Ìlú Òbè-nlá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ÌTÀN ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ ÌLÚ ÒBÈ-ŃLÁ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olúbákin ni orúkọ ẹni àkọ́kọ́ tí ó jẹ Olúbo ní òde Ugbo. Ìtàn sọ pé àtọmọdọ́mo Sẹ̀pẹ̀lúwà tí ó jẹ́ Awùjalẹ̀ ìkejìdínlógún ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú ni Olúbákin jẹ́. Olúbákin àti àbúrò rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ bàbá ni wọ́n jọ dunpò Awùjalẹ̀ ìkẹtàdínlógójì ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú lẹ́yìn tí Ọba Morógbèsọ̀, Awùjalẹ̀ ìkejìlélogojì. Òródùdùjoyè ni orùkọ àbúrò olúbákin tí wọ́n jọ du oyè náà. Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, “Ohun gbogbo lọ́wọ́ orí, orí la fi ń mú ẹran láwo” Òródùdùjoyè tí ó jẹ́ àbúrò ni àwọn afọbajẹ yàn dípò Olúbákin tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n gẹ́gẹ́ bí i Àwùjalè tuntun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Bí àbúrò Olúbákin ṣe gun orí oyè kò ṣàìdá họ́ùhọ́ù àti yànpọnyánrin sílẹ̀ láàárin àwọn méjèèjì.

Olúbákin gbé ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ dìde sí àbúrò rẹ̀ pẹ̀lú èrò àti gba ìjọba padà sọ́wọ́ araarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni ti oyè náà tọ́ sí. Àṣẹ̀yìnwá-àṣẹ̀yìnbọ̀, ìṣẹbọ-ìṣoògùn, bí a ti lá á rì í láyé. Àwọn ọmọ ogun ọlọtẹ tí Olúbákin gbé díde kò lè sẹ́gun ti àbúrò rẹ̀ Òródùdùjoyè. Látàrí èyí, ó pinnu láti fi ìlú sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀. Kàkà kí kìnnìún ṣe akápò ẹkùn kálukú á máa dọ́dẹ ṣẹ.

Gbogbo ìsapá àti akitiyan Òródùdùjoyè láti tu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lójú já sí pàbó lẹ́yìn tí ó rò pé ó sàn kí wọ́n yanjú ọ̀ràn náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ibùdó àkọ́kọ́ tí Olùbákin tẹ̀dó sí lẹ́yìn tí ó kúrò ní Ìjẹ̀bú ni wọ́n ń pè ní Èhì títí di òní yìí. Lẹ́yìn tí ó kúrò níbẹ̀, ó forí lé ìha ìlà-oòrùn Ugbò, ó sì tẹ̀dó sí ibi tí wọ́n ń pè ní ode-Sèpèlúwà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tẹ̀dó tán. Ọ̀gangan ibí yìí ni ọ̀kan lára àwọn ọmọ Olúbákin ti a mọ̀ sì Ọ̀rọ́tọ́ ti papòdà. Ó ṣeni láàánú pé Ọ̀rọ̀tọ̀ kò bí ọmọ kankan sáyé kí ó tó re ibi àgbà ń rè. Nítorí náà bàbá rẹ̀ pinnu láti yí orúkọ òde-sèpèlúwa padà sí ti ọmọ rẹ̀ ti ó kú síbẹ̀. Láti ìgbà náà wà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Òde-Ọ̀rọ́tọ̀ títí o fi di òní yìí.

