Àwọn àdúgbò ìlú Ilé-Ifẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ILÉ-IFẸ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Àdúgbo: Ìjíó Ìtumò: Agbolé yi jé ibi tí òsùpá ìjíó wà ìdí nìyí tí wón fi ńpè ni ìjíó


2 Àdúgbo: Ìrémo Ìtumò: Ìwádìí so fún wa wípé nígbà tí òrànmíyàn fé wolè ó so fún àwon àgbà ifè wípé tí won bá tí ní ìsòre kí wón má pé òuni kò pé ní àwon àláìgbàgbó kan bí lope láìsí ìsòrò bí óse fí ìbínú jáde sí wón tí ó sí ńbe wón lórí lo ibè ní àwon àgbègbè bá le pàdé rèní wón bá so fún wípé kó má bínú pé àwon omorè náà ní bí àwon àgbàgbà se so wípé Ìré-lórí-mo Iremo.

3. Àdúgbo: Lókòóré Ìtumò: Àgbolé yí jé ibi tí wón má ń sin àwon tó bá pokùnso sí idi ní tí wón fí máń pè ní lókòóré

4. Àdúgbo: Ajàgbuà Ìtumò: Nípa sè erú ní orúko yíi ti je jáde erú kan ti olówó kan ni agbègbè yíi ni óni ogún ni ojó kan wón níkí o gun orí àjà lo láti lo sisé ó gún orí àjà naa ó sì bímo sí ibè osì so wípé láti ojó naa ni aboyún àdúgbò naa yo tí má bímo sí orí àjà àwon tí kò sí tèlé ohun tí ó so omo yìí, omo won ń bèrè sí ń ku.


5. Àdúgbo: Arùbidi Ìtumò: Ni àdúgbò yíi isu ti ó dára pò ni ibè, ìdí ni wípé wón ńbe ógbin isu ògbìn isu daradara íbè wón sí má ń di isu ní ìdì, bí ìdi ní, ìdi nìyí tí wón se ń pe ni Arùbidì

6. Àdúgbo: kééku Ìtumò: Eku ní wón sábà má ń rú ní àdúgbò yí àti egúngún ìdí nìyí lí wón se ń pen í Kééku

7. Àdúgbo: Ìtaakogun Ìtumò: Orúko àdúgbò yìí je yo ni pa sè olóyè Akogun, ìta olóyè Akogun ni wón so di Itakogun.

8. Àdúgbo: Oyárò Ìtumò: Ìtàn so wípé oya ni ó rò sí àdúgbó yìí

9. Àdúgbo: Igótàn Ìtumò: Jé ibi ti wón má ń sin àwon tó bá kú pèlú oyún síi

10. Àdúgbo: Àgbàgbànyagbà Ìtumò: Ènìyàn kan tí ó tì Ibòmíràn wá ti ó sì wá di olówó àti olórò jù eni tó gba látì dúrò lo.

11. Àdúgbo: Àpáta Ìtumò: Jé ibi tí wón má ń sin àwon tí ó bá fori sole kú síi

12. Àdúgbo: Ìta àgbon Ìtumò: Jé Ibì tí àgbon pò sí ni wón fi ń pè ní Ìtà àgbon.

13. Àdúgbo: Enuwá Ìtumò: Ìtàn so wípé àdúgbò yí jé bi tíó jé àlà nígbà tí ifè àti ilésà fé má jà sí ilè wón wá so wípé kí àwon mó jà pé tí ó bá din í òla kí á jí sí ònà kí á pàdé ara sùgbón àwon ilésà kò sùn sùgbón ifè tí sùn ìgbàtí wón má jí ilésà tí dé òdò won, wón wá wò pé Enu owá la ó ma pe àdúgbò yi Enuwa.

14. Àdúgbo: Agbèdègbede Ìtumò: Àdúgbò yí jé ibi tí wón ti má ń ro okó àti àdá àwon Àgèdè

15. Àdúgbo: Edènà Ìtumò: Orúko àdúgbò yíi wá nipa sè wípé ó jé Ogbà tí olórun fí Adámù àti Éfà sin i ìsèdálè ayé gégébí ase mò.


16. Àdúgbo: Ìtajéro Ìtumò: Àdúgbò yi jé ibi tí odùduwà àti àwon omo rè ti jo se Àjorò kí wón tó pín yà.

