Àwọn ìkún omi ní Nàìjíríà ní ọdún 2022
Ìrísí
Àwọn ìkún omi tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2022 ya wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ní orílẹ̀ èdè. Gẹ́gẹ́ bí ìjọba àpapò ṣe sọ, ìkún omi náà mú kí àwọn ènìyàn tí ó lé ní mílíọ̀nù kan pàdánù ilé àti ọ̀nà wọn, ó pa àwọn ènìyàn ẹ̀ta lé ní ẹgbẹ́ta, ó sì ṣe àwọn ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ́éjìlá léṣe. Àwọn ilé tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógọ́rin sì ló ti bà jẹ́.[1]
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìkún omi ma ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà ní ẹ̀kọ̀kan, ìkún omi ọdún 2022 jẹ́ èyi tí ó fa ìdààmú jù láti ìgbà tí ìkún omi ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2012 ní Nàìjíríà..[2]
Òjò líle wà lára àwọn ǹkan tí ó fa ìkún omi yìí àti ṣíṣí omi láti Lagdo Dam ní orílẹ̀ èdèCameroon. Ìkún omi, tí ó ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà, Niger, Chad, àti àwọn agbègbè, bẹ̀rẹ̀ ní oṣù karùn-ún, ó sì dáwọ́ dúró ní oṣù kẹsàn-án.[3][4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Oguntola, Tunde (2022-10-17). "2022 Flood: 603 Dead, 1.3m Displaced Across Nigeria – Federal Govt" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-11-07.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedNYT
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedBBC
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedAP2022-11-16