Jump to content

Ìyípadà ojú-ọjọ́ ní Somalia

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìyípadà ojú-ọjọ́ ní Somalia tọ́ka sí àwọn ìyípadà ojú-ọjọ́Somalia àti ìdáhùn tí ó tẹ̀le, ìyípadà àti àwọn ìlànà ìdínkù ti orílẹ̀-èdè náà.

Somalia jẹ́ orílẹ̀-èdè kejì tí ó ní ìpalára ti ojú-ọjọ́ ní àgbáyé. [1] Orílè-èdè náà ti rí ìlosókè nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojú-ọjọ́ ńlá láti ọdún 1990, pẹ̀lú àwọn ọ̀gbẹ̀ẹlẹ̀ mẹ́ta pàtàkì láti ọdún 2010, ìkún-omi ti ń wáyé àti àwọn eṣú déédé díẹ̀ si tí ó ba àwọn irúgbìn jẹ́. Ní ọdún 2080, àwọn ìwọ̀n òtútù tí ó nírètí yóò dìde nípasẹ̀ ìwọ̀n 3.4 Celsius, pẹ̀lú àfikún 152 àwọn ọjọ́ gbígbóná púpọ̀ fún ọdún kan (níbití àwọn ìwọ̀n òtútù tí ó pọ̀ jùlọ yóò kọjá ìwọ̀n 35 Celsius). [2]

Ìyípadà ojú-ọjọ́ ni a nírètí láti fi igara pàtàkì sórí omi tó jẹ́ ọ̀wọ́n tẹ́lẹ̀ àti àwọn ohun ògbìn láàrín orílẹ̀-èdè náà, tí ó ń halẹ̀ mọ́ aàbò orílẹ̀-èdè àti ìdúróṣinṣin ètò-iṣelu. [3]

Àwọn ipa tí ìyípadà ojú-ọjọ́ kó lórí agbègbè àdáyébá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn awòṣe ojú-ọjọ́ ṣe àsọtẹ́lẹ̀ pé láìpẹ́-ọjọ́ agbègbè Ilà-oòrùn Áfíríkà ṣeé ṣe láti ní ìrírí àwọn ìyípadà ní oju-ọjọ bíi ooru, àwọn àyípadà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àti ipa ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gajù, àti òjòrírọ̀ tí ó dínkù, àti àwọn ìṣípòpadà ọlọ́jọ́pípẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpele kíkún okun. .

̀̀Àwọn ìwọ̀n òtútù àti àwọn ìyípadà ojú ọjọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orílẹ̀-èdè Somalia máa ń ní ooru, àkókò méjì ni wọ́n ní fún ojo. Àwọn ìwