Àwọn ṣòro igun aago

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Àwòrán yìí ṣe àfihàn àwọn igun àfọwọ́ṣe tí ó n ṣàfihàn agogo méjì lé ogún

Àwọn iṣòro igun aago jẹ́ irú ìṣòro ìṣirò tí ó ní ṣe pẹ̀lú wíwá àwọn igun láàrín àwọn ọwọ́ aago àfọwọ́ṣè.


Ìṣòro ìṣirò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ṣòro igun aago ṣe àkàwé àwọn ìwọ̀n méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: igun àti àkókò. Wọ́n ma a ń wọn igun pèlú degree lati ààmì iye méjìlá sí apá ọ̀tún. Àkókò yìí dá lórí aago wákàtí méjìlá.


Ọ̀nà tí à ń gbà sọ àwọn ìṣòro yìí di pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ìyípadà igun ní degree fún ìṣẹ́jú kan. Ọwọ́ wákàtí fún déédé wákàtí méjìlá aago àfọwọ́ṣe ń yípo  360° ní  àwọn wákàtí méjìlá (ìṣẹ́jú 720) tàbí 0.5° fún ìṣẹ́jú kan. Ìṣẹ́jú ọwọ́ yí má a ń yípo nípasẹ̀ 360° ní àwọn ìṣẹ́jú 60 tàbí  6° fún ìṣẹ́jú kan.[1]

Ìbádọ́gba fún igun ti ọwọ́ wákàtí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ní ibi tí:

  • θ jẹ́ igun àwọn degree tí ìwọn ọwọ́ ìwọ̀n ìyípo apá ọ̀tún láti méjìlá
  • MΣ jẹ́ àwọn ìṣẹ́jú tí ó kọjá aago méjìlá .
  • H jẹ́ wákàtí yẹn .
  • M jẹ́ àwọn  ìṣẹ́jú tí ó kọjá wákàtí yẹn.

Ìbádọ́gba fún igun ti ọwọ́ ìṣẹ́jú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • θ jẹ́ igun àwọn degree tí ìwọn ọwọ́ ìwọ̀n ìyípo apá ọ̀tún láti ipò aago méjìlá.
  • M jẹ́ ìṣẹ́jú yẹn.

Àpẹẹrẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkókò yẹn ni  5:24. Igun yẹn ní àwọn degree ti ọwọ́ wákàtí ni:

Igun yẹn mí àwọn degree ti ọwọ́ ìṣẹ́jú ni:

Ìbádọ́gba fún igun ti láàrín àwọn  ọwọ́ yẹn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A lè rí igun tí ó wà  láàrín àwọn ọwọ́ yẹn nípasẹ̀ lílo àgbékalẹ̀ yìí:

ní ibi tí

  • H ti jẹ̣́ wákàtí
  • M ti jẹ̣́ ìṣẹ́jú

Tí igun yẹn bá  180 degree, kí a yọọ́ kúrò ní 360 degrees

Àpẹẹrẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkókò yẹn jẹ́ 2:20.

Ní ìgbà tí ọwọ́ wákàtí àti ìṣẹ́jú aago bá wà lórí ara wọn?[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọwọ́ wákàtí àti ìṣẹ́jú ma ń wà lórí ara wọ́n nígbà tí igun wọn bá jẹ́ bákan náà.

H jẹ́ odidi láàárín  0–11. Èyí fún wa ní ìlọ́po: 0:00, 1:05.45, 2:10.90, 3:16.36, 4:21.81, 5:27.27. 6:32.72, 7:38.18, 8:43.63, 9:49.09, 10:54.54, àti 12:00. (ìṣẹ́jú 0.45 jẹ́ déédé aáyá 27.27 .)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Elgin, Dave (2007). "Angles on the Clock Face". Mathematics in School (The Mathematical Association) 36 (5): 4-5. JSTOR 30216063. 

Àwọn ìjápọ̀ látìta[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]