Àwọn àdúgbò ìlú Iléṣà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ILÉSÀ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Àdúgbo: Ìkótì Ìtumò: Ìbí yìí ni àwon omo ogun Ìjèsà gbà lé àwon òtá won ni ìgbà ogun ni èyí, èka ède ló fà á tí ó fi jé Ìkótì.

2. Àdúgbo: Bíládù Ìtumò: Orúko owá ketàlá tó jè ni Ilésà ni Bíládù Arère, ìrántí rè ni won fi so àdúgbò yìí ni orúko rè. Nìgbà tí ò ti dé orí oyè, ó wá gbajúmò débi pé fí àwon èèyàn ba n lo si àdúgbò yen, dígbò ki won so pe àwon n lo si ògbón wón á ni àwon n lo sí ilé Bíládù bí wón se so ó àdúgbò yìí di Bíládù nìyí

3. Àdúgbo: Ota pèté Ìtumò: ibi tí àwon jagunjagun Ìjèsà pelu àwon omo Ogun Èkìtì ti pàdé ní ìgbà Ogun ni àdúgbò yìí torí pé ota ìbón pò ni ilè ibi yìí léyìn Ogun yìí ni won se so o ní ota pèté.

4. Àdúgbo: Omi Asorò Ìtumò: Omi kan wà ni àdúgbò yìí tí won ń pè ni asorò tori omi yìí ni won se so àdúgbò yìí ni omi-asorò.

5. Àdúgbo: Orinkùnràn Ìtumò: Àwon ènìyàn gbà pé igbó tí ó wà ni àdúgbò yìí ni ìgbà àtijó ni àwon abàmì lópòlópò eni tó sì mú ki won gbà pé òràn ni yóò ri, Orìn-ken-òràn (èdè Ìjèsà) O rìn kan òràn.

6. Àdúgbo: Ìdí àyàn Ìtumò: Igi ààyàn kan wà ní agbègbè yìí tele èyí ló fàá tí won fi so àdúgbò yìí ní ìdí àyàn.

7. Àdúgbo: Ita-Balogun Ìtumò: Àdúgbò yìí ni ilé Obalógun Ilesa wà ní àkókò ti won so orúko àdúgbò yìí (Ìta-Obalogun).

8. Àdúgbo: Mùrókò Ìtumò: Ibi yìí kojá ibi tí ìrókò kan wà díè, èyí ló fà á ti won fi so pe o-mu-iroko (èdè Ìjèsà) ìtumò-mu-iroko nip é ó kojá ìrókò mùrókò.

9. Àdúgbo: Isarè Ìtumò: Ibi tí àwon Haúsá ń gbé tí won sí ti n ta ojà, àlejò ni arè ní èdè Ìjèsà

10. Àdúgbo: Ìdásà Ìtumò: Àwon tí won ón dá ara won sà sí ònà kan ni ìtumò ìdásà, àwon kan kúrò ni àárín ìgboro, wón sì lo da àdúgbò yìí sílè ni won ba so o ni Ìdásà.

11. Àdúgbo: Òkè-Padre Ìtumò: (Páàdì) Ibi yìí ni àwon Òyìnbó ìjo Rátólíkì tí a gbà pé won mu ìgbàgbó wá ń gbé nígbà yen ni òkè-Páàdì.

12. Àdúgbo: Arágan Ìtumò: Eni tí ó kókó dá àdúgbò yìí sílè bínú kúrò láàrin àwon ènìyàn lo dá dúró síbè ni, èyí ni awon ènìyàn fì so ibè ní arágan torí pé, wón gbà pé ìwà eni tí ó kókó dé àdúgbò yìí kò jot i ènìyàn tó kù lò fàá to fi wá dá àdúgbò tirè sílè.

13. Àdúgbo: Bámúso Ìtumò: Òtè ló gbé àwon tó kókó de adugbo yìí dé ibè torí pé wón ń gbèrò láti yan olóyè láàrin ara won, Owá gbó èyí ló bá lé won kúrò ni ibi tí won ti wá télè.

