Èébì
Vomiting | |
---|---|
Miracle of Marco Spagnolo by Giorgio Bonola (Quadroni of St. Charles) | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta |
Èébì tí a tún mọ̀ sí ebi tàbí èbìbì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni kí ikùn tàbí inú ẹni ó ma ru bàlà nígbà tí àwọn ohun tí a ti ja tàbí mu sínú ń gba ẹnu tàbí imú jáde síta pẹ̀lú agbara.[1]
Oríṣiríṣi nka ni ó lè fàá kíènìyàn ó ma bì, lára rẹ̀ ni inú kíkún, tí ó túmọ̀ sí wípé óúnjẹ kò dà nínú ènìyàn.[2] Ohun mìíràn tí ó tún lè ṣokùnfà èébì ni kí ènìyàn ó jẹ májèlé tàbí kí ènìyàn ó ní àrùn ọpọlọ bíi túmọ̀, tàbí kí ọpọlọ ènìyàn ó gbóná ju bí ó ti yẹ lọ látàrí ooru ati bèẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àárẹ̀ tí ó ma ń sọni nígbà tí ó bá fẹ́ ṣe bí ọwọ́ kan èébì ni a ń pe ní ìhúnrìrà, amọ́ kìí sábà jásí èébì lọ́pọ̀ ìgbà. Ohun tí a lè ló láti fi dẹ́kun àárẹ̀ ìhúnrìrà ati èébì ni a pè ní Antiemetic. Lópọ̀ ìgbà tí àpọ̀jù èébì bá fa kí omi ó fẹ́ri lara ènìyàn, a lè lo omi tí wọ́n ń pe ní intravenous láti fi ṣẹ́gun rẹ̀. Nígbà tí ènìyàn bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí ó lè mú kí ó bì sílẹ̀ ni a lè pè ní ìjẹ-kú-jẹ tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pe ní Bùlímíà, èyí sì lè fàá kí ènìyàn ó máa yàgbẹ́ gbuuru. [3]
Kí ènìyàn ó máa bì yàtọ̀ sí kí ènìyàn ó máa ní àjẹpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n ma ń lo gbólóhùn méjèèjì fúnra wọn. Àjẹpọ̀ ní tìrẹ ni kí ènìyàn ó pọ ohun tí ó ti ẹ gbémì fúnra rẹ̀ padà wá sí ẹnu láìsí wàhálà kan kan, tí onítọ̀hún sì tún ní ànfaní láti gbé ohun tí ó pọ̀ yí mì padà pẹ́lú ìrọ̀rùn lẹ́ni tí ó ń gbádùn adùn tí ó wà nínú òúnjẹ náà.
Àwọn itọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Tintinalli, Judith E. (2010). Emergency Medicine: A Comprehensive Study Guide (Emergency Medicine (Tintinalli)). New York: McGraw-Hill Companies. p. 830. ISBN 978-0-07-148480-0.
- ↑ K.L., Koch (2000). "Unexplained nausea and vomiting". Current Treatment Options in Gastroenterology 3 (4): 303–313. doi:10.1007/s11938-000-0044-5. PMID 11096591.
- ↑ "New Eating Disorder: No Binge, Just Purge". 20 September 2007.