17 Àdúgbo: Lúwoo Ìtumò: Àdúgbò yí jé yo nípa sè lúwon gbágidá tí ó jé óbìnrin àkókó tí ó jé òòni

18. Àdúgbo: Abéwéla Ìtumò: Àdúgbò yí jé yo nípa sè oba Adékúnlé Abewéla

19. Àdúgbo: Ìrésùmi Ìtumò: Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo òrànmíyàn.

20. Àdúgbo: Osògún Ìtumò: Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo ògún lákoko olójó.

21. Àdúgbo: Obaláyan Ìtumò: Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Èsù-Obásan.

22. Àdúgbo: Obadíó Ìtumò: Àdúgbò yì je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Òduduwà.

23. Àdúgbo: Ìlárá Ìtumò: Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Obàlùfòn.

24. Àdúgbo: Olópo Ìtumò: Adúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Orè.

25. Àdúgbo: Òkè-Itasè Ìtumò: Àdúgbò yí ní òrúnmìlà dé sí nígbà tí o de sí ilú ilé-Ifè.

26. Àdúgbo: Èsìnmìrìn Ìtumò: ó jé ibi odò tí wón tí fí Èlà, tí ń se omo morèmi rúbo, òun ní wón sínpè ní, Mòkúrò.

27 Àdúgbo: Ajígbáyín Ìtumò: Àdúgbò yí jé yo nípa sè ìyá Oba adésojí Adérèmí tó jé àfé kéhìn tí ó má gbá àwon imín àwon eran tí ó má ń wá níta ilé wón òun ní wón wá so dí ajígbáyín

28. Àdúgbo: Okùnora Ìtumò: Àdúgbò yí jé yo nípa sè olóyè tó má ń bo Elésìje.

29. Àdúgbo: Igbó-ìtàpá Ìtumò: Jé ibi tí won má ń sin àwon tí ó bá kú pèlú Oyún si.

30 Àdúgbo: Jétanwo Ìtumò: (Enuwa Square) Eni tí ó te agboolé náà dó ni orúko rè ń jé Jétawo, Ìdí nìyí tí wón fi so ilé náà ní jétawo.

31. Àdúgbo: Ìta-Òsun-Ilé-Lówá Ìtumò: Nígbàtí kò sí ààyè mó láti kólè sí mó ní ilé-Jétewo (Enuwa) Àwon omo Àkàntìokè wá lo sí Adugbo Ìtà-Òsun. Ìdí nìyí tí wón fi máa ń so wípé Enuwa kò gbàà yè, lówá yalémo ó lo Ìta-òsun.

32. Àdúgbo: Moremi Ìtumò: (Ìlórò Square) àdúgbò morèmi jé Àdúgbò ibi tí ojúbo òrìsà morèmi wa.

33. Àdúgbo: Òkè-Atan Ìtumò: Àdúgbò yí jé ibi tí omí-odò kan tí won ń pè ní Atan wa, ìdí nìyí tí won fi ń pe Àdúgbò náà ní Òkè-Àtan.

34. Àdúgbo: Láfogídó Ìtumò: Àdúgbò yí ni Oba Láfogído wolè sí, ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní Láfigído.

35. Àdúgbo: Sèru Ìtumò: (Enuwa Square) Oba Olófin pe sèru láti Ìta-ye mò ó wá sí agbègbè Enuwá láti wá tèdó. Ìdí nìyí tí wón fi so Àdúgbò náà ní Ilé-Sèru.

36. Àdúgbo: Alákàá Ìtumò: Orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó ni Alákàá. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní Ilé-Alákàá.

37. Àdúgbo: Òròkó Ìtumò: (Enuwa Square) Òkòrí ni orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó.

38. Àdúgbo: Àlútú Ìtumò: (Enuwa Square) Orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó ni Àlútú.

39. Àdúgbo: Àká Ìtumò: (Enuwa Square) Àká ni orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó.

40. Àdúgbo: Obàloràn Ìtumò: Orúko eni tí ó te àdúgbò yí dó ni Ogua Ògìdigbo, O yè ti o jé ni Obaloran, isé ré nip é ó ní àse láti gbésè lé èsè késè ti àwon ènìyàn tàbí ará ìlú bá dá. èyí túmò sí Oba-ló ni òràn. Ìdí tí won fi so àdúgbò yí ni Agboolé Obàloràn.


41. Àdúgbo: Odù Ìtumò: (Ilódè-Oríyangí Square). Ní ayé àtijó, eni tí ó bá kó isé-Ifá, tí ó tó àkókò láti ní Odù-Ifá, ilé tàbí àdúgbò yí ni wón máa ń lo láti gba Odù-ifá náà.

