Ìjàpá l’óyun ijángbòn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ààlọ́ Ìjàpá àti Yannibo aya rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlo ó!!

Ààlò!

Ààlọ́ mi dá fìrìgbagbò, ó dá lórí Ìjàpá àti Yánníbo aya rẹ.[1]

Ìjàpá fẹ́ ìyàwó rẹ̀ nígbàtí ó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọn. Orúkọ rẹ̀ a maa jẹ́ Yánníbo. Yánníbo rẹwá pupọ l’óbìnrin, ó pupa fòò, eyín ẹnu rẹ̀ funfun nigín nigín dada. Iyàwó ìjàpá singbọnlẹ̀, kò sí ohun ti o wọ̀ (bíi aṣọ, bata ati bẹẹ bẹẹ lọ) ti ko níí yọ ni ara rẹ. O ma n mú ìrìn wu ni.[2]

Yánníbo rẹ'wa lootọ, bẹẹ ni ó tún fi ìwà tútù bíi àdàbà kún ẹwa rẹ̀. O laanu ọmọnikeji rẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ t'ọmọde t'agba. Ṣùgbọ́n Yannibo kò rí ọmọ bí, Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba tí ó bá rí obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn.  Yáníbo ko dúró lásán, ó tọ Babaláwo lọ láti ṣe ãjo bí òhun ti le ri ọmọ bí.

Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo[3].  Babaláwo kìlọ̀ fún Ìjàpá gidigidi wípé õgùn yí, obìnrin nìkan ló wà fún, pé kí o maṣe tọwò.  Ìjàpá ọkọ Yáníbo ṣe àìgbọràn, ó gbọ õrùn àsèjẹ, ó tọ wò, ó ri wípé ó dùn, nítorí ìwà wobiliki ọkánjúwà, o ba jẹ àsèj̀ẹ tí Babaláwo ṣe ìkìlọ̀ kí ó majẹ. Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú.  Yorùbá ni “ohun ti a ni ki Baba má gbọ, Baba ni yio parí rẹ”.  Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ:

Orin ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀, 

Alugbirinrin 2ce

Òògùn to ṣe fún mi lẹ́rẹkan, Alugbinrin

Tóní nma ma fọwọ́ kẹnu, Alugbinrin

Tóní nma ma fẹsẹ kẹnu,  Alugbinrin

Mo fọwọ kan ọbẹ̀, mo mú kẹnu, Alugbinrin

Mofẹsẹ kan lẹ mo mu kẹnu, Alugbinrin

Mobojú wo kùn o ri gbẹndu, Alugbinrin

Babaláwo mo wá bẹbẹ̀, Alugbinrin

Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀.  Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú[4].

Ẹ̀kọ́ inú ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlọ́ yíì kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú.  Ìtàn Yorùbá yi wúlò lati ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ti o nwa owó òjijì nípa gbígbé õgùn olóró mì lati kọjá lọ si òkè okun/Ìlúòyìnbó lai bìkítà pé, bí egbògi olóró yí ba bẹ́ si inú lai tètè jẹ́wọ́, ikú ló ma nfa.  Ìtàn nã bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí.

ÀWỌN ÌTỌ́KASÍ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
  2. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  3. https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. https://dokumen.tips/documents/akojopo-alo-ijapa-babalola?page=51