Jump to content

ÌFÁÀRÀ LÓRÍ ÀÀLỌ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìfáàrà lórí àlọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá, ní ìgbà tí kò tíì sí ètò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí ó wà lóde òní, ọ̀rọ̀ àt'ẹnu dé ẹnu ni àwọn bàbá ńlá wa máa n fi ń ṣe àkọsílẹ̀ àwon ìṣẹ̀lẹ̀ ti o bá ṣẹ̀ . Wọn a máa fi irú ìtàn tí wọn bá lẹnu àwọn baba wọn yìí fún ìran tí ó bá tẹle won. Fún àpẹẹrẹ , àwọn bàbá yóò sọ ìtàn fún àwọn ọmọ won, nígbà tí irú ọmọ bẹẹ náà bá sì di bàbá , òun náà yóò sọ irú ìtàn bẹẹ fún àwọn ọmọ tirẹ náà . Lára àwọn ọmọ iru awọn ọrọ àt'ẹnu d'ẹ́nu tí a ń sọ ní ìtàn , àróbá ati ààlọ́. Ni ojú ewé yii, ààlọ́ ni a ó máa gbé yẹ̀wò.[1]

Ààlọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onírúurú ọ̀nà ti àwọn Yorùbá máa n gba ṣe ìtọ́ni, ìkìlọ̀, ìbániwí, ati bẹẹ bẹẹ lọ fun àwọn ènìyàn wọn. Ààlọ́ jẹ́ ìtàn tó n ṣe àkàwé ohun kan pẹ̀lú èkejì. Lọpọlọpọ ìgbà , Ààlọ́ a máa níí ṣe pẹ̀lú eranko sí eranko, eranko sí ènìyàn , tàbí awon oun abẹmi míràn ti Aṣẹ̀dá dá sínú ayé, lẹẹkọọkan ààlọ́ a maa jẹ mọ́ àwọn ẹ̀dá tí a kò le fi ojú lásán rí.

Pèpele tí a gbé ààlọ lé jẹ́ ìgbà láéláé nígbà tí a gbà gbọ́ wípé ènìyàn àti ẹranko ń sọ èdè kan náà. Ní àkókò yìí , a gbàgbọ́ wípé ọ̀run àti ayé sún mọ́ ara wọn tó bẹ́ẹ̀ tí ìrìnàjò lọ bọ kò ṣòro fún ènìyàn tàbí fún ẹranko nítorípé a gbà gbọ́ wípé ọkàn ènìyàn kò kún fún ẹgbin àti ìwà ìkà bí òde òní .

Ẹni tí kò mọ àṣà fún ìbágbépọ̀ ìrọ̀rùn pẹ̀lú àwọn ènìyàn àyíká rẹ̀, kò lè yangàn pé òun mọ ojúṣe òun fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú àwùjọ gan-an tó ń gbé, débi tí yóò mọ ojúṣe rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ lápapọ̀ (Awóníyì, 1975:363). Nítorí ìmọrírì òdodo ọ̀rọ̀ pé “ilé la ti í kẹ́sọ̀ọ́ rode”, ló fi yẹ pé kí gbogbo ọmọ Yorùbá kọ́kọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò ojúṣe wọn bó bá tọ̀nà, kí wọn tó lè kópa tó gúnmọ láwùjọ gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè yìí nínú jíjẹ́ ìpè ìjọba.

Ipò pàtàkì ni Yorùbá to àlọ́ sí lágbo ńlá lítíréṣọ́ nípa kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àṣà. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ‘lílò’ tí Bascom dábàá gẹ́gẹ́ bíi tíọ́rì tó tọ̀nà jù lọ láti máa fi ṣe àtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ àti àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ gbogbo, bí ìtàn ìwáṣẹ̀ àti fókìlọọ̀ (Dorson, 1972:21). Ẹ̀dá inú àlọ́ ni apàlọ́ hun àṣà tó fẹ́ fi kọ́ àwùjọ̀ lọ́gbọ́n mọ́ lára. Lára ohun tí apàlọ́ ń kíyè sí kó tó gbé ìṣẹ́ fún ẹ̀dá yòówù ó jẹ́ nínú àlọ́ ni bí àbùdá, ìrísí, ìṣesí àti ìhùwàsí tí apàlọ́ ti mọ̀ mọ irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ṣe lẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ irú iṣẹ́ tí a fẹ́ gbé fún un náà (Finnegan, 1967:344-346). Fún àpẹẹrẹ, iṣẹ́ tí í fi èrè ìwà ọ̀dàlẹ̀, tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun, ọgbọ́n àrékérekè, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ọgbọ́n ìjàǹbá hàn ni apàlọ sáábà ń rán alábahun Ìjàpá nínú àlọ́ (Babalọlá, 1973).