14. Àdúgbo: Ìlórò Ìtumò: Àwon tí ó kókó dé adúgbò yìí jè ólòwó pàápàá àwon tí ó kókó jáde to se awo ni èyìn odi tí won fi wá n kólé sí ilé.

15. Àdúgbo: Òkè èsó Ìtumò: àdúgbò yìí ni won ti máa n ta aso àwon oyinbo nigba tí àwon kòráà kókó gbé aso títà dé Ilesa, ìdí niyi ti won fi n pè é ni Òkè-eso.

16. Àdúgbo: Ìsònà Ìtumò: Ibi tí àwon tó ma n se isé onà pò jù sí láyé àtijó, ìtàn so fún wa pé ibè ni won ti máa n hun òpá àse àti ìlèkè owá, tí àwon ìyàwó rè àti àwon olóyè.

17. Àdúgbo: Ìgandò Ìtumò: Ìgi ìgandò kan náà ló wà ní àdúgbò yìí láyé àtijó.

18. Àdúgbo: Òkè-Ayò Ìtumò: Àwon désìn kinyó ló so àdúgbò yìí ni òkè ayò nígb`atí won kó ilé ìjósìn ati ibi ìsojí àti lé isun won síbè.

19. Àdúgbo: Omo-Ofe (Omife) Ìtumò: Ìtàn so pé àdúgbò yìí àwon omo ogun ti níláti gbéra lati sigun lo sibi ti won ti fé jagun. Béè náà ni won sì gbódò wá jábò ti won si pin enìati erú tí wón kó bò lójú ogun.

20. Àdúgbo: Ìlájé Ìtumò: ìbi tí ará ìgboro ti má a ń wá pàdé àwon ará oko láti ra ojà lówó won èyí ló fà á tí wón fi so àdúgbò yìí ní Ìlájé.

21. Àdúgbo: Òkè Ìrò Ìtumò: Orúko igi kan tó wà ládùgbóò yìí télè ni wón fi so àdúgbò yìí

22. Àdúgbo: Odò Ìrò Ìtumò: Ibi tí ó bó sí aopá ìsàlè ní adúgbò òkè ìrò ni odò ìrò

23. Àdúgbo: Ìjòfì Ìtumò: ibí yìí ni wón ti máa n aso ofì nígbà tí ó kókó dé Ilésà.

24. Àdúgbo: Ìkòyí Ìtumò: Àdúgbò yìí jè ìbi titun tí òpòlopò àwon tí ó fi jáde nílùú tipé tipé ń gbé òpòlopò won lo ti Èkó wá kólé síle, ojú tì wòn fi wo ìkòyí Estate l’Ekoo ni won fi mu àdúgbò náà.

25. Àdúgbo: Enú Odi Ìtumò: Ibí yìí ni ìlú parí si látijó sùgbón ìlú ti fe séyìn si i ju ibí yìí lo

26. Àdúgbo: Adétí Ìtumò: Ibi tí àwon Ìbòkun dúró dí nígbà tí ogún parí ti won wá láti dúpé lówó Owá ti o ràn wón lówó láti segun òtá wòn (A-de-eti-owá) À dé tòsí ilé Owá Adètí Owá.

27. Àdúgbo: Ìjòkà Ìtumò: Àwon ará Òwò ló so adúgbò yìí lórúko yìí, àgbàdo ni won máa n tà níbè télè bóyá àgbàdo tí won máa n dàpè ní okà ló fa orúko yìí.


28. Àdúgbo: Ìmàdín Ìtumò: Ní ìgbà àtijó àwon ìyá àgbà má a n se àdín níbí yìí (Ùmàdín)

29. Àdúgbo: Temìdire Ìmàdín Ìtumò: àdúgbò titun tó jáde lara Ìmàdín nìyí

30. Àdúgbo: Omo Olúpè Ìtumò: Òríkì èèyàn tí ó kókó kólé sí àdúgbò yìí ni won fi pe ibí yìí.

