Ìròyìn Oṣù Kọkànlá 2011
Ìrísí
- Mariano Rajoy jẹ́ dídìbòyàn bíi Alákóso Àgbà ilẹ̀ Spéìn.
- Mario Monti di Alákóso Àgbà ilẹ̀ Itálíà lẹ́yìn ìfipòsílẹ̀ Silvio Berlusconi.
- Ellen Johnson Sirleaf jẹ́ títún-dìbòyàn bíi Ààrẹ ilẹ̀ Làìbéríà.
- Silvio Berlusconi fipòsílẹ̀ bíi Alákóso Àgbà ilẹ̀ Itálíà nítorí rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ gbèsè orílẹ̀-èdè náà.
- Lucas Papademos di Alákóso Àgbà ìjọba òjijì orílẹ̀-èdè Gríìsì.
- Ajaẹ̀sẹ́ ará Amẹ́ríkà Joe Frazier (fọ́tò) saláìsí, ó jẹ́ ọmọ ọdún 67.
- Paul Biya gba ìbúra bíi Ààrẹ ilẹ̀ Kamẹrúún fún ìgbà kefà.
- Michael D. Higgins borí nínú ìdìbòyàn ààrẹ ní orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Irẹlándì.