Ìtàn ìsèdálẹ̀ Ilé-Ifẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ìlú Ilé-Ifẹ̀ jẹ́ ìlú tí Òrìṣà Bàbá Ṣìgìdì tí mo fẹ́ sọ ìtàn rẹ̀ ti wá. Èyí ló mú mi yà bàrá láti sọ ní ṣókí nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ló ti wà lórí ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilè-Ifẹ̀ bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ àwọn òǹkọ̀wé àti òǹpìtàn ló ti fi èrò wọn hàn lórí ìtan ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bíòbákú (1955) dábàá wí pé a dá ìlú Ilé-Ifẹ̀ sílẹ̀ láàrin ọ̀rùndún kéje àti ìkẹ́jọ (seventh & eighth centuries). Jeffrey. (1958:21-25) Ṣe àfojúsùn pé ìlú náà tí yẹ kó di ńlá láti ọ̀rùndún kọkànlá (eleventh century). Ìwòye àwọn méjéèjì fì ìmọ̀ ṣòkan pé Ilé-Ifẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ kan gbòógì láààrin òrùndún kéje sí ìkejìlá (seventh to twenth centuries) àti pé Ilé-Ifẹ̀ ti wà ní ìletò kékèèkéé tẹ́lẹ̀ rí kó tó di pé ó wá para pọ̀ dí odidi tí ó wà lónìí yìí. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò pẹ̀lú olóyè Ọbadio, ó ní ìtàn Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oríṣun. Ìdí nìyí tí a fí ń pe “Ilé-Ifẹ̀ ní ìlú ibi tí o júmọ́ ti ń mọ́ wá”

Lékèè gbogbo rẹ̀, ọ̀nà mẹ́rin pàtàkì nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn òǹkọ̀tàn ti kọ sílẹ̀ tí wọ́n sì gbé yẹ̀wò. Cordellia (2006:33-36), sọ fún wa nínú ìtàn àkọ́kọ́ pé odùduwà fi ẹ̀wọ̀n rò kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn igba irúnmọlẹ̀ (200 deties) láti ọ̀run láti wá tẹ Ilé-Ifẹ̀ dó. Nígbà tí ìtàn kejì sọ fún wa pé Odùduwà àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ kúrò láti ìlú Mẹ́kà. Nínú ìrìnàjò wọn, olúkúlùkù bẹ̀rẹ̀ sí níí tẹ̀dó sí ojú ọ̀nà, nínú èyí tí Kòkòbírí ní Òkè Ọya wà. Odùduwà kò àwọn ẹmẹ̀wa rẹ̀ yóòkù dé Ilé-Ifẹ̀ ní ìgbẹ̀yíngbéyín. Bẹ́ẹ̀ sì ni Odùduwà bá àwọn àgbà awo ní Ilé-Ìfẹ̀ tí Odùduwà sì ja ìjà àjàborí tí ó sì borí lọ́wọ́ wọn. (Biobaku 1955 : 88).

Èrò kẹ́ta yìí jẹ èrò Elúyẹmí tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ilé-Ifẹ̀, Ó gbà pé ìlà oòrùn tí àwọn ènìyàn ń tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí oríṣun Yorùbá ni “Òkè-Ọrà”. Elúyẹmí (1986 :16) ní Odùduwà àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ sọ̀kalè láti òkè wá sí ìsàlẹ̀ láti wá ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí wọn lè fi dáko pẹ̀lú ohun èlò ìgbàlódé. Òkè Ọrà ní ìlẹ̀ tí ó lọ́ràá tí Odùduwà àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ rí láti fi dáko, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ẹni tí wọ́n bá níbẹ̀. Isichei (1982 :132) fi hàn nínú èrò kẹ́rin nígbà tí ó fara mọ́ ọn pé Ifẹ̀ ti wà kí ó tí di wí pé Odùdudwà tí ó jẹ́ jagunjagun akọni àti Bàbáńlá Yorùbá wáyé. Kí Odùduwà tó wáyé àti kí ìlú Ilé-Ifẹ tó fìdí múlẹ̀ ni àwọn ìletò mẹ́tàlá ti wà káàkiri agbègbè náà tí òkọ̀ọ̀kan wọn sì ní Baálẹ̀. Àwọn ìletò mẹ́tàlá yìí ló para pọ̀ di ìletò ọ̣̀kan ṣoṣo tí òkọ̀ọ́kan Baálẹ̀ àwọn ilètò wọ̀nyí ṣì ń ṣe olùdarí àpapọ̀ lóòrèkóòrè. Ìletò náà ní wọ̀nyìí: Parakin, Ìráyè, Ìdìta, Òkè-Ọrà, Ọmọlogun, Iwìnrìn, Ìmójùbí, Ijùgbẹ̀, Ìdó, Ìlórómù, Ìlọràn, Odin, àti Òkè Awo. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé púpọ̀ nínú àwọn orúkọ wọ̀nyìí ló sì wà títí di òní gẹ́gẹ́ bí àdúgbò tàbí agbègbè lábẹ́ Ilé-Ifẹ̀. Òranfẹ̀ Baálẹ̀ Òkè Ọrà ni ó kọ́kó ṣe Baálè àpapọ̀ ìletò wọ̀nyí nígbà tí Ọ́bàtálá ṣe Baálẹ̀ tó gbẹ̀yìn. Ní àkótán, gbogbo èrò mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí mo ti mẹ́nu bà ní sókí náà ló sọ nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Ilé-Ifẹ̀. Nínú èrò tèmi, ní àfikún, ìtàn àtẹnudénu ni ìtàn àwọn ará Ilé-Ifẹ̀ ó kún fún ẹ̀kọ́ àti àṣà, bí ó ti wù kí ó rí ó yẹ kí á sọ pé irú ìtàn bẹ́ẹ̀ kò ní àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìjìnlẹ̀ ìtàn.