Àjẹsára Meningococcal

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àjẹsára Meningococcal

Àjẹsára Meningococcal jẹ́ èyíkèyí àjẹsára tí a fi ń dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn kan tí à ń pè ní Neisseria meningitidis.[1] Oriṣiriṣi ẹ̀yá àjẹsára yìí lo ń ṣiṣé fún díẹ̀ nínú tàbí gbogbo oriṣi meningococcus: A, C,W135 àti Y. Ó kéré jù, àjẹsára yìí  ń ṣiṣé dáadáa láàrín 85 sí 100% fún ọdún meji gbáko.[1] Ó máa ń dínku meningitis àti sepsi láàrín ọ̀pọ̀ ènìyan níbi tí wọ́n ti ń lòó káàkìri.[2][3] Wọ́n máa ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yí sára gba inú iṣan tàbí abẹ́ ẹran ara.[1]

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbani nímọ̀ràn pé kí àwọn orílẹ̀ èdè tí àrùn náà ti ṣe rẹ́gí tàbị wọ́pọ̀ máa gba àjẹsára yìí lóòrèkóòrè.[1][4] Ní ìlú tí wọn kò b́ ti láàńfàní púpọ̀ lati kó àrùn yìí, wón gbani nímọ̀ràn wípé àwọn tí láàńfàní púpọ̀ lati kóo láàrín wọn gbódọ gba àjẹsára.[1] Ní apá ibìkan ní [[Africa|Áfíríkà]] níbí tí áàńfàní púpọ̀ lati kó meningitis, ìyànjú ń lọ lọ́wó lati ri wípé wọ́n gba abẹ́rẹ́ àjésára fún àwọn ènìyàn tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀ẹ̀rẹ̀ lati ọdún kan sí ọgbọ̀n ọdún.[4] Ní ilẹ̀ Kánádà àti Amẹ́ríkà, àjẹsára èyí tó ń ṣiṣé fụn oriṣi mẹrin meningococcus ni wọ́n máa ń gbà fún àwọ́n ọṃọ tí kò tíì bàlágà àti àwọn tí ó láàńfàní jùlọ lati kó àrún yìí[1] Ó tún pọn dandan fún àwọn tó ń lọ sí ilẹ̀ mẹ́kà fún Hajj.[1]

ààbò jẹ́ ohun tó dará púpọ. Àwọn mìràn máa ń ní ìrora àti pípọ́n lójú ibi tí wọ́n gba abẹ́ẹ́rẹ́ sí. [1] Lílò rẹ̀ nínú oyún kò léwu rárá.[4] àìbániláramu má ń ṣelẹ̀ lẹ́ẹ̀ksn nínú mílíọ́nù kan.[1]

Àjẹsára meningococcal di èyí tó wà fún lílò ní ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1970s.[5] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[6] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 3.23 àti 10.77 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[7] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ 100 sí 200 fún ìdá kan.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 "Meningococcal vaccines: WHO position paper". Weekly epidemiological record 47 (86): 521–540. Nov 2011. PMID 22128384. http://www.who.int/wer/2011/wer8647.pdf. 
  2. Patel, M; Lee, CK (25 January 2005). "Polysaccharide vaccines for preventing serogroup A meningococcal meningitis.". The Cochrane database of systematic reviews (1): CD001093. PMID 15674874. 
  3. Conterno, LO; Silva Filho, CR; Rüggeberg, JU; Heath, PT (19 July 2006). "Conjugate vaccines for preventing meningococcal C meningitis and septicaemia.". The Cochrane database of systematic reviews (3): CD001834. PMID 16855979. 
  4. 4.0 4.1 4.2 "Meningococcal A conjugate vaccine: updated guidance, February 2015.". Weekly epidemiological record 8 (90): 57–68. 20 Feb 2015. PMID 25702330. http://www.who.int/wer/2015/wer9008.pdf. 
  5. Barrett, Alan D.T. (2015). Vaccinology : an essential guide. p. 168. ISBN 9780470656167. https://books.google.ca/books?id=NvKyBwAAQBAJ&pg=PA168. 
  6. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF). World Health Organization. October 2013. Retrieved 22 April 2014. 
  7. "Vaccine, Meningococcal". International Drug Price Indicator Guide. Retrieved 6 December 2015.