Ìgbéyàwó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìgbéyàwó

Ìgbéyàwó jẹ́ ìdarapọ̀ṣọ̀kan ọlọ́mọge tó ti bàlágà, tàbí obìnrin adélébọ̀ àti àpọ́n tàbí ọkùnrin géńdé tó tójú bó láti di ọkọ àti aya.[1] [2]

Ọjọ́ Orí Tó Tọ́ Láti Ṣe Ìgbéyàwó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nílẹ̀ Yorùbá, ọkùnrin tàbí obìnrin níláti bàlágà tàbí tójúbọ́ kí wọ́n tó lè dábàá ìgbéyàwó. Ó kéré tán, ọkùnrin tàbí obìnrin níláti tó ọmọ ọdún méjìdínlógún, kí wọ̀n tó lè lọ́kọ tàbí láyà.

Ìgbéyàwó Láyé Àtijọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láyé àtijọ́, ìgbéyàwó jẹ́ àṣà tó ní ìgbésẹ̀ tá à ń tọ̀. Àpọ́n tó bá bàlágà kì í ṣà dédé fẹ̀ ìyàwó. Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní "Bọ́mọdé bá tó lọ́kọ́, àá lọ́kọ́", láyé àtijó, bọ́mọkùnrin bá ti bàlágà láti fẹ́ ìyàwó ó ní ìgbésẹ̀ tí a ní láti gbé.[3]

Àwọn Ìgbésẹ̀ Àṣà Ìgbéyàwó Láyé Àtijọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìfojúsóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn òbí ọmọkùnrin tó bá ti bàlágà máa ń gbé láti ṣe àwárí omidan tó bá yáyì tí wọ́n yóò fi ṣaya fún ọmọ wọn. Láyé àtijó, ọmọkùnrin kì í kọnu sí omidan tó bá wù ú. Lẹ́yìn tí àwọn òbí bá ti fojú sóde, tí wọ́n sì ti rí omidan tí wọ́n fẹ́ kí ọmọkùnrin wọn fẹ́ ní ìyàwó, ìgbésẹ̀ tó kàn ní ìwádìí.

Ìwádìí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni ìgbésẹ̀ kejì nínú àṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ẹbí ọkùnrin yóò ṣe ìwádìí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ nípa ọlọ́mọge tí wọ́n tí yàn láàyò láti fẹ́ fún ọmọkùnrin wọn. Wọ́n máa ń ṣe ìwádìí irú ìdílé tí omidan náà tí wá. Ṣé ìdílé tó dára ní tàbí tí kò dára?, wọ́n a ṣe ìwádìí bóyá ìdílé náà ní àrùn tàbí àìsàn kan tí ó máa ń ṣe wọ́n. Bí ìdílé bá yege nínú àwọn ìwádìí yìí, àsìkò yìí ni wọn yóò tó pinnu láti fẹ́ omidan náà fún ọmọkùnrin wọn.

Alárenà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn ìwádìí, yínyan Alárenà tàbí alárinà ni ìgbésẹ̀ tó kàn láṣà ìgbéyàwó láyé àtijó. Alárenà ni yínyan ẹnìkan tí ó lè ṣe agbódegbà fún ọkọ àti ìyàwó-ojú ọ̀nà. Ẹni bẹ́ẹ̀ sáà máa ń jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkàn nínú àwọn tọkọ-taya-ojúọ̀nà. Òun ni àwọn méjèèjì maa rán níṣẹ́ ìfẹ́ títí títí ọkọ àti ìyàwó yóò fi mójú ara wọn. Ìdí nìyí tí Yòóbá fi máa ń paá lówe pé "bí ọkọ àti ìyàwó bá mọjú ara wọn tán, alárenà á yẹ̀ a"

Ìjọhẹn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni ìgbésẹ̀ tí ẹbí ọkọ ìyàwó-ojúọ̀nà máa ń gbé láti ríi pé àwọn ẹbí ìyàwó-ojúọ̀nà gba láti fi ọmọbìnrin wọn fọ́kọ tí ó wá tọrọ rẹ̀. Ó dàbí ètò mọ̀mínmọ̀ọ́.

