Ibà
Ibà (Fever) jé ìlosókè igba die ti ìwọn otutu ara(eyi ti a mò sí "temperature) ju bi ose ye lọ. Ìwon otutu ara to ye wa laarin 36°C sí 37°C. Ibà fún rarè ki se aìsàn sugbon ibà le jé àìmì aìsàn, nitorina, ibà ki ṣe idi fun ijaya, ṣugbọn aisan ti o wa ní idi ibà náà le nílò itọju ilera, sùgbón sa, òpòlopò oni imo eto ara gbogbo pe bi iba ba koja ojó meji tàbí meta, oda kí ènìyàn lo rí dókítá. [1] [2]
Àwon aìsàn tàbí nkan to le fa ibà pèlú:
- Otútù
- àìsàn òtútù àyà
- Aìsàn ìtò(UTI)
Ibà le fa orí fífó, ara gbígbòn, lilagun jù, ìrora isan, ailera ara ati bebe lo.
Ibà je àìmì aìsàn ti owo po, ara ònà ti a fi wadi re ni nílo òsùnwàn ìgbóná(ti awon oyinbo n pe ni "thermometer"). Ònà itoju ma saba je títójù aìsàn ti o fa iba. Bi oti e je pe àwon òògùn bi paracetamol[3] le din awon àìmì ibà ku, imọran pataki ni lati kan si dokita ṣaaju lilo eyikeyi òògùn.
Wo eléyí náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
• Ako ibà
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
- "CareCentral Urgent Care 2020">"When to seek treatment for a fever". CareCentral Urgent Care. 2020-01-03. Retrieved 2022-02-18.
- Health direct 2021">"Paracetamol". healthdirect. 2021-07-18. Retrieved 2022-02-18.
- "Fever: Symptoms, Causes, Care & Treatment". Cleveland Clinic. Retrieved 2022-02-18.