31. Àdúgbo: Òkèsà Ìtumò: Ìkòkò ni àwonìjèsà máa ń dà á pè ní ìsà. Àdúgbò yìí sì ni wón ti máa ń ná oyà ìkòkò saájú kí ilésà tó di ilé-ìsà.

32. Àdúgbo: Ìsòkùn Ìtumò: Ìsò okùn ló di ìsokùn yìí, ibè ni àwon àgbè àti elému ti máa ń wá okùn láti fid i erù tàbí òpe-emu won ní ìgbà láéláé.

33. Àdúgbo: Ìdí Ose Ìtumò: Igi osè ńlá kan ló wà ní ìbí yìí ni ìgbà láéláé tí àwon ènìyàn máa ń dúró ta ojà mí abé rè.

34. Àdúgbo: Ìdí Ògún Ìtumò: Ìbí yìí ni wón ti máa ń bo ògún owá ní ìgbà àtijó, wón sì máa ń pa ajá ògún sí ibé yìí títí di oní.

35. Àdúgbo: Ìta Akogun Ìtumò: Ibí yìí ni àwon ológun máa ń dúró sí de àwon òtá ní ìgbà láéláé, ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ní ìta akogun.

36. Àdúgbo: Adétí Ìtumò: Àgékúrín fún “A dé etí owá” mí èyí, ibè ni àwon ará ìbòkun dúró sé nígbà tí ogun parí tí wón fé wá dúpé lówó owá-omo-Ajíbógun tó ràn wón lówó láti ségun àwon Ìlàré.

37. Àdúgbo: Ìbàlá Ìtumò: Òrúko akoni kan tó wá láti ìbòkun sùgbón tó wolè láàrin ìlésà àti ìbòkun nígbà tí ó gbó pé ogun ti pa ìyàwó àti omo òun mi ìbòkun.

38. Àdúgbo: Erégúrìn Ìtumò: Orí egúrù ló di Erégúrù, ìlè tó le ló wà ní ibí yìí télè àwon omodé sì máa ń seré níbè.

39. Àdúgbo: Ìsònà Ìtumò: Ibi tí àwon tó má a ń se isé onà pò jù sí láyé àtijó ìtàn so fún wa pé ibè ni wón ti máa ń hun òpá ńlèkè owá, tí àwon Olóyè rè àti ti àwon ìyàwó rè.

40. Àdúgbo: Araromi Ìtumò: Orúko ìgbàlódé ní èyí, Arágan ni orúko àdúgbò yìí télè wón sèsè yíi padà sé Aráròmí ni

41. Àdúgbo: Ìtinsin Ìtumò: Ìgi Isis ńlá kan ló wà ní ibí yìí télè tí àwon ènìyàn máa ń ta ayò ní idi rè èyí ló di ìtà-isin lónìí (Ìhnsin).

42. Àdúgbo: Bólórundúrò Ìtumò: Orúko tuntun ni orúko àdúgbò yìí nítorí pé àwon tó kókó dé ibè kò tètè kólé kan ara won, wón gbà pé àwon bá olórun dúrò.

43. Àdúgbo: Ìgbàyè Ìtumò: Ní ìgbà ogun, Ibí yìí ni àwon Ológun ìjèsà gbà láti sá àsálà fún èmí won. “Ibi tí a gbà tí a fi yè”ni àpèjá rè.

44. Àdúgbo: Eréjà Ìtumò: Orí ojà ni wón gé kúrú sí Eréjà, ibí yìí ló jé bíi oríta fún gbogbo àwon ìlú kékèèké ibè sì ni wón ti máa ń pàdé láti ta ojà won.

45. Àdúgbo: Ìkòyí Ìtumò: Àdúgbò tuntun ni èyí, àwon tó sì fún un ní orúko yìí yá a lò láti ìlú Èkó ni.

