Jump to content

Àkókó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àkókó
Rockview in Ikare Akoko
Rockview in Ikare Akoko
Àpapọ̀ iye oníbùgbé
~ 815,360 (2011)
Regions with significant populations
Ondo State - 815,360

 · Akoko North East: 208,080
 · Akoko North West: 246,150
 · Akoko South East: 95,790
 · Akoko South West: 265,340

Èdè

Akoko languages · Akoko dialects of the Yoruba language

Ẹ̀sìn

Christianity · Yoruba religion · Islam

Adekunle Ajasin University, Akungba Akoko

Àwọn ènìyàn Àkókó ni wọ́n jẹ́ ẹ̀yà àti ìran Yorùbá tí wọ́n wà ní apá gúúsù àríwá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.[1] Ilẹ̀ Àkókó ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ibi tí ó di Ìpínlẹ̀ Òndó lóní títí dé Ìpínlẹ̀ Edo. Àwọn ẹ̀yà Yorùbá Àkókó ni wọ́n kó ìdá ogún ó lé ẹ̀sún mẹ́ta (20.3%) nínú ìdá márùn ún tó lé ẹ̀sún meje (5.7%) ènìyàn tí wọn ń gbé ní Ìpínlẹ̀ Edo. Ẹ̀Wẹ̀, agbègbè Àkókó ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin, àwọn ni: Akoko North-East, Akoko North-West, Akoko South-East àti Akoko South-West, tí ó fi mọ́ Akoko Edo LGA tí ó wà ní àárín Ìpínlẹ̀ Edo àti Ìpínlẹ̀ Ondo. Ilé ẹ̀kọ́ fásitì Adekunle Ajasin University náà wà nílú Àkùngbá Àkókó[2] Akungba-Akoko.[3] Bákan náà ni ilé-ìwòsàn ti ìjọba ìpínlẹ̀ wà ní ìlú Ikare Akoko, nígbà tí ilé-ìwòsàn gbogbo-gbòò ti ìjọba náà wà ní ìlú Ọ̀kà-Àkókó àti ìlú Ìpè-Àkókó.

Arigidi, jẹ́ ẹ̀ka èdè Àkókó tí wọ́n ń sọ ní ìjọba ìbílẹ̀ Akoko North East, Akoko North West, Ekiti East, àti Ijumu.

Agbègbè ilẹ̀ Àkókó

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilẹ̀ Àkókó ni ó ní àwọn ìlú kékèké àti abúlé tí wọ́n tó mẹ́tàdínláàádọ́ta tí wọ́n wà láàrín àwọn òkè àpáta ńlá ńlá ní Ìpínlẹ̀ Òndó.[4] Bóyá nítorí àwọn òkè òkè ńlá ńlá wọ̀nyí ni ó fàá tí oríṣiríṣi àwọn ènìyàn Yorùbá tókù fi ń tọ̀ wọ́n wá láti apá aríwá,gúúsù, ìwọ̀ àti ìlà Oòrùn ilẹ̀ Yorùbá yòókù tó fi mọ́ ẹ̀yà Yorùbá tókù gbogbo. Àwọn ẹ̀yà Àkókó nìkan nínú àwọn àyà Yorùbá yòókù ni wọn kò ní ẹ̀ka èdè kan pàtó tí ó so gbogbo wọn pọ̀ yàtọ̀ sí èdè Yorùbá. Díẹ̀ lára àwọn ìlú tí wọ́n wà ní abẹ́ Àkókó ni: Ọ̀kà-Àkókó, Ìkàrẹ́ Àkókó, Ọ̀bà, Ikun, Arigidi, Ùgbẹ̀, Ọ̀gbàgì, Òkèàgbè, Ìkárám, Ìbárám, Iyani, Àkùngbá, Erúṣú, Àjọwá, Àkùnù, Gedegede, Ìsùà, Àuga, Ìkakúmọ́, Ṣúpárè, Ẹpìnmì, Ìpè, Ìfira, Ìsẹ̀, Ìbòròpa, Ìrùn, Iye, Afin, Ìgáṣì, Ṣósàn, Ìpèsì, Etíòro, Ayégúnlẹ̀, Erítí àti Oyín Àkókó. [5]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]