Jump to content

Ìmọ-ìṣègùn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìmọ̀-ìṣègùn jẹ́ ìmọ̀ tàbí ìwádìí ohun tí ó ń fa àìsàn, àti ọ̀nà tí a lè gbà ṣe ìtọ́jú irúfẹ́ àìsàn tàbí kí á ṣe àmójútó rẹ̀, tàbí kí á pèé ní ìmọ̀ tí fi ń dá àìsàn lọ́wọ́ kọ́ àti àwọn oríṣiríṣi ìpalára tí ó lè fà sínú àgọ́ ara . Ẹ̀kọ́ sayẹbinsi tí ó rọ̀gbà yí ìlò àwọn oògùn. Óunjẹ ati àwọn egbògi míràn ká. Ó jẹ́ ògun tàbí àwọn ìtọ́jú sí àìsàn. Nǹkan tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àtúnṣe àrùn ara. [1]

Ìmọ̀ ìṣègùn jẹ́ ìmọ̀ àti ọ̀nà ọgbọ́n nípa ṣíṣé ìtójú àti ìmú pàdà-sípò tàbí ìràpadà àlááfià fún ènìyàn nípa àṣàrò, ìwádìí ohun tí ń mú àìsàn wá àti ìtọ́jú fún àwọn aláísàn.

Iṣé ìmọ̀ ìṣègún ti ìgbà ìsisìyí hàn púpọ, bí ẹ̀kọ́ ìwòsàn àti gbogbo ìwádìí ìmọ̀ ìṣègùn fún àwọn àìsàn tí wọn ṣèsẹ̀ jade. Ìpínlẹ̀ ìmọ̀ ìṣègùn lẹ̀ní, ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀ka ìmọ̀ ìṣègùn, ìwádìí ìṣègùn àti egbògi oníṣègùn, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwádìí yìí, ìpèníjà tí dé bà àìsàn àti ìpalára.

Ìtàn nípa ìmò isegun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn àpẹrẹ tàbí àwòrán nínú ìṣègùn níi àwọn ìlú púpọ̀ tí nló adánidá orísun bí ohun eléwé tutu (lílo ẹ̀gbogi), ìpín ẹranko àti àwọn nǹkan tí ó wà nínú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ní gbogbo ìlú ìwọ̀-oòrùn, ìmọ̀ wàà lòri ẹ̀sìn àti uana èsìn níi pá tí iṣègùn. Ní àwọn àyíká múràn wọ́n ńlò ìmọ̀ ìṣègùn tí ó tan mọ ẹ̀s`in, àṣà irírí àti adánidá orison nínú ìmọ̀ ìṣègùn.

Àwọn ẹ̀sìn mí gbagbọ pé àwọn oriṣa ní ẹ̀mí, nipe ẹ̀mí wá nínú ohun gbogbo àti wipe gbogbo ènìyàn ló ní agbára ogùn àti àfọ̀ṣẹ, èyí ló tún fún wọn ní agbáara à tí wa ìmọ̀ kún ìmọ̀ ìṣègùn.

Ìlú Géreékìì ni ìmọ̀ ìṣègùn ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀ń ìmọ̀ ìṣègùn jẹ́ ìtẹ̀síwájú tuntun láti dá èyì tí ò pọ̀jú lọ́ nínú ìmọ̀ ìṣègùn nípa ìlo ìlànà ìmọ̀ àti ìṣàjọ àwọn ẹ̀rí pẹ̀lú ìdàgbásòkè àwọn ọ̀págun èyí tí ó fọ́nká sí àwọn òlùtọ́ jú aláísàn.

Ìlò ìmọ̀ ìṣègùn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ní ìmọ̀ bí ẹ̀ní ìpìlẹ̀ àti ọ̀nà tí à ń gbà lo àwọn ìmọ̀ ìṣègùn yíì ní àkójọpọ̀. Pẹ̀lú ọgbọ́n inú ati ìdájọ́ ilé-ìwòsàn láti fi mọ ìwòsàn tí o tọ́.

Agbede sí ìmọ̀ ìṣègùn ni dọ́kítà aláísàn jẹ́, onímọ̀ ìṣègùn yíí gbọ́dọ̀ ní ìbátan pẹ̀lú ènìyàn tí ó ní àìsàn láti fi ran lọ́wọ́. Àwọn oníwòsàn miiràn náà má ń dá àjọ̀ṣepọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn àti ẹ̀ni tí wọ́n ń tọ́jú láti fi mọ wan dada.

Ìwúlò ìmọ̀ ìṣègùn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ṣe ìwádìí àìsàn Fún ìtọ́ju àti ìlosí fún àwọn aláísàn Láti mọ́ ohun tí o n fa àìsàn Fún ìmọ̀ nípa lílò àwọn ògùn Láti dín iye àwọn tí wọ́n ń ṣe àìsàn kù.[1]

Gbogbo nǹkan tí ó bá ti wà fún ìtọ́jú àìsàn yaálà ní mímu, lílò, fi para tàbí fi sùn, ni a ń pè ní oògùn. Ìmọ̀ ìṣègùn jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ tí ó ń ṣe ìgbìmọ̀ ìtọ́jú, ìwádìí àti àfíhàn ohun tí ó ń fa àìsàn àti ìtọ́jú rẹ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 Scarborough, Harold (2022-03-21). "medicine - Definition, Fields, Research, & Facts". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2022-03-23.