Ìlù
Ìlù jẹ́ ọ̀kan nínú ohun èlò ìdárayá láàárín àwọn Yorùbá. Ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a lè pín ìlù sí. Ìlù ìpín kìn-ín-ní wà fún Ẹ̀sìn Ìbílẹ̀. Ìpín kejì wà fún Ayẹyẹ Lóríṣiríṣi. Ìpín kẹta jẹ́ Ìlù ìgbàlódé tí a ń lù fún àṣeyẹ tàbí fún ìgbádùn lásán. Ní ìgbà mìíràn a lè lò nínú ìlù tó wà fún ẹ̀sìn níbi àṣeyẹ tàbí kí á lọ àwọn ìlù ayẹyẹ níbi àjọ̀dún ìbílẹ̀. Èyí já sí pé ìlò wọn wọnú ara.[1]
Ìlù Ṣíṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Tí Yorùbá bá fẹ́ ṣe ìlù, igi rìbìtì ni wọn ń kọ́kọ́ gbé tí ihò yóò wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, wọn yóò wá awọ ẹran bò ó lójú kí wọn tó fi èèkàn tàbí ọsán dè é létí yíká. Díẹ̀ nínú àwọn ìlù tí a fi igi àti awọ ẹran ṣe nì wọ̀nyí: Bàtá, Ìpèsè, Àgẹ̀rẹ̀, Gbẹ̀du, Ìgbìn, Dùndún, Bẹ̀ǹbẹ́ àti Gángan. Àwọn ìlù mìíràn wà tí a fi odidi ìkòkò àti awọ ẹran ṣe Ọrùn ìkòkò àti awọ ẹran ni a fi ń ṣe Sákárà ní tirẹ̀. Igbá, agbè pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ni a fi ń ṣe àgídìgbo àti móló. Èso ìdòrò àti owó ẹyọ tí a so mọ́ agbè ni ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀.
Bí a tí ń lu àwọn Ìlù yìí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Púpọ̀ nínú àwọn ìlù wọ̀nyí ló jẹ́ ojú méjì ni wọ́n ní, ọ̀nà méjèèjì la sì ti ń lù wọ́n. Dùndún, Bẹ̀ǹbẹ́, Gángan àti bàtá jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ìlù tí ó lójú méjì. Ọ̀nà kan ṣoṣo là ń gbà lu Sákárà àti Ìgbìn. Ọwọ́ la fi ń lu àràn, ìkòkò, igbá àti agbé. Awọ pàlàbà tó nípọn díẹ̀ tí à ń pè ní ọsán ni a fi ń lu bàtá. Ọ̀pá àti kọ̀ǹgọ́ ni a fi ń lu àwọn ìlù tó kù. Ṣùgbọ́n ìka ọwọ́ ni a fi ń ta móló, àgídìgbo àti sáńbà. Fífọn là ń fọn fèrè tí a sí ń lu agogo.
Ẹ jẹ́ kí a wo àwọn oríṣi ìlù lábẹ́ ìpín kọ̀ọ̀kan àti àkókò tí à ń lò wọ́n.
* Ẹ̀sìn
-Bàtá: Ṣàngó, Egúngún, Ògún
-Ìpèsè àti Àràn: Ifá
-Àgẹ̀rẹ̀, Tòròmagbè, Ekùtù àti Agogo: Ògún
-Gbẹ̀du: Ọba, ìjòyè, ọdún orò
-Ìgbìn: Ọbàtálá
* Ayẹyẹ
-Dùndún, Sákárà, Gángan: ìgbéyàwó, ìṣílé
-Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀: oyè jíjẹ
-Bẹ̀ǹbẹ́, Apinti: Ìkómọjáde
-Igbá, Agbé: Ìyọra ewu ìsìnkú
* Ìgbàlódé
-Àgídìgbo, Sẹ́lí, Sáńbà, Jùjú, Móló, Gìtá, Àpàlà: fún oríṣi àṣeyẹ bí i ìsìnkú àgbà, ìkómọjáde abbl.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Olúdáre Ọlájubú- Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá ISBN 978-139-023-9