Jump to content

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Mauritania

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní Mauritania
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiMauritania
Index caseNouakchott
Arrival date13 March 2020
(4 years, 8 months, 2 weeks and 5 days)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn5,923 (as of 21 July)[1]
Active cases2,136 (as of 21 July)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá3,632 (as of 21 July)
Iye àwọn aláìsí
155 (as of 21 July)

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ni wọn fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó dé orílẹ̀-èdè Mauritania ní oṣù kẹta ọdún 2020.

Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kíní ọdún 2020, àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) fìdí rẹ múlẹ̀ pé kòkòrò àrùn ẹ̀rànkòrónà ni ó fa àrùn atẹ́gùn ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú Wuhan ní agbègbè Hube, orílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ fún àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé (World Health Organization) ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2019.[2]

Ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 kéré púpọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ ti SARS tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2003,[3][4] ṣùgbọ́n bí àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ṣe ń káàká kiri pọ̀ púpọ̀ ní pàtàkì tí a bá wo iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí.[5]

Àwọn àkókò tí àrùn yí ń ṣẹ́yọ àti ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun rẹ̀.

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oṣú Kẹta Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ni wọ́n fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ múlẹ̀ tí wọ́n sì mú ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ kó àrùn yí lọ sí ibi ìyaraẹnisọ́tọ̀.[6]

Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ ní Mauritania, olú-ìlú Nouakchott sí ẹnìkan tí ó wá láti ìlú òkèrè tí wọn kò i ti dárúkọ orílẹ̀-èdè rẹ.[7] Lẹ́hìn ìgbàtí àbájáde àwọn àyẹ̀wò dé pẹ̀lú ìdánilójú, wọ́n fagilé àwọn ọkọ̀ òfurufú tí wọ́n ń lọ sí orílẹ̀-èdè Faranse

Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta, Mínísítà fún ètò ìlera ti ìlú Mauritania kéde ṣíṣe àwárí ènìyàn kejì tí ó dájú wípé ó ní àjàkálẹ-àrùn COVID-19. Ènìyàn yí jẹ́ arábìnrin àjèjì òṣìṣẹ́ kan tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní ilé àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n wá láti ìlú òkèèrè. Lẹ́hìn ọjọ́ kẹwàá tí arábìnrin yi dé ni wọ́n ṣe àwárí ìṣẹ̀lẹ̀ yí lára rẹ.

Ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀rànkòrónà kẹta ni wọ́n kéde rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta pé ó ṣẹlẹ̀ sí bàbá àgbàlagbà kan eni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́rin tí ó jẹ́ ará ìlú Mauritania tí ó padà dé sí ìlú Mauritania ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta láti orílẹ̀-èdè Faranse pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú ti ilẹ̀ Faranse.[8]

Orílẹ̀-èdè Mauritania ṣe àkosílẹ̀ ẹni àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ aláìsí ní ọgbọ̀n ọjọ́ kẹta ọdún 2020.[9] Ní ìparí oṣù kẹta, ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́fà ni wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ nígbà tí ènìyàn kan jẹ aláìsí, àwọn méjì gba ìwòsàn ó wá ṣẹ́ku ènìyàn mẹ́ta tí wọ́n ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́.

Oṣù Kẹrin Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kẹjìdínlógún oṣù kẹrin, ẹnití ó kẹ́yìn lára àwọn tí ó ṣẹ́kù tí àrùn yí ń bájà lọ́wọ́lọ́wọ́ gba ìwòsàn. Ní ọjọ́ ná à, wọ́n ti kọ́kọ́ fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ méje múlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Mauritania, èyí tí mẹ́fà nínú wọn ti gba ìwòsàn, tí ọ̀kan sì ti jẹ́ aláìsí. Eléyì í ló mú kí orílẹ̀-èdè Mauritania jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀, tí wọ́n ń kojú àrùn yí ní àgbáyé, tí wọ́n gba òmìnira lọ́wọ́ àrùn COVID-19 fún ìgbà díẹ̀.

Ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin, ọmọ orílẹ̀-èdè Senega kan ni àyẹ̀wò tí ó dájú fi hàn pé ó ní àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀rànkòrónà. Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ni ti arábìnrin ọmọ ọdún méjìdínláàdọ́rin kan tí ó n gbé ní Ìpínlẹ̀ Nouakchott.[10]

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun méjì ni ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù kẹrin, èyí tí ó mú kí iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ di mẹ́jọ. Iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí kò yí padà. Láàrín ọjọ́ kejìdínlógún àti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin, kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́o; arábìnrin tí àyẹ̀wò ti fi hàn pé ó ní àrùn yí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin nìkan ni àrùn yí ń bájà lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìparí oṣù kẹrin.

Oṣù kárùn ún Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kẹfa oṣù kárùn ún, pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, wọ́n mú kí òfin ìsémọ́lé rọrùn díẹ̀.[11] Nígbà tí oṣù kárùn ún má a fi parí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ti gòkè lọ sí 480 tí àwọn tí ó ti jẹ́ aláìsí ti gòkè lọ sí mẹ́tàlélógún. Iye àwọn tí wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ pé wọ́n ní àjàkálẹ̀-àrùn yí ti lọ sókè sí 530 ní oṣù kárùn ún tí àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n si ti gba ìwòsàn.

Oṣù Kẹfà Ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun 3,707 ni ó wáyé nínú oṣù kẹfà tí ó sì mú kí iye àwọn tí wọ́n fìdí rẹ múlẹ̀ wípé wọ́n ní àrùn yí di 4,237. iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí lọ sókè sí 128. Ní ìparí oṣù kẹfà, àwọn ènìyàn 2612 ni wọ́n ń ṣe àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́.

  1. "Coronavirus Update (Live)". www.worldometers.info (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-07-21. 
  2. Reynolds, Matt; Weiss, Sabrina (2020-02-24). "How coronavirus started and what happens next, explained". WIRED UK. Retrieved 2020-07-26. 
  3. "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2020-07-26. 
  4. "High consequence infectious diseases (HCID)". GOV.UK. 2018-10-22. Retrieved 2020-07-26. 
  5. Higgins, Annabel (2020-07-26). "Coronavirus". World Federation Of Societies of Anaesthesiologists. Archived from the original on 2020-03-12. Retrieved 2020-07-26. 
  6. "Mauritania confirms first coronavirus case". CNA. 2020-03-14. Archived from the original on 2020-03-14. Retrieved 2020-07-26. 
  7. Reuters (2020-03-13). "Mauritania confirms first coronavirus case". National Post. Retrieved 2020-07-26. 
  8. "تسجيل إصابة جديدة فيروس كورونا بموريتانيا". الأخبار: أول وكالة أنباء موريتانية مستقلة (in Èdè Árábìkì). 2020-03-26. Retrieved 2020-07-26. 
  9. "موريتانيا تعلن عن أول حالة وفاة بسبب "كورونا"". الأخبار: أول وكالة أنباء موريتانية مستقلة (in Èdè Árábìkì). 2020-03-30. Retrieved 2020-07-26. 
  10. "وكالة الأخبار المستقلة". Facebook‬ (in Èdè Latini). 2020-07-25. Retrieved 2020-07-26. 
  11. Newsroom, APO Group - Africa; (UNICEF), United Nations Children’s Fund. "Coronavirus". Africa Newsroom / Press release. Retrieved 2020-07-26.