Ìnáwó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Sé Yorùbá bò wón ní “Se bó o ti mo eléwàà sàpón. Ìwòn eku nìwòn ìté.” Won a sì tún máa pa á lówe pé “ìmò ìwòn ara eni ni ìlékè ogbón nítorí pé ohun owó mi ò tó ma fi gògò fà á, í í já lu olúwarè mólè ni” áyé òde òní, àwon òdó tilè máa ń dásà báyìí pé “dèédèé re, ìgbéraga ni ìgbérasán lè.” Wón máa ń so èyí fún eni tí ó bá ń kojá ààyè rè ni. Gégé bí òro ogbón kan se wí pé “ni àtètékóse ni òrò wà,” béè náà ni ètò ti wà fún ohun gbogbo láti ìpilèsè wá. Ètò ní í mú kóhun gbogbo rí rémú. Olorun ògá ògo to da ayé. Ó fi eranko sígbó {àwon olóró}. Ó tún fi eja síbú. Ó fi àwon eye kan sígbó. Ó fi àwon mìíràn sílé. Àdìmúlà bàbá tó ju bàbá lo tún fi ààlà sáààrin ilè, omi òkun, àti sánmò. Ohun gbogbo ń lo ní mèlò-mèlo. Bàbá dá àwa omonìyàn kò fi ojú wa sí ìpàkó. Kò fi esè wa sórí kí orí wá wà lésè. Elétò lOlórun gan-an.

Kíni ètò? Ètò jé ònà tí à ń gbà láti sàgbékalè ohun kan tàbí òpòlopò nnkan lójúnà àti mú kí ó se é wò tàbí kó se é rí tàbí kó dùn ún gbó sétí. A sèdá orúko yìí gan-an ni. Ohun tí a tò ní í jé ètò. Èwè, ìnáwó ni ònà tàbí ìwà wa lórí bí a se ń náwó. Ohun pàtàkì ni láti sètòo bí a óò se máa ná àwon owó tó bá wolé fún wa. Ní àkókó ná, èyí yóò jé kí á mo ìsirò oye owó tó ń wolé fún wa yálà lósè ni o tàbí lósù, bí ó sì se lódún gan-an ni. Bákan náà, yóò tún mú kó rorùn fún wa láti mo àwon ònà tí owó náà ń bá lo. Síwájú síi, ètò yóò ràn wá lówó láti le ní ìkóra-eni-níjàánu lórí bí a se ń náwó wa. Bí a bá ti mú ìsàkòtún tán, tí a tún mú ìsàkòsì náà, ìsàkusà ni yóò kù nilè. Tí a bá yo ti ètò kúrò nínú ojúse ìjoba pàápàá sí ará ìlú, eré omodé ni ìyókù yóò jé. Gbogbo àwon eka ìjoba pátá-porongodo ló máa ń ní àgbékalè ìlànà tí won yóò tèlé lati mo oye owó ti won n reti ati eyi ti won óò na bóyá fún odidi odún kan ni o tàbí fún osù díè. Èyí ni wón n pé ní ‘ÈTÒ ÌSÚNÁ’ Ìdí nìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo tolórí-telémù, tònga-tònbèrè ki kúlukú ní ètò kan gbòógì lónà bí yóò se máa náwó rè. Yorùbá bò wón ní, “eku tó bá ti ní òpó nílè, kì í si aré sá. Bí a bá ti se àlàkalè bí a óò se náwo wa yóò dín ìnákùùná kù láwùjo wa. Ìnáwó àbàadì pàápàá yóò sì máa gbénú ìgbé wo wá láwùjo wa. Mo ti so léèèkan nípa àwon eka ìjoba métèètà orílè èdè yìí tí wón máa ń sètò ìnáwó won. Àwon wo ló tún ye kó máa sètò ìnáwó? Àwon náà ni àwon òsìsé ìjoba, àwon onísòwò, àwon omo ilé-ìwé, níbi àseye. Àwon òsìsé ìjoba gbodò sètò ìnáwó won kó sì gún régé. Ìdí ni pé, èyí ni yóò jé kí owó osù won tó í ná. Eni tó ń gba egbèrún méwàá náírà lósù tí kò sì fi òdiwòn sí ìnáwó rè nípa títò wón léseese le máa rówó sohun tó ye láàákò tó ye nígbà tí ó bá ti náwó rè sí àwon ohun mìíràn tó seése kó nítumò sùgbón tí kì í se fún àkókò náà.

Irú won á wá má ráhàn owó tósù bá ti dá sí méjì tàbí kí wón je gbèsè de owó osù mìíràn. Síwájú sí i, àwon onísòwò gbódò máa sètò to jíire lórí ìnáwó won. Nípa síse èyí, won óò ni ànfààní láti mò bóyá Oláńrewájú ni isé won tàbí Oláńrèyìn. Níbi tí àtúnse bá sì ti pon dandan, “a kì í fòdù òyà sùn ká tó í nà án ládàá,” won kò nì í bèsù bègbà, won óò sì se àtúnse ní wéréwéré. Àwon omo ilé-ìwé gan-an gbodò mò pé ká sètò ìnáwó eni kì í sohun tó burúkú bí ti í wù kó mo. Gégé bí omo ilé èkó gíga, béèyàn bá gbowó fún àwon orísirísi ìnáwó láti ilé lórí èkó eni, ó seése kí irú eni béè máa ná ìná-àpà tó bá dé ààrin àwon elegbée rè. Irú won ló máa ń pe òsè tí wón bá ti ilé lódò àwon òbí won dé ní ‘Ose ìgbéraga’ Èyí kò ye omolúàbí pàápàá. Ó sì ń pè fún àtúnse. Síse ètò tó gúnmó lórí ònà tí à ń gbà náwó kò pin sí àwon ònà tí mo sàlàyé rè sókè yìí. Mo fé kó ye wá pé a le sètò ìnáwó wa níbi àwon orísisi ayeye bí ìsomolórúko [tàbí ìkómójáde], ìgbéyàwó, oyè jíje, ìsílé, àti ìsìnkú àgbà àti béè béè lo. Yóò ràn wá lówó láti fi bí a se tó hàn wá ká le mo ohun tí a óò dágbá lé níbi irúfé àseye tí a bá fé í se. Nípa béè a ò ní í sí nínú àwon tó máa ń pa òwe tó máa ń mú kí won kábàámò nígbèyìn òrò. Òwe won ni, “rán aso re bí o bá se ga mo.” Èyí tí won ì bá fi wí pé “rán aso re bí o bá se lówóo rè sí.” Bí eni tó ga bá rán aso rè ní ‘bóńfò’ bó se lówó mo ni, kò sì fé í sàsejù. Irú eni béè le ti mò pé alásejù péré ní í té. Bí a bá wá fé láti sètò ìnáwó wa, ó ye ká mò pé ìtòsè ló lÒyòó, Oníbodè lo làààfin, enìkan kì í fi kèké síwájú esin. Iwájú lojúgun í gbé. Ìnáwó tó bá se kókó jùlo tó sì ń bèèrè fún ìdásí ní kíákíá ló ye ká fi síwájú bí a se ń tò ó ní eseese. Bí a bá wá kíyèsí pé ètò tí a là sílè ti ju agbára wa lo, e jé ká fura nítorí pé akéwì kan wí pé:

“E fura óò!

E fura óò!

Páńsá ò fura

Páńsá jááná

Àjà ò fura

Àjá jìn

Ońlè tí ò bá fura

Olè ní ó ko o…”


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]