Jump to content

Ìró àti Bùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Iró ati Bùbá jẹ́ orúkọ aṣọ tí ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn Obìnrin ẹ̀yà Yorùbá ní apá ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà má a ń wọ̀ [1] . Ní ìbẹ̀rẹ̀, aṣọ yìí jẹ́ onípele márùn-ún, lára rẹ ni ìró èyí tí ó tóbi jù lọ tí wọ́n máa ń ró mọ́ ìbàdí. Nígbà tí Bùbá jẹ́ ẹ̀wù tí wọ́n ń máa ń wọ̀ lé orí ìró. Gèlè ní tirẹ̀, ni wọ́n máa ń wé sí orí. Wọ́n sì máa ń ró ìpèlé lé ori ìró kí ẹwà ìmúra wọn lè yọ dára dára . Wọ́n sì máa ń so ìborùn lé èjìká . Láfikún , orísìírísìí asọ èyí tó bá wu ni ni wọ́n le fi rán ìró àti bùbá , ó lè jẹ́ aṣọ òfì , léèsì, àǹkárá, dàńsíkí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ .

  1. "11 Traditional African Clothing That Identifies African Tribes At A Glance". African Vibes. 2022-07-23. Retrieved 2023-02-01.