Ìdána[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn Ìjọ́hẹn, ìdána ni ètò tó kàn nínú ayẹyẹ àṣà ìgbéyàwó láyé àtijó. Ìdána ni sísan àwọn ẹrù àti owó-orí tí ẹbí ìyàwó-ojúọ̀nà bá kà fún ọkọ-ojú ọ̀nà láti san.[4] [5]

Ẹkún-Ìyàwó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni ayẹyẹ ìkẹyìn tí ìdílé ìyàwó máa ń ṣe fún omidan tí ó ṣetàn láti ṣe ìgbéyàwó kí ó tó forí lé ilé ọkọ rẹ. Omidan tí ó fẹ́ lọ ilé ọkọ ni ó máa ń sun ẹkùn ìyàwó. Omidan yìí a máa sún ẹkùn yìí láti dárò bí ó ṣe fẹ́ fi ilé bàbá rẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ilé ọkọ. Ẹkún ayọ̀ ni èyí ẹkún ìyàwó máa ń jẹ́.

Ìgbéyàwó Gangan[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni ayẹyẹ tó kẹ́yìn láṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ó máa ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọkọ-ojúọnà bá ti san gbogbo ẹrù ìdána. Àwọn ìdílé ìyàwó-ojú ọnà yóò wa sètò láti sìn ìyàwó lọ ilé ọkọ rẹ. Ọ̀kan-ọ̀-jọ̀kan àwọn ẹbí ìyàwó àti ọkọ á máa wúre fún ìyàwó àti ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó. Jíjẹ àti mímu máa ń pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu.

http://edeyorubarewa.com/a%E1%B9%A3a-igbeyawo/

https://www.latestnigeriannews.com/news/6214514/asa-igbeyawo-ati-oju-ise-alarina-laye-atijo.html

Pàtàkì Ìbálé Nínú Àṣà Ìgbéyàwó Láyé Àtijọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìbálé ni bíbá ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀ gbé nílé láì tí bá ọkùnrin kankan sùn rí kí ó tó lọ ilé ọkọ. Ó jẹ́ àṣà tí ó gbajúmọ̀ tí ó sìn máa ń buyì kún ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé. Ìwúrí ni ó máa ń jẹ́ fún ọkọ ìyàwó tí ó bá bá ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé nílé. Lálẹ́ ìgbeyàwó, àwọn òbí ọkọ yóò tité aṣọ funfun sí orí ibùsùn nínú yàrá ọkọ ìyàwó-àṣẹ̀ṣẹ̀gbé láti fi gba ìbálé rẹ̀. Iyì ńlá ni fún àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ rẹ bá bá nílé, ó túmọ̀ sí wípé ọmọbìnrin náà kò tíì mọ ọkùnrin rí. Odidi agbè ẹmu tàbí odidi páalí ìsáná, ìyàn àti ọbẹ̀ tí ó dára ní àwọn ẹbí ọkọ ìyàwó yóò gbé lọ fún àwọn òbí ìyàwó laarọ kùtùkùtù ọjọ́ kejì láti fi dúpẹ́ lọwọ wọn wípé odidi ni wọ́n bá ọmọ wọn, èyí ni oúnjẹ ìbálé, ìyàwó yóò tún gba owó ìbálé tíì ṣe ọ̀kẹ́ méjì lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀. Ohun ìtìjú àti ìbànújẹ́ ni ó máa ń jẹ́ fún ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé tí ọkọ rẹ̀ kò bá bá nílé àti ìdílé rẹ̀. Kódà, ònínàbì àti òníranù ni Yòóbá máa ń ka irú ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé bẹ́ẹ̀ sì.

À ń tẹ síwájú sìi lórí ọ̀rọ̀ yìí

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "What Is the Definition of Marriage?". The Spruce. Retrieved 2019-11-13. 
  2. "Traditional Marriage Rites in Yoruba Land: How It Is Done". Nigerian Infopedia. 2019-09-20. Archived from the original on 2020-10-01. Retrieved 2019-11-14. 
  3. "ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ – TRADITIONAL MARRIAGE". The Yoruba Blog (in Èdè Latini). 2018-12-30. Retrieved 2019-11-14. 
  4. "How It's Done In Yoruba Land". Pulse Nigeria. 2014-10-02. Archived from the original on 2020-02-10. Retrieved 2019-11-14. 
  5. "Asa Igbeyawo Ati Oju Ise Alarina Laye Atijo". Stella Dimoko Korkus.com (in Èdè Catala). Retrieved 2019-11-14.