         Nígbà tí àpàlọ́ bá fẹ́ rán ahun nírú iṣẹ́ báwọ̀nyí, ó sáábà ń fi ẹ̀dá mìíràn tí ìhùwàsí àti àbùdá rẹ̀ lòdì sí ti alábahun ta ko Ìjàpá. Dípò pé kí apálọ́ (olùsẹ̀dá àlọ́) jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tó fẹ́ fi ìtàn inú àlọ́ náà kọ́ àwùjọ hàn ní kíákíá, ó máa ń fún àwọn ẹ̀dá inú àlọ́ náà láyè láti tayò àmúlò àṣà tàbí ọgbọ́n rere àti búburú, bó tílẹ̀ jẹ́ pé àṣà tàbí ọgbọ́n tí apàlọ́ gbàgbọ́ pé ó wúlò, tó sì fẹ́ fi kọ́ àwùjọ ni yóò pàpà jẹ́ kó borí ọgbọ́n tí àwùjọ lòdì sí, ṣùgbọ́n tó ti fún ẹ̀dá inú àlọ́ náà lò ní àlòtẹ́rùn. Níbi tí àwọn ẹ̀dà inú àlọ́ ti ń tàkòtó àmúlò ọgbọ́n ni ẹ̀kọ́ inú àlọ́ ti í hàn sí olóye ènìyàn kí apàlọ́ wá tó fa ọgbọ́n yọ ní ìkádìí àlọ́, pàápàá fún ọmọdé.

         Fún àpẹẹrẹ, nínú àlọ́ ‘Ìjàpá Rí Ilẹ̀ tí ó lójú’ (Babalọlá, 1973b:70) ni apàlọ́ ti fi ìwà sùúrù, ìwà pẹ̀lẹ́ àti làákàyè ẹyẹlé ta ko ìwà ojúkòkòrò, ànìkànjopọ́n àti àrékérekè alábahun Ìjàpá. Nígbà tí apàlọ́ náà ń hun ìtàn inú àlọ́ nàá pọ̀ mọ́ àwọn olú ẹ̀dá tó lò, ìjàpá, ẹyẹlé, àna ẹyẹlé, abbl., ó mú kí àwọn olú ẹ̀dá ìtàn méjèèjì, ìjàpá àti ẹyẹlé, máa yí ara wọn sébè àti sí poro nípa àmúlò ọgbọ́n. Bí alábahun ti ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí a mọ̀ ọ́n mọ́ jẹ ẹyẹlé níyà, náà ni ẹyẹlé ń fi ìwà sùúrù àti làákàyè jàjàgbara. Nítorí ẹ̀kọ́ tí apàlọ́ fẹ́ fi kọ́ àwùjọ nínú àlọ́ náà, pé ‘àkọ́dá oró kò dà bí oró àdágbẹ̀yìn’, ó fi àyè gba alábahun Ìjàpá láti kọ́kọ́ fi ọgbọ́n àrékérekè jẹ ẹyẹlẹ́ níyà kí apàlọ́ ọ̀hún tó wá fún ẹyẹlé láyè láti fi hàn pé bẹbẹ ọgbọ́n kò pin sọ́dọ̀ ẹni kan ṣoṣo.

         Lára àwọn ìwà burúkù tí a ti mọ̀ mọ alábahun Ìjàpá, tí a sì fún un láyè láti hù tẹ́rùn nínú àlọ́ òkè yẹn ni ìwà àìsòótọ́, àìṣeégbẹ́kẹ̀lẹ́, àrékérekè, wọ̀bìà, ojúkòkòrò, ahun, àṣerínikójẹ, àjẹkì, ọ̀kánjúà, àgàbàgebè, òfófó, ìfèrúgbàbùkún àti ẹnu-àìmẹ́nu. Gbogbo ìhùwàsí wọ̀nyí àti irú wọn mìíràn ni àwùjọ Yorùbá lòdì sí. Lára àwọn ìwà tó bá àwùjọ lára mu tí apàlọ́ mú kí ẹyẹlé hù nínú àlọ́ náà ni ìwà ìfẹ́ tòótọ́, ìpamọ́ra, sùúrù, ìtẹ́lọ́rùn, ìwà tútù àti ọgbọ́n inú.

