Àgbékalẹ̀ Ẹ̀kọ́
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti Àgbékalẹ̀ Ẹ̀kọ́ (Lesson Note))
Àgbékalẹ̀ Ẹ̀kọ́ ni ó dá lè ìfọ́sí wẹ́wẹ́ ìlapa èrò olùkọ tí ol ùkọ́ ti pèsè kalẹ̀ ní kíkùn lórí ìgbékalẹ̀ bí ẹ̀kọ́ yóò ṣe ye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú iyàrá ìkẹ́kọ́. Ẹ̀wẹ̀, ojojúmọ́ ni olùkọọ́ gbọdọ̀ ma kọ ìlapa èrò ẹ̀kọ́ fún àsìkò ìkẹ́kọ́ kọ̀ọ̀kan ṣáájú kí ó tó wọ iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Èyí yóò mú kí ẹ̀kọ́ ó ye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lásìkò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn.[1] Àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ ma ń dá lè orí nkan mẹ́ta.
Àkọ́kọ́ ni: Kí ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní láti mọ̀? Èkejì: Ọ̀nà wo ni ẹ̀kọ́ yòó gbà yé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tàbí mọ ẹ̀kọ́ náà? Ẹkẹta ni: Báwo ni olùkọ́ yóò ṣe ṣe ìgbéléwọ̀n àgbọ́yé àwọn akẹ́kọ̀ọ́?
Àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ yí ni yóò ran olùkọ lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí lórí ètò ìkọ́ni rẹ̀ gbogbo. A [2]
Àpẹẹrẹ Àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nínú ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá a ó ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ wa báyí :
Orúkọ Olùkọ́ : Músá Adégúnjú
Orúkọ Ilé-ẹ̀kọ́ : Agóló High School
Iṣẹ́ : Èdè Yorùbá
Déétì : 12-01-2016
Àkókò : Ogójì Ìṣẹ́jú
Kókó Iṣẹ́ : Àṣà
Ìsọ̀rí Iṣẹ́ : Àṣà Ìkíni
Ìwé Ìtọ́kasí : Ìwé Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá Titun
Èròngbà : Olùkọ́ yóò kọ èròngba ẹ̀kọ́
Ohun Èlò Àmúṣe ye ni : Olùkọ yóò kọ́ síbẹ̀
Ìmọ̀ Àtiẹ̀yìn wá: Olùkọ yóò kọ ohun tí ó yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀
Ìfáàrà : Olùkọ yóò ṣe Ìfáàrà ẹ̀kọ́
Ìgbésẹ̀ Kíní : Olùkọ́ yóò ṣe ṣàlàyé Àṣà
Ìgbésẹ̀ Kejì : Olùkọ yóò sọ pàtàkì Àṣà
Ìgbésẹ̀ Kẹta : Olùkọ yóò kọ́ nípa ìkíni
Ìgbésẹ̀ Kẹrin: Olùkọ yó sèyàtọ̀ láàrín àwọn oríṣi ìkíni tí ó wà
Ìkádí : Ìbéèrè àti ìdáhùn
Ìgbéléwọ̀n : Olùkọ yó bèrè àwọn Ìbéèrè bóyá ẹ̀kọ́ náà ye àwọn akẹ́kọ̀ọ́
Iṣẹ́ Àmúrelé : Olùkọ á fún wọn ní àmúrelé
Nígbà tí Olùkọ yóò bá fi ṣe gbogbo ìwọ̀n yí Ogójì ìṣẹ́jú àt àbọ̀ yóò ti re kọjá. Àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ gbọ́dọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àlàklẹ̀ ètò Sílábọ́ọ́sì àti Kọ̀ríkúlọ́ọ̀mù.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ O'Bannon, B. (2008). "What is a Lesson Plan?". Innovative Technology Center * The University of Tennessee. Archived from the original on July 29, 2011. Retrieved May 17, 2011.
- ↑ "What Is A Lesson Plan?". English Club. Retrieved 15 October 2014.