdírẹ́ẹ̀sì IP, jẹ́ ṣíṣe àjọhùnsí ní ọdún 1998.[3][4][5] Ìlò IPv6 ti bẹ̀rẹ̀ láti àrin ìgbà ọdún 2000.

Àwọn àdírẹ́ẹ̀sì IP ún jẹ́ kíkọ àti híhàn ní ọ̀nà tó ṣe é rí kà fún ọmọ ènìyàn, fún àpẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí 172.16.254.1 nínú IPv4, àti 2001:db8:0:1234:0:567:8:1 nínú IPv6. Ìtóbi ìṣọ̀nà ìfikúnwájú fún àdírẹ́ẹ̀sì jẹ́ yíyànsílẹ̀ nínú CIDR notation nípa síṣe ìfikúnlẹ́yìn àdírẹ́ẹ̀sì pẹ̀lú nọ́mbà àwọn bit pàtàkì, f.a., 192.168.1.15/24, tó jẹ́ ìkannáà mọ́ subnet mask 255.255.255.0 tí wọ́n únlò látì ìbẹ̀rẹ̀.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. RFC 760, DOD Standard Internet Protocol, DARPA, Information Sciences Institute (January 1980).
  2. 2.0 2.1 Àdàkọ:Cite IETF Updated by Àdàkọ:IETF RFC.
  3. Àdàkọ:Cite IETF
  4. Àdàkọ:Cite IETF
  5. Àdàkọ:Cite IETF