42. Àdúgbo: Ogbón-Oya Ìtumò: (Láàkáyè) Láakáyè ni oruko eni tí ó te àdúgbò yí dó. Àdúgbò yí tún jé ibi tí won ti máa ń bo Oya. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ni Ògbón-Oya.

43. Àdúgbo: Obàsa o Ìtumò: (Oríyangí) Eni tí ó te agboolé yí dó jé Aláwo. Ìdí nìyí tí won fi so ilé tàbí àdúgbò yí ní Ilé-Obàsa o.

44. Àdúgbo: Òpá Ìtumò: (Èdènà) Orúko eni tí ó te àdúgbò láà dó ni Òpá, Ìdí nìyí tí won fi so agboolé náà ní ilé-Òpá.

45. Àdúgbo: Omìtótó: Ìtumò: Orúko ìyàwò Obalòràn ni ó ń jé omìtótó, òun ni eni tí ó te àdúgbò náà dó.

46. Àdúgbo: Déboóyè Ìtumò: Orúko eni tí ó te agboolé náà dó ni Déboóyè.

47. Àdúgbo: Ìdú Ìtumò: Orúko eni tí ó te agboolé náà dó ni won Ìdú-Oládère. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní Ilé-Ìdú.

48. Àdúgbo: Lákòró Ìtumò: (Ojà-Ifè) Orúko eni tí ó te agboolé náà dó nì ó ń jé Olákòró.

49. Àdúgbo: Òjájá Ìtumò: (Mòòrè Square) Oba òjájá ni ó te Àdúgbò náà dó.

50. Àdúgbo: Ìtàpá Ìtumò: Àdúgbò ibi yí jé ibi tí Ojúbo Obàtálá wà. Òpá tí won máa ń ta tabi ní gbàtí wón bá ń se odún Obàtálá. Ìdí nìyí tí won fi ń pe àdúgbò náà ní Igbó-Ìtàpá.

51. Àdúgbo: Obalásè Ìtumò: Obalásè jé orúko eni tí o máa ń bo Olúorogbo, òun sin i eni tí te àdúgbò Obalásè dó.

52. Àdúgbo: Obalùbo Ìtumò: Ilé yìí jé ilé tí won ti máa ń bo Odùduwà.

53. Àdúgbo: Njasa Ìtumò: Oníjà-kìí-sá ni Orúko eni tí ó te àdúgbò yí dó. Ìdí nìyí tí wón fi so àdúgbò náà ní Njasa. 54. Àdúgbo: Oláyodé Ìtumò: Ilé yìí jé agbo ilé tí won ti máa ń je oyè ní ayé àtijó, sùgbón nígbà tí ó yá won kò rí omo okùnrin tí yóò je oyè mó, nígbà tí ó pé òkan lára àwon ìyàwó agbo ilé náà bí omo Okùnrin kan, èyí tí won fi je oyè náà, tí won sì ń pe orúko rè ní Oláyodé orúko olóyè yìí ni wón fi so agbo ilé náà tí won fi ń pèé ní Oláyodé.

55. Àdúgbo: Olókó Ìtumò: Ilé Olókó jé ilé tí a mò sí ilé àgbède tí ó jé pé isé okó ní isé tí won. Kò wá sí orúko tí àwon ènìyàn lè fi pè wón, wón bá so ilé won ní ilé Olókó.

56. Àdúgbo: Ààre-Òjè Ìtumò: Agbo ilé yìí jé agbo ilé Eléégún, eni tí ó jé olórí àwon eléégún yìí ni a ń pè ní Ààre-òjè. Orúko rè ni àwon ènìyàn fi so agbo ilé yìí.

57. Àdúgbo: Jagun Ìtumò: Ilé Jagun ni ilé tí àwon ènìyàn mò gégé bíi ilé Olóógun, nígbà tí ayé sì wà láìsí omo ogun rárá. Eni tí ó je olórí Ogun nígbà náà ni Jagun. Wón wá so agbo ilé rè di ilé Jagun nínú ìlu.

58. Àdúgbo: Òjóbàtá Ìtumò: Bàbá kan ní agbo ilé yìí tí orúko rè ń jé òjó tí ó féràn láti máa jó ijó bàtá ni à ń pè ní Òjóbàtá tí a fi so agbo ilé yìí ní Òjóbàtá.

