Ìdìbòyàn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ọwọ́ tó ń dìbò.

Ìdìbò jẹ́ ìpinnu àti ìgbésẹ tí àwọn ènìyàn kan gbà láti yan ẹni tí yóò ṣojú tàbí darí wọn sípò. [1]

Ìdìbò ti jẹ́ èròjà ìṣèjọba àwaarawa láti bíi sẹ́ńtúrì mẹ́tàdínlógún sẹ́yìn. A máà ń lò ó fún yíyan ni sípò aṣòfin àti ti aṣojúṣòfin àti sí Ìjọba ìbílẹ̀ pẹlú ti ẹlẹ́kùnjẹkùn. Ìgbésẹ yìí tún wọpọ ní àwọn Ilé-iṣẹ́ ńlá-ńlá àti ti aládani pẹlú àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́.

Ìlo káríayé ìdìbò gégé bí èròjà fún yíyan asojú tí ó wọpọ ní ìjọba àwaarawa ti àsìkò yìí wà ní ìyàtọ̀ sí ti ayé àtijọ́ nigbati yíyan ni sípò máa ń wáyé nípa lílosortition[2],Ẹni orí yàn tabi kádàrá nípa ṣíṣe èyí-jẹ-èyí-o-jẹ láti fi yàn wọ́n sípò.

Àtúnṣe sí ètò ìdìbò ṣe àfihàn àwọn ìgbésẹ tí wọ́n ń se fun ìrọwọ́-ìrọsẹ̀ nínú ètò ìdìbò tàbí síṣe àtúnṣe sí àwọn ètò ìdìbò tí ó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀. PsephologySífọ́lọ́jì jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa èsì ìdìbò àti àwọn ìṣirò mìíràn tí ó rọ̀mọ́ ètò ìdìbò ní pàtàkì jùlọ láti ṣírò èsì ìdìbò náà síwájú kíkéde rẹ̀.[3] Ìdìbò jẹ kókó dídìbòyàn tàbí ìdìbòyan

Láti "dìbò" túmọ sí láti Yàn tàbí ṣe "ìpinnu" àti nígbà mìíràn,wọn máa ń lo àwọn ìwé pélébé aláfọwọ́jù sínú àpótí gégébí ìdìbò(referendum).Ìlú Amẹ́ríkà ní èyí tí wọ́pọ̀ jùlọ.

Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Election definition and meaning". Collins English Dictionary. Retrieved 2021-09-30. 
  2. "Sortition". Wikipedia. 2003-08-06. Retrieved 2021-09-30. 
  3. "What does psephology mean?". Definitions.net. 2021-09-30. Retrieved 2021-09-30.