Àjẹsára táífọ́ọ̀dù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sgt. Mildred Rosado Canales ń gba abẹ́rẹ́ Àjẹsára táífọ́ọ̀dù fún Capt. Buckley Kozlowski

Àjẹsára táífọ́ọ̀dù jẹ́ àjẹsára tí n dènà ibà táífọ́ọ̀dù.[1] Oríṣi méjì ni ó wà káàkiri: Ty21a tó jẹ́ àjẹsára tó wà láàyè, tí a sì má a n gba ẹnu fúnni, àti àjẹsára Vi capsular polysaccharide, èyí tó jẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára ẹlẹ́yọ.[1] Ìwọ̀n agbára wọn tó 30 sí 80% fún bí ọdún mẹta.[2][1]

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbani nímọ̀ràn pé kí a fún gbogbo àwọn ọmọdé tí n gbé ní àwọn agbègbè ibi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀ ní àjẹsára náà. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, wọ́n gbani nímọ̀ràn láti fún gbogbo àwọn tó wà lábẹ́ ewu nlá láti kó àrùn náà ní àjẹsára náà. Ìpolongo nípa gbígba àjẹsára ni a tún lè lò láti fi ṣàkóso ìtànkálẹ̀ àrùn náà. A gbani nímọ̀ràn láti gba àfikún ìwọ̀n àjẹsára náà láàárín ọdún kọ̀ọ̀kan sí méje-méje, bí a bá wo bí àrùn náà ti wọ́pọ̀ tó ní agbègbè náà.[1] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, a gbani nímọ̀ràn láti fún àwọn tó wà lábẹ́ ewu nlá níkan, bíi àwọn arìnrìnàjò lọ sí àwọn agbègbè ibi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀, ní àjẹsára náà.[3]

Àwọn oríṣi àjẹsára náà ti òde-òní kò léwu láti lò rárá. Àwọn àtúnbọ̀tán díẹ̀díẹ̀ lè wáyé ní ojú ibi abẹ́rẹ́ náà. Oríṣi àjẹsára náà tí à n gún fún ni bí abẹ́rẹ́ kò léwu fún àwọn tó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS láti lò, a sì lè lo oríṣi àjẹsára náà tí à n gba ẹnu fúnni níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn náà kò bá tíì ní àmì àrùn náà. Kò tíì yé ni bóyá oríṣi àjẹsára náà tí à n gba ẹnu lò léwu láti lò nígbàtí ènìyàn bá wà nínú oyún.[1]

Almroth Edward Wright, Richard Pfeiffer, àti Wilhelm Kolle ni wọ́n ṣe àgbéjáde àjẹsára táífọ́ọ̀dù àkọ́kọ́.[4] Nítorí àwọn àtúnbọ̀tán, àwọn àgbéjáde titun àjẹsára náà ni a gbani níyànjú láti lò.[1] Àwọn àjẹsára táífọ́ọ̀dù wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù[5] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 4.44 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[6] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó wọn jẹ́ 25 sí 50 USD.[7]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Typhoid vaccines: WHO position paper.". Releve epidemiologique hebdomadaire / Section d'hygiene du Secretariat de la Societe des Nations = Weekly epidemiological record / Health Section of the Secretariat of the League of Nations 83 (6): 49-59. 8 February 2008. PMID 18260212. http://www.who.int/wer/2008/wer8306.pdf?ua=1. 
  2. Anwar, E; Goldberg, E; Fraser, A; Acosta, CJ; Paul, M; Leibovici, L (2 January 2014). "Vaccines for preventing typhoid fever.". The Cochrane database of systematic reviews 1: CD001261. PMID 24385413. 
  3. "Typhoid VIS". CDC. 5/29/2012. Retrieved 15 December 2015.  Check date values in: |date= (help)
  4. Flower, Darren R. (2008). Bioinformatics for Vaccinology.. Chichester: John Wiley & Sons. pp. 40-41. ISBN 9780470699829. https://books.google.ca/books?id=Rg6-T_1-LWkC&pg=PA40. 
  5. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF). World Health Organization. October 2013. Retrieved 22 April 2014. 
  6. "Vaccine, Typhoid". International Drug Price Indicator Guide. Retrieved 6 December 2015. 
  7. Hamilton, Richart (2015). Tarascon Pocket Pharmacopoeia 2015 Deluxe Lab-Coat Edition. Jones & Bartlett Learning. p. 317. ISBN 9781284057560.