Èdè Esan

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Esan
Ishan
Sísọ níNigeria
Ọjọ́ ìdásílẹ̀2022
Ẹ̀yàEsan people
Èdè ìbátan
Niger-Kóngò
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-3ish

Esan jẹ́ èdè alohùn ti Edoid ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n ń ṣe àgbẹ́jáde àwọn ìwé atúnmọ̀ èdè ti Esan lọ́wọ́ lọ́wọ́. Oríṣiríṣi ẹ̀ka èdè Esan ló wà, bíi Ogwa, Ẹkpoma (Ekuma), Ebhossa (Ewossa), Ewohimi, Ewu, Ewatto, Ebelle, Igueben, Irrua, Ohordua, Uromi, Uzea, Ubiaja àti Ugboha.[1]

Àwọn ẹ̀ka èdè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni àwọn ẹ̀ka èdè ti Esan, tí Osiruemu (2010) ṣàkójọ:[2]

Orúkọ tó gbajúmọ̀ Orúkọ èdè ní Esan Agbègbè tí wọ́n ti ń sọ ọ́ Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀
Ekpoma Iruekpen Ekuma Iruekpen Akahia, Ayetoro, Egoro, Amede, Eguare, Egoro Eko, Oikhena, Idoa, Igor, Izogen, Uhiele, Ujeme, Ukpenu, Urohi, idumebo, ihumudumu Esan West
Ewatto Ebhoato Okhuesan, Emu, Okhuedua Esan South East
Igueben Igueben Ebele, Uzebu, Uhe, Ebhosa, Ekpon Igueben
Ilushi Ilushi Oria, Onogholo, Uzea, Ugboha Esan South East
Irrua Uruwa Egua Ojirua, Atwagbo, Isugbenu, Usenu, Uwesan, Ugbohare, Ibori, Edenu, Ibhiolulu, Opoji Esan Central
Ogwa Ujogba Ogua Ugiogba Ujogba, Amahor, Ugun Esan West
Ohordua Okhuedua Ohordua, Ewohimi Esan South East
Ubiaja Ubiaza Eguare, Kpaja, Udakpa Esan South East
Udo Udo Udo, Ekpon, Ekekhen Igueben
Ugbegun Ugbegun Ugbegun, Ugbegun Ebodin, Ekekhen, Ewossa, Ujabhole, Ugbelor Esan Central
Ugboha Owaha Emu, Oria, Ilushi Esan South East
Uromi Urhomwun Uzea, Obeidun, Ivue, Ibhiolulu, Awo, Amendokhen, Ebulen, Ekomado, Uwesan Esan North East

Ìlò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ènìyàn láti ìlú Uromi, Irrua àti Ewu máa ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí ti Esan, ìyẹn tí a bá fi wọ́n wé àwọn ará Uzea, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn fi yé wa pé àwọn ará Uromi àti Uzea ní ìbátan kan náà.[3] Àwọn ìyàtọ̀ nínú èdè àti sípẹ́lì ọ̀rọ̀ wọ́pọ̀ nínú èdè Esan. Ọ̀pọ̀ àwọn ìpàdé àwọn lọ́balọ́ba máa ń wáyé ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ wọ́n kéde rẹ̀ pé èdè Esan ṣe pàtàkì gan-an. Wọ́n máa ń kọ́ èdè yìí káàkiri àwọn ilé-ìwé tó wà ní ilẹ̀ Ẹsan, wọ́n sì máa ń lò ó ní orí rédíò àti orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán. [4]

Àwọn orúkọ tó wọ́pọ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn onímọ̀ èdè tí ṣàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ yìí ‘gbe’ ló ní ìlò tó pọ̀ jù lọ nínú èdè Esan, tó sì ní tó ìlò mẹ́rìndínláàádọ́rin (76), àti ìtumọ̀ nínú ìwé atúmọ̀ èdè. Àwọn orúkọ tó ní àwọn àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ bíi Ọsẹ; Ẹhi, Ẹhiz tàbí Ẹhis; àti Okoh (fún ọkùnrin), Okhuo (fún obìnrin) ló wọ́pọ̀ jù lọ nínú èdè Ẹsan. Àpẹẹrẹ ni Ehizefe, Ẹhizọkhae, Ẹhizojie, Ẹhinọmẹn, Ẹhimanre, Ẹhizẹle, Ẹhimẹn, Ẹhikhayimẹntor, Ẹhikhayimẹnle, Ẹhijantor,Ehicheoya,Emiator àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.; Ọsẹmundiamẹn, Ọsẹmhẹngbe, etc.; Okosun, Okojie, Okodugha, Okoemu, Okouromi,Okoukoni, Okougbo, Okoepkẹn, Okoror, Okouruwa, Oriaifo etc. Sí àwọn orúkọ bíi Oko-, 'Ọm-' wọ́n máa ṣe àfikún àfòmọ́ ẹ̀yìn sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ọmosun, Ọmuromi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn álífábẹ́ẹ̀tì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Esan máa ń lo oríṣiríṣi álífábẹ́ẹ̀tì, àmọ́ ti ilẹ̀ Róòmù ló wọ́pọ̀ jù, ó sì ní álífábẹ́ẹ̀tì márùndínlógún, àwọn ni:

a, b, d, e, ẹ, f, g, h, i, j, k, l, m, n, o, ọ, p, r, s, t, u, v, w, y, z.

Àwọn dáyágíráàfù náà jẹ́ mẹ́wàá nínú èdè náà, àwọn ni:

bh, gb, gh, kh, kp, kw (wọn ò kì í fi bẹ́ẹ̀ lò ó), mh, nw, ny, sh.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Welcome To Esanland Edo state Nigeria". www.edoworld.net. Retrieved 2020-12-19. 
  2. Osiruemu, Evarista. 2010. A structural dialectology of Esan. Doctoral dissertation, University of Ibadan.
  3. Aluede, Charles O.; Bello, Abayomi O. (2016-08-02). "Amojo Amen-Niyeye: a study in Esan minstrels". EJOTMAS: Ekpoma Journal of Theatre and Media Arts 5 (1–2). doi:10.4314/ejotmas.v5i1-2.7. ISSN 2449-1179. 
  4. Nardini, Robert (2000-04-01). "Op-Ed-Opinions and Editorials-Johannes Gutenberg, Publishing Chaos and Ebooks". Against the Grain 12 (2). doi:10.7771/2380-176x.3064. ISSN 2380-176X.