Àdúrà Olúwa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdúrà Olúwa jẹ́ àdúrà tí àwọn Ẹlẹ́sìn ọmọ lẹ́yìn Jésù Kírísítì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Bíbélì, nínú ìwé Mátíù orí kẹfà, ẹsẹ kẹsàn-án títí dé kẹtàlá. Ó jẹ́ àdúrà tí àwọn kírísítẹ́nì máa ń gba pẹ̀lú Ọ̀wọ̀ níbikíbi tí wọ́n bá ti ń gbà á. [1] [2] [3]

Àdúrà Olúwa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Bíbélì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

6:9 Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Bàbá wa tí ḿ bẹ ní ọ̀run; Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.

6:10 Kí ìjọba rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé, bi ti ọrùn.

6:11 Fún wa ní oúnjẹ oòjọ́ wa lónìí

6:12 Dárí gbèsè wa jìn wá, bí àwa ti ń darijì àwọn onígbèsè wa.

6:13 Má si fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì. Nítorí ìjọba ni tìrẹ, àti agbára, àti ògo, láyéláyé. Àmín.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Buls Sermon Notes Easter V". Christian.net. Retrieved 2020-01-07. 
  2. "Catechism of the Catholic Church - The summary of the whole Gospel". Vatican. Retrieved 2020-01-07. 
  3. Farmer, W.R. (1994). The Gospel of Jesus: The Pastoral Relevance of the Synoptic Problem. Westminster/John Knox Press. p. 49. ISBN 978-0-664-25514-5. https://books.google.com/books?id=KkO4qzxHrsEC&pg=PA49. Retrieved 2020-01-07.