46. Àdúgbo: Omi-Oko Ìtumò: Àdúgbò tí omi tí àwon ènìyàn máa ń pon ní ayé àtijó, omo yìí wà ní ìtòsí ibi tí wón máa ń dá oko sí, èyí ni wón fi máa ń pè é ní omi-oko.

47. Àdúgbo: Enu-Odi Ìtumò: Ibí yìí ni ilésà dé ní àkókò yìí, èyí ló fà á tí wón fi ń pe ibí yìí ní Enu-Odi.

48. Àdúgbo: Ìróyè Ìtumò: Ìróyè yìí kò jìnà sí ìgbàyè, ibè ni àwon tó sá fún èmí won ní ìgbà ogun ti kókó dúró.

49. Àdúgbo: Ìlórò Ìtumò: Àwon tí ó kókó dó àdúgbò yìí jé olówó, pàápàá wón jé òkan lára àwon tó kókó jáde lo sòwò ní òkè oya tí wón wá ń kólé sílé.

50. Àdúgbo: Òlómilágbàlá Ìtumò: Àdúgbò yìí kò jìnà sí omi kan tí àwon ènìyàn máa ń mu, èyí ló jé kí àwon ènìyàn máa pe àwon tó ń gbé àdúgbò yìí ní òlómilágbàlá.


51. Àdúgbo: Ògbón Àgbède Ìtumò: Àgbède kan wà ní àdúgbò yìí ní àkókò tí wón fún un ní orúko yìí, omo Èfòn alààyè ni àgbède yìí.

52. Àdúgbo: Òkè-jìgbà Ìtumò: Òrúko Babaláwo kan ni Jìgbà, àdúgbò yìí ló sì máa ń gbé tí ó ti ń se isé owo rè. ìdí nìyí tí wón fi ń pe àdúgbò náà ní òkè-jìgbà.

53. Àdúgbo: Òkè-omi-irú Ìtumò: Òmi kan wà ní ibí yìí tí wón ti máa ń fo irú ní ayé àtijó, ìgbà tí àwon ènìyàn téèrè sin í kólé omi irú.

54. Àdúgbo: Omi-Aládìe Ìtumò: Oko kan wà ní ibí yìí ní ìgbà àtijó tí wón ti máa ń sin adie (poultry) omi kan sì wà ní ìtòsí oko yìí, èyí ló mú kí won máa pe omi yìí ní omi aládìe èyí tó di o’ruko àdúgbò náà lónìí.

55. Àdúgbo: Olórunsògo Ìtumò: Àdúgbò yìí ti wà láti ìgbà láéláé sùgbón àwon ènìyàn kò tètè wá ko ilé sí ibè, nígbà tí ó sì yá ààrin ìgbà díè ni àwon ènìyàn kó òpòlopò ilé sí ibè, èyí ló mú kí won pè é ní Olórunsògo.

56. Àdúgbo: Ìjámo Ìtumò: Ibí yìí ni àwon àgbè tó bá ń bò láti oko ti máa ń já imò òpe láti di erù won ibè ló di Ìjámò nígbà tí ilé bèrè si ní de ibè.

57. Àdúgbo: Ògúdù Ìtumò: Orúko akíkanjú kan ni ìgbà ogun ògèdèǹgbé ni èyí, ní ìrántí rè ni wón se so àdúgbò yìí ní ògúdù.

58. Àdúgbo: Ìfòfín Ìtumò: Òmi kan wà ní àdúgbò yìí télè tí àwon ènìyàn ti máa ń do nǹkan, torí omi yìí ni wón se so àdúgbò yìí ní Ìfofín.

59. Àdúgbo: Omi-Eran Ìtumò: Ibi tí àwon alápatà ti máa ń pa eran won fún títà ni wón so di omi-eran.

60. Àdúgbo: Imàdín Ìtumò: Ibi tí àwon ìyá àgbà ti máa ń se àdín ní ìgbà àtijó ni wón ń pè ní Umàdín ní èka èdè ìjèsà, èyí ló sì di Imàdín lónìí