Jump to content

Ìbò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìbò[1] ni a lè pè ní ìlànà kan tí ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn gbà fìmọ̀ ṣọ̀kan, fọwọ́sowọ́pọ̀, kí wọ́n sì fi ẹnu kò lápapọ̀ láti yan ẹnìkan yálà ọmọdé ni tàbi àgbàlgba sípò kan kí ó lè máa ṣojú wọn ní ipò àṣẹ tàbí ìgbìmọ̀ tí wọ́n torí rẹ̀ yàán.[2]

Nínú ètò ìjọba àwa-arawa, oríṣiríṣi ọ̀bà ni a lè gbà dìbò láti yan ẹnikẹ́ni tí a bá fẹ́ yàn sípò. A lè dìbò nípa ìka títẹ̀ sínú àpótí ìdìbò, a tún lè dìbò nípa lílo ìlànà ìfohùn-ṣọ̀kan tàbí nípa lílo ẹ̀rọ ayélujára.[3]

Nínú ètò ìṣèlú ìjọba àwa-arawa, àwọn olùdìbò ma ń dìbò yan adarí tàbí aṣojú ará ìlú tí wọ́n bá fẹ́ sí ipò àṣẹ ìjọba láàrín ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn olùdíje sí ipò àṣẹ náà nípa kíkópa nínú ètò ìdìbò. [4]

  1. "VOTING". meaning in the Cambridge English Dictionary. Retrieved 2020-10-09. 
  2. "Voting in person, by post or proxy". Electoral Commission. Retrieved 2020-10-09. 
  3. "Nigerian Voting System Modernized". Esri. Retrieved 2020-10-09. 
  4. "Voting - GOV.UK". www.gov.uk. Retrieved 2018-06-09.