Àdúgbò Oyé-Èkìtì
1. Ijisẹ:- Àdúgbò ti a n pen i Ijisẹ ni o fẹ ilu Ọye do lati Ile Ifẹ wa. Wọn pa erin ibi ti ẹrin náà ku si iba ni wọn pe ni atẹba ẹni to pa erin náà ni ọlọta aburo ijise ibi ti wọn pa erin náà si ni wọn pe ni ijisẹ. Ijisẹ lo pa àwọn ara Ọyẹ wa lati ile ifẹ pe wọn ti ri ibi tí wọn magbe. Ijisẹ ni orisu ilu Ọyẹ lati ile-ifẹ wa.
2. Ọgbọ mẹta :- Ọ̀nà mẹta ni àwọn ara ọgbọ mẹta ti si wa ki wọn to tẹ̀dó si ilu Ọyẹ.
3. Ọmọdọwa:- Ibi jẹ agbegbe ti ọba ilu maa n gbe.
4. Ire:- Aburo Oloye ni Àdúgbò to wa ni Iyeni, Ọde ni se idi ti o fi ń de ade ogun
5. Ulọdo:- Ibe ni wọn ti se ọdẹ
6. Ilẹsẹ:- Àdúgbò yi kọ de igọsi ko si de ilu Ọyẹ wọn wa ni arin meji.
7. Ilẹdara:- Orukọ ti àdúgbò yi jẹ wa lati ile-ifẹ wa ni wọn tun jẹ ni ìgba ti wọn de ilu Ọyẹ.
8. Odo:- ibi ti àdúgbò yi deto si je egbe odọ.
9. Iwaro:- Oni imọlẹ kan ti wọn máa ń jo ni ibẹ ìdí ti wọn fi pe ni ìwarọ ni yẹn.
10. Ijagun:- Awọn ti on jagun ni wọn gbe ni àdúgbò yìi.
11. Oke-Ọfa:- Apa oke ni àdúgbo naa wa
12. Ayegbaju:- Wọn tun pe àdúgbò yi ni odo-oje nitori pe ẹgbẹ odo ni ilu náà wa.
13. Ẹgbẹ:- Ọ̀nà mẹta ni àwọn ara ẹgbẹ ti si wa ki wọn to wa si mọ àwọn ara ijisẹ.
14. Ijagẹmọ:- Àwọn ara àdúgbò yin i a mọ si ologun tàbí onija láti ìle-ifẹ wa. Igbati wọn de ilu Ọyẹ wọn sit un pe wọn ni ijagẹmọ nitorí ija wọn.
15. Ilogbo:- àdúgbo yi jẹ pàtàkì ni ìlú Ọye, Ijalọ po púpọ̀ si arin wọn itorí náà ni wọn ni ọmọ orin yọyọ ilugbo.
16. Ilupeju:- Ireko ilu Ọyẹ ni, àwọn ni wọn máa ń sin ọba Ọyẹ wọn máa ń pe jọ si ilu Ọyẹ láti ba ọba ji roro, ìdí ti wọn fi pe wọn ni ilupeju.
17. Orisunmíbare:- Wọn jẹ àdúgbò ti o ko owo ati oríṣìíríṣìí dukiya wa si ilu Ọyẹ, àwọn ara Ọyẹ ri pe ọlọrọ ni wọn jẹ ni wọn se pe wọn ni orísunmibare.
18. Esọ sin :- àdúgbò yi ti wọn pe ni esọ sin jẹ ara àwọn ti ogun ko wa lati ile- ifẹ.
19. Ile ya o :- Ogun ko wọn láti Iyao wa si ìlú Ọyẹ ti wọn wa ya ile gbe ni ilu Ọyẹ ni wọn fi ń pe ni ile-yao.
20. Ileesa:- Wọn jẹ àdúgbò to ji náà si ìlú nitorí wọn ko ogùn ba ilu púpọ̀.
21. Ilẹmọ:- O wa lati ile-ifẹ wa si ilu Ọyẹ wọn si kin jẹ iyọ ni àdúgbọ̀ yi.
22. Ipamọ:- wọn jẹ ọmọ ìya si ilẹmọ, wọn jẹ ara ilẹmọ ìdí ti wọn fi ń pe ni ilẹmọ ni yen.
23. Idọfin:- Ọ̀nà mẹrin ni àwọn ara àdúgbò yi ti si wa kì wọn to para po wa si Ijisẹ.
24. Irare:- Ilare ni wọn jẹ ni ilẹ-Ifẹ wọn wa ń jẹ́ irare ni ìgbati wọn de ilu Ọyẹ.
25. Oke ìyin-Araroni:- Ọ̀nà mẹta ni wọn ti si wa
26. Iyeni:- jẹ àdúgbò ti wọn ti jẹ orogun ni ilu Ọyé.
27. Asara:- àdúgbò yìí jẹ ibi àwọn ìransẹ ọba ń gbe.
28. Oloyagba:- Iya gba ni ogun tí ki wọn wa sí ilu Ọyẹ ni wọn se ń jẹ oloyagbe. 29. Ibẹru:- Ọlota ni aburo Ijise lati ile ifẹ wa nígbati wọn de Ọyẹ iberu ati Ijisẹ wa yapa o sit un jẹ àdúgbò ti o bẹru ogun tàbí ija púpọ̀.
30. Imijẹ:- Àdúgbò yii wa láti ilu Itapu iṣẹ ọdẹ ni baba ń la wa n se. Iṣẹ yii lo se wa si ilu Ọyẹ ìdí ti wọn fi tẹ̀dó si ìlú Ọyẹ ni èyí.