         Nínú àlọ́ ‘Ìjàpá jí iṣu Ìgbín àná rẹ̀’ (Babalọlá, 1973a:107) apàlọ́ hun onírúurú èrè àṣà tó jẹ mọ́ olè jíjà mọ́ Ìjàpá àti Ìgbín àna rẹ̀ lára. Ìjàpá jèrè ìtìjú nígbà tí Ìgbín àna rẹ̀ jèrè ìwà àṣejù. Nínú àlọ́ mìíràn, ‘Òjòlá ṣahun sí Ìjàpá’ (Babalọlá, 1973b:132).  ni apàlọ́ ti hun èrè àṣà ahun síṣe pọ̀ mọ́ Ìjàpá àti Òjòlá lára  ṣùgbọ́n Ìjàpá ṣe àmúlò ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti jẹ Òjòlá lójèé; èyí tó fa òwe ‘ènìyàn ní í kọ́ni pé ká gùn, ènìyàn ní sì í kọ́ni pé ká kúrú.’ Nínú àlọ́ mìíràn ni apàlọ́ ti hun ẹ̀kọ́ àṣà àmúlò ọgbọ́n pọ̀ mọ́ Ìjàpá (kòtòǹkan ẹranko) àti erinmi (tó tóbi jù lọ láwùjọ ẹran inú omi). Nínú àlọ́ yìí, ‘Ìjàpá, Erin Òkè àti Erinmi’ (Babalọlá, 1973a:56), ni Ìjàpá ti fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ jẹ àwọn ‘atóbanti má lọ́gbọ́n nínú’ ẹranko wọ̀nyí lójèé, èyí tó bí àkànlò èdè ‘ọgbọ́n ju agbára’. Yàtọ̀ sí àwọn àpẹẹrẹ àlọ́ òkè wọ̀nyẹn, onírúurú àlọ́ mìíràn tó fi ìbáṣepọ̀ ènìyàn sí ènìyàn àti ènìyàn sí ẹranko hàn lò wà, tó sì wúlò fún ìtanijí sí àṣà tó wúlò fún ìbágbépọ̀ ènìyàn ní àwùjọ. Fún àpẹẹrẹ, nínú àlọ́ ‘Ọmọ́yọ àti Erè: (Abọ́dúndé: tó ń bọ̀ lọ́nà) ni apàlọ́ ti hua ọ̀kan-ò-jọ̀kan àpẹẹrẹ àṣà àwùjọ pọ̀ mọ́ra wọn sí. Nígbà tí alóyinlétè apàlọ́ yóò bá fi kádìí àlọ́ náà ni onírúurú ẹ̀kọ́ yóò ti hànde.

Ọnà Àlọ́ Àpagbè

         Ìtàkúrọ̀sọ tó ń wáyé láàrin apàlọ́ àti elègbè àlọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ àlọ́ òkè yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà. Ọ̀nà àtimáaṣe àkójọ àwọn elègbè orin àlọ́ ni ó jẹ́ ìdí pàtàkì kan tó fi í wáyé. Nígbà mìíràn, apàlọ́ a máa fi àlọ́ àpamọ̀ bíi mélòó kan, àrọ̀ jíjá tàbí ìmọ́ bíbú kún bátànì ìtàkúrọ̀sọ bẹ́ẹ̀.


      Ìkádìí Àló

         Ìdí àlọ́ mi rèé gbáńgbáláká

         Ìdí àlọ́ mi rèé gbàǹgbàlàkà …’

Kò ní ìtumọ̀ kan pàtó ju ète ìfọ̀rọ̀dárà, tó tún jẹ́ ìpèdè tó ya àlọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ mìíràn. Ọgbọ́n àtimú ìtàn dùn náà ni.

         Onírúurú ọnà èdè ni apàlọ́ máa ń mú lò láti hun ìtàn inú àlọ́ pọ̀, tó ń mú kí àlọ́ dùn kó sì lárinrin. Irú ọnà èdè bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ aṣàpèjúwe (àpèjúwe ẹwà ọmọkùnrin tí wọ Ọmọ́yọ lójú), àwítúnwí, àfiwé (dára bí egbin).


Ìwé Ìtọ́kasí

Abímbọ́lá, Wándé (1975), “Ìwàpẹ̀lẹ́: The Concept of Good Character in Ifá Literary Corpus.” in  Yorùbá Oral


Tradition: Poetry in Music, Dance and Drama, edited by  Wándé Abímbọ́lá, pp. 389-420. Ile-Ife, Nigeria:  Department of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo University..


Abọ́dúndé, Abíọ́dún (forthcoming), Àlọ́ Pípa Nílẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: New Horn Press Ltd.


Babalọlá, Adébóyè (1973), Àkójọpọ̀ Àlọ́ Ìjàpá (2 Vols.). Ìbàdàn: University Press Ltd.


Dorson, Richard, M. (1972), Folklore and Folklife: An Interoduction. Chicago: The University of Chicago Press.


Finnegan, Ruth (1967), Oral Literature in Africa. Clarendon: Oxford University Press.

Àwọn itọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "IPÒ ÀLỌ́ NÍNÚ AKITIYAN ÌTANIJÍ". Yoruba for Academic Purpose (in Èdè Faroesi). 2016-08-27. Retrieved 2022-12-30.