Olúmọ̀dàn tí òun náà jẹ́ ọmọ Olúbákín ni ó ṣalábápàdé ọmọbìnrin kan létí òkun níbi tí wọ́n ti lọ máa ń ṣe ohun kan tí wọ́n ń pè ní ‘ìpé’ lóko. Ìsẹ̀lẹ̀ yìí gan-an ni ó padà wá yọrí sí bí Olúbákin àti Ọ̀rọ́nmàkin ṣe gbà láti jọ máa ṣe ìjọba pọ̀ ní Ugbo níbi tí Ọranmàkin ti wà sáájú kí Olúbákin tó dé sí àgbègbè náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlájà Ugbò. Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún Olúmọ̀dàn ọmọ Olúbákin pé àwọn kan tún wà ní tosí, tí àwọn tí ó wà ní Òde-Ọ̀rọ́tọ̀ kò mọ̀ nípa wọn tẹ́lẹ̀. Ọjàludé ni orúkọ ọmọbìnrin ti Olúmọ̀dàn bá pàdé ń jẹ́. Ọmọ Olúgbò tí a pè ní Òrọ́nmakin lẹ́ẹ̀kan ni. Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí yan ara àwọn lọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n kò sí ọmọ láti inú ìbáṣepọ̀ wọn jálẹ̀ gbogbo ọdún tí àwọn méjèèjì fi wà lórí erùpẹ̀. Ìbáṣepọ̀ Olúmọ̀dàn àti Ọjàludé ni ó mú àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín Olúbákín àti Ọ̀rọ́nmakin wáyé. Wọ́n kó ijọba pọ̀, nitori pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí èrò púpọ̀ ní àgbègbè náà nígbà yẹn. Nígbà tí Olúbákin jẹ Olubo ní Òde Ugbò, àwọn ọmọ rẹ̀ kan àti lára àwọn tí ó tẹ̀lé e wá láti Èhin kò kúrò ní Òde-Ọ̀rọ́tọ̀. Lẹ́yìn ikú Olúbákin, Olúmọ̀dàn ọmọ rẹ̀ ni ó jẹ Olúbo tẹ̀lé e. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kọjá lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Olúbákin tí wọ́n wà ní Ọ̀rọ́tọ̀ pinnu láti wásẹ́ ẹja pípa síwájú ìhà-ila-oòrùn òde-ọ̀rọ́tọ̀ ìgbàyẹn, látàrí àkíyèsí rẹ̀ pé àwọn ẹyẹ ńlá-ńlá máa ti apá ìhà ibẹ̀ yẹn wá. Á ní láti jẹ́ pé omi ńlá kan wà lápá ibẹ̀ ti ẹja pọ̀ sí, nítorí àwọn ẹyẹ máa ń dọdẹ ẹja ní irú àgbègbè bẹ́ẹ̀. Akíkanjú okùnrin ni kúlájolú jẹ́. Ó kó àwọn kan mọ́ra wọ́n sì bẹ̀ rẹ̀ ìrìn-àjò si apá ìlà-oòrún òde-ọ̀rọ́tọ̀. Nígbẹ̀yìn wọ́n ṣàwárí omi náà tí ó kún fún ògìdigbo ẹja ńláńlá. ‘Agbárà’ tàbí ‘ọrà’ ńlá ti àwọn ẹja wọ́ sí yìí ni wọ́n ń pè ni “ebe” láàárín àwọn Ìlàjẹ ìgbà yẹn. Kúlájolú tẹ̀dó sí ibi tuntun yìí ti wọ́n fi ìrísí sọ lórúkọ. Láti inú ‘èbè-ńlá’ ni Òbè-ńlá ti súyọ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Bí ibùdó àwọn àtọmọdọ́mọ Olúbákin ti ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ sí i, wọ́n yàn láti fi òpin sí ìjọba alájùmọ̀ṣe tí Olùbákin dá sílẹ̀ pẹ̀lú Olúgbo, wọ́n kórajọ sí Òbe-ńlá, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ibùdo Olúbo gẹ́gẹ́ bí i ọba aládé.

Iwe ti a yewo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • ÀGBÉYÈWÒ ORÍKÌ OLÚBO ÒBÈ-ŃLÁ NỊ́ ILẸ̀ ÌLÀJẸ APÁ KAN NÍNÚ ÀṢEKÁGBÁ OYÈ B.A (HONS.) YORÙBÁ

YUNIFÁSÍTÌ ỌBÁFẸ́MI AWÓLỌ́WỌ̀ ILÉ-IFÈ, NIGERIẠ LÁTI ỌWỌ́ OWÓYẸLÉ OYÈKÀNMÍ KEEN OSÙ Ọ̀PẸ̀, 2007