Jump to content

Àjẹsára àrùn ìta

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àjẹsára àrùn ìta jẹ́ àjẹsára tó ní agbára púpọ̀ láti dènà àrùn ìta.[1] Lẹ́yìn ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo, iye àwọn ọmọ oṣù mẹ́ẹ̀sán tó pọ̀ tó 85% àti àwọn ọmọ tó ti ju oṣù méjìlá lọ tó pọ̀ tó 95% ni yóò ní agbára tó péye láti kojú àrùn náà.[2] Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo àwọn tí kò ní agbára àti kojú àrùn náà lẹ́yìn tí wọ́n bá gba ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ni wọn yóò ní agbára yìí lẹ́yìn ìwọ̀n egbògi náà kejì. Nígbàtí iye àwọn tó gba àjẹsára náà láàárín àwùjọ kan bá ju 93% lọ, àtànkálẹ̀ àrùn ìta kìí sábà wáyé mọ́; ṣùgbọ́n wọ́n ṣì tún lè wáyé bí ìwọ̀n àjẹsára gbígbà bá tún wálẹ̀ síi.

Núrsì kan ń fún ọmọdé ní abẹ́rẹ́ ajesára lẹ́yìn Typhoon Haiyan

Ipa àjẹsára náà a má a pẹ́ títí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Kò tíì yé ni bóyá ipa rẹ̀ a má a dínkù bí ó bá pẹ́. Àjẹsára náà tún lè dènà àrùn náà bí a bá fúnni láàárín ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti wà ní àyíká ibití àrùn náà gbé wáyé.[1]

Àjẹsára náà kò léwu láti lò, èyí sì kan àwọn tó ní àkóràn àrùn HIV pàápàá. Àwọn àtúnbọ̀tán kò ní ipá, wọn kìí sì pẹ́ rárá. Lára ìwọ̀nyí ni ìnira ní ojú ibi abẹ́rẹ́ náà tàbí ibà díẹ̀. A ti ṣe àkọsílẹ̀ ìfèsì ara ẹni lọ́nà òdì sí ohun tí ènìyàn kòrira lára iye àwọn ènìyàn tó tó ọ̀kan nínú ọgọ́ọ̀rún. Iye ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn àrùn bíi Guillian-Barre syndrome (nínú èyítí àwọn ẹ̀yà ara tí nkojú kòkòrò àrùn yóò bẹ̀rẹ̀ síí gbógun ti iṣan ara), autism (àrùn ọpọlọ tí nmú ni má lè sọ ọ̀rọ̀ tó já geere tàbí bá àwọn ẹlòmíràn ṣe ní àwùjọ) àti inflammatory bowel disease (àrún dídáranjẹ̀ ìfun) dàbí èyítí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́.[1]

Àjẹsára náà wà gẹ́gẹ́ bí èyí tó dá dúró fúnrarẹ̀ àti bí èyítí a ṣe pọ̀ pẹ̀lú àwọn àjẹsára mìíràn bíi àjẹsára rubella (àjẹsára àrùn ìta Jámínì), àjẹsára ṣegede, àti àjẹsára varicella (àjẹsára àrùn ọfà ṣọ̀pọ̀nná tàbí ilẹ̀gbóná) (àjẹsára MMR àti àjẹsára MMRV). Àjẹsára náà a má a ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ nínú gbogbo àwọn oríṣiríṣi àgbéjáde wọ̀nyí. Àjọ Ìlera Àgbáyé gbani nímọ̀ràn láti fúnni ní àjẹsára náà bí ènìyàn bá ti pé ọmọ oṣù mẹ́ẹ̀sán ní àwọn agbègbè ibití àrùn náà ti wọ́pọ̀. Ní àwọn agbègbè ibití àrùn náà kò ti wọ́pọ̀ rárá, fífúnni ní àjẹsára náà bí a bá ti pé ọmọ oṣù méjìlá bá ọgbọ́n mú. Ó jẹ́ àjẹsára tó wà láàyè. A má a wá bíi iyẹ̀fun gbígbẹ tí a gbọ́dọ̀ pò kí á tó fúnni yálà sábẹ́ awọ ara tàbí sínú ẹran-ara. Ṣíṣàyẹ̀wò bóyá àjẹsára náà ṣiṣẹ́ lè wáyé nípa ṣíṣe àwọn àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀.[1]

Bíi iye àwọn ọmọdé tó tó 85% káàkiri àgbáyé ni ó ti gba àjẹsára yìí ní bí ọdún 2013.[3] Ní ọdún 2008, ó kéré, àwọn orílẹ̀-èdè bíi 192 ni wọ́n ń fúnni ní ìwọ̀n egbògi náà méjì.[1] A ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ọdún 1963.[2] Àpapọ̀ àjẹsára àrùn ìta-àrùn ṣegede-àrùn ìta Jámínì (MMR) di wíwà fún lílò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1971.[4] Àjẹsára àrùn ọfà ṣọ̀pọ̀nná tàbí ilẹ̀gbóná (chickenpox vaccine) di ohun tí a fi kún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ní ọdún 2005, èyí tó wá di àjẹsára MMRV.[5] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[6] Àjẹsára náà kò wọ́n púpọ̀.[1]

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Measles vaccines: WHO position paper."
  2. 2.0 2.1 Control, Centers for Disease; Prevention (2014).
  3. "Measles Fact sheet N°286". who.int.
  4. "Vaccine Timeline".
  5. Mitchell, Deborah (2013).
  6. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).