59. Àdúgbo: Baba Alásé Ìtumò: Asé ni wón máa ń hun nínú ilé yìí bíi isé e won ìdí nìyí tí a fi so agbo ilé náà ní ilé Baba Alásé

60. Àdúgbo: Badà Ìtumò: Agbo ilé yìí ni a ti máa ń je oyè Badà. Ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Badà.

61. Àdúgbo: Baálè-Àgbè Ìtumò: Agbo ilé yìí ni wón ti máa ń je Oyè Baálè-Àgbè ìdí nìyí tí won fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Bálè-Àgbè

62. Àdúgbo: Baba-Elégún Ìtumò: Ní ìgbà àtijó Okùnrin kán wà tí ó jé elégun tí àwon ènìyàn máa ń pè ní Baba-Elégun, nínú ilé náà ìdí nìyí tí àwon ènìyàn fi ń pe agbo ilé náà ni ilé Baba-Elégún.

63. Àdúgbo: Máyè Ìtumò: Orúko Oyè won ní agbo ilé yìí ní Máyè, ìdí nì yí tí a fi ń pe ilé náà ní ilé Máyè.


64. Àdúgbo: Àgòrò Ìtumò: Agbo ilé yìí ni wón ti máa ń je Oyè Àgòrò, ìdí nìyí tí a fi ń pe ilé náà ní ilé Àgòrò.

65. Àdúgbo: Baálè Ìtumò: Orúko Oyè tí won ń je bákannáà ní agbo ilé yìí, ni wón fi ń pe ilé náà ní ilé Baálè

66. Àdúgbo: Eléyelé Ìtumò: Eyelé ni wón ń sìn gégé bí ohun òsìn nínú ilé yìí, ìdí nìyí tí a fi ń pe ilé náà ní agbo ilé Eléyelé.

67. Àdúgbo: Alusèkère Ìtumò: Ìlé yìí jé ilé tí won ti máa ń lu sèkèrè, ìdí nìyí tí wón fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Alusèkèrè.

68. Àdúgbo: Olóni Ìtumò: Ní agbo ilé yìí ni wón ti ń sin òni, ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Olóní.

69. Àdúgbo: Basòrun Ìtumò: Orúko oyè won ní agbo ilé yìí ni Basòrun, òun náà ni a sì fi ń pe agbo ilé yìí.

70. Àdúgbo: Ààre ìlù Ìtumò: Okùnrin kan ní agbo ilé yìí ni à ń pè ní Ààre ìlù tí ó jé olórí àwon onílù, Orúko rè ni a fi so agbo ilé yìí.

71. Àdúgbo: Dáódù Ìtumò: Agbo ilé yìí ní ayé àtijó ni àkóbí oba tí à ń pè ní Dáódù kó ilé sí, ìdí nìyí tí wón fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Dáódù.

72. Àdúgbo: Ìkólàbà Ìtumò: Agbo ilé yìí ni ilé tí agbápò sango ń gbé, agbápò sàngó yìí ni à ń pè ní ìkólàbà, ìdí nìyí tí a fi n pe agbo ilé náà ní ilé Ìkólàbà.

73. Àdúgbo: Arífájogún Ìtumò: Ní ayé àtijó eni tí ó jé baálé ilé náà onífá ni, sùgbón nígbà tí ó kú tán, gbogbo àwon omo ìlé náà àti ègbón àti àbúrò ni won ń se èsìn ifá yìí, ìdí nìyí tí wón fi so agbo ilé náà ní agbo ilé Arífájogún.

74. Àdúgbo: Olóólà Ìtumò: Agbo ilé yìí ni àwon tí won máa ń ko ilà fún àwon ènìyàn wa. ìdí nìyí tí a fi ń pe ilé náà ní ilé Olóólà


75. Àdúgbo: Baba-Ìsàlè Ìtumò: Ní ayé àtijó ní agbo ilé yìí àwon egbé kan fi baba àgbàlagbà kan je baba ìsàlè inú egbé e won, ilé tí baba yìí ń gbé ní àwon ènìyàn so di agbo ilé Baba-ìsàlè.

76. Àdúgbo: Seriki Ìtumò: Agbo ilé yìí ni eni tí ó jé Olórí àwon alápatà tí à ń pè ni Séríkí ìnú ìlú náà wà, agbo ilé tí ó ń gbé ni à ń pè ní agbo ilé Séríkí.

77. Àdúgbo: Alókońgbó Ìtumò: Orúko agbo ìlé yìí ń tóka sí ilé tí wón ti ń dá oko ju, tí won sì ní oko jù ní inú ìlú, ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Alókońgbó.

78. Àdúgbo: Aládìe Ìtumò: Láti ayébáyé ni onílé yìí ti ń sin adìe, kí ó tó kú, núgbà tí ó sì túnkú àwon omo rè náà tun ń sin adìe náà. ìdí nìyí tí àwon ènìyàn fi so agbo ilé náà ní ilé Aládìe

79. Àdúgbo: Asúnmádódò Ìtumò: Agbo ilé yìí jé agbo ilé tí ó súnmó Odò, tí awon ènìyàn si so di agbo ilé Asúmádódò.

80. Àdúgbo: Anísulájà Ìtumò: Láti ayábáyé ní agbo ilé yìí ni a ti rí àwon àgbè tí ó jé pé isu kìí wón ní orí àjà won, títí tí àgbodò fi máa ń dé, ìdí nìyí tí won fi so agbo ilé náaà ní agbo ilé Anísulájà.

81. Àdúgbo: Alájá Ìtumò: Ilé yìí ni ilé tí wón ti máa ń sin ajá lópòlopò fún títà, tí àwon ènìyàn sì ń pe agbo ilé náà ní ilé Alájá.

82. Àdúgbo: Alaro Ìtumò: Ilé yìí ni ilé tí eni tí ó máa ń lu aro wà tí ó ń gbé, tí àwon ènìyàn sì ń pe agbo ilé rè ní ilé Alaro

83. Àdúgbo: Baba-tedé Ìtumò: Ìlé yìí jé ilé tí baba kan àti ìyàwó re wá tèdó sí láti ìlú Tedé tí wón sì bímo sí ibè tí won sì di púpò ní agbo ilé náà. ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé baba-Tedé.

84. Àdúgbo: Ìrédùmí Ìtumò: Nípa sè Èrédùmí tí ó jé Olusìn Òrànmíyàn tí ó sì ma ń fún oòni tí ó bájé ní idà.

85. Àdúgbo: Odùduwà Ìtumò: Àdúgbò yìí ni Odùduwà wolè sí. Wón sì ń pe àdúgbò yìí ni odùduwà fún ìrántí.


86 Àdúgbo: Olúrìn Ìtumò: Wón ń fi orúko yìí rántí Gómìnà ìpínlè òyó àná fún isé ribiribi tí ó gbé se.

87. Àdúgbo: Òpa Ìtumò: Bàbá tí a ti ipasè rè n pe Òpa ni Akíngbolá. Agbo ilé yìí wà ní ègbé àfin Oba.

88. Àdúgbo: Pédrò Ìtumò: Àdúgbò yìí ni wón fi ń se ìrántí pédrò gan-an fún rarè tí ó gbé ìgbé-ayé tí o burú jojo.

89. Àdúgbo: Adérèmí Ìtumò: Àdúgbò yìí ni a fí ń se ìrántí Oba àná tí ó wà jà

90. Àdúgbo: Ajámopó Ìtumò: Bàbá ològùn ni ó te ibè dó, Orúko yi wá jásí aláki ajámopó, Bàbá olóógùn yi ma ń já omo nínú apó ni wón so di ajámopó.

91. Àdúgbo: Ìta òsun Ìtumò: Òsun kan wà tí orúko re ń jé òjìyàn ibè ni okúka kán wá tóní ojú ihò méje gégé bi poón ayò tí enikéni kò mò enití ó gbe ìdí èyí ni wón fi sodi ìta òsun.

92. Àdúgbo: Oke Isoda Ìtumò: Okùnrin kan lo ma ń gba ibè lo sí inú oko rè nígbà tí ń kan rè dàgbà tan olè ma ń wo inú oko rè lo, ìgbà yen ni bale la ojú ònà ibè ìdí èyí ni wón fi ń pe nì òkèsòdà.

93. Àdúgbo: Ìta Yosùn Ìtumò: Ibití oòni Ilé Ifè bòǹsè rè sí nígbà tí wón bá ń se odún òrìsà kan tí a ń pè ní jùgbè ìta ni wón sì ti ma ń se odún náà ni wón so di ìtasìn

94. Àdúgbo: Òkèràwè Ìtumò: Ìdí tí wón fi ń pen í òkèrèwè nip é ògbón ni ojó, nígbà tí enití ó te ibè dó fi so pé òun á kó ilé òun sí orí òkè níbí ibè ni wón so di òkèrèwè.

95. Àdúgbo: Fájuyì Ìtumò: Ògbón nì o náà ń jé ifájuyì ni wón ń pe ttélè nígbà tí enìkan kú tí wón sì dá Ifá níbè pé kí wón ma gbé òkúrè àfi tí wón bá sin sì ibè, bíwón se bèrè sip è ní fájuyì nìyàn.

96. Àdúgbo: Ilugbade Ìtumò: Omo aládé ni wón ń jé télè, nígbà tí wón dá Ifá tí ifá mú enití adé tósí ni wón sí bèrè sí pe ibè ni lúgbadé


97. Àdúgbo: Dógbónya Ìtumò: Ògbón ni ibè ń jé ògbón Oya yen wón ti ibì kan ya wá ni wón wá te ibè dó ni wón fi kó ilé síbè bíwón se bèrè sí pè wón ni ògbón-oya.

98. Àdúgbo: Ìlórò Ìtumò: Àwon ará ilé òpá ni wón, níbè ni wón tí so pé àwon ń lo si oko àwon ni olórò ni wón fi ń pé gbogbo ibè ni ìlórò.

99. Àdúgbo: Wánísàní Ìtumò: Àwon ìdílé Obaláyè ni wón ní ibè sùgbón òkè kúta ni wón n pe ibè òkè kúta pò níbè ni wón fí so ibè di wánísánì òkè kúta

100. Àdúgbo: Odò Yàrá Ìtumò: Omi tí ó wà níbè láyé ni wóni sì ti ma ń pon omi náà bíwón se so ibè di odo Yàrá.

101. Àdúgbo: Òtutù Ìtumò: Obu ìjéta ni ó je oba níbè ibi tí agbo ilé náà wa ni wón ń pe nì ìta-òtutù bí wón se so ibe di otutu niyen.

102. Àdúgbo: Látalè Ìtumò: Ìdí tí wón fi ń pe ibè ni látalè ni pé ilè ni wón ń tà níbè ni ayé àtijó, bí wón se so ibè di látalè (compound)

103. Àdúgbo: Iyékéré Ìtumò: Ìdí tí wón fi ń pé ni yèèkéré ni pé nígbà tí enití ó te ibè dó bèrè si pin ilé fún won ní won bèrè sí so pé yèèkéré ìdí èyí ni won fi ń pen i ìyékéré.

104. Àdúgbo: Ìgboyà Ìtumò: Ní ayé àtijó ènítí ó te igbó òyà dó ni okùnrin. Òyà ni ó sì ma ń pa nítorí pé kò sí isé nígbà náà ju isé ode lo bíwón se bèrè síí pe ibè ni ìgboyà.

105. Àdúgbo: Aroko Ìtumò: wón ń pe ibè ní aroko nítorí pé oko ni wón ma ń jù ní gbogbo ojó ayé wón ìdí nìyen ti wón fi ń pen i aroko.

106. Àdúgbo: Oǹdó rodù (Road) Ìtumò: ó jé sírítí tí wón ma ń gbà lo sí òndó bí wón se bèrè sip é ni òndó Road ojú ònà, òndó.

107. Àdúgbo: Ìtà olópo Ìtumò: Ìdí tí ó fi á jé orúko náà ní pé wón ma ń jòró opó ni àdúgbò náà ìdí nìyen ti ó fi ń je ìtáolopo

108. Àdúgbo: Òrunobadó Ìtumò: Ìdí pàtàkì ti o fi á jé òrunobadó nip é ni ayé àtijó tí oba bá fé wàjà tí ó bá ti wo odò tàbí kànga náà á lo sí òrun bí wón se bèrè sip é ni òrunobado nìye

109. Àdúgbo: Jaàrán Ìtumò: Ní àdúgbò jàrán yi àrán ni wón ń jàn nibe láyé àtijó bíwón se bèrè sí pen i jàrán nìyan.

110. Àdúgbo: Agesinyówá Ìtumò: Ní ayé àtijó bàbá kan wá tí ó má ń gun esin yówá sí àdúgbò náà láti ìgbà yen ní wón ti bèrè sip e ibè ní agesinyówá.

111. Àdúgbo: Ògbón àgbàrá Ìtumò: àdúgbò ògbón àgbàrá yìí àgbàrá ma ń sàn níbè gan ti wón sì ma ń fi igbá gbón omi náà kúrò lónà, bí wón se so ibè di ògbón àgbàrá.

112. Àdúgbo: Igbódò Ìtumò: Ìgbódò jé ìdílé tí wón ti ma ń gbé odó ìgbà tí enití ó ń gbé odó náà kú ni wón bèrè sí so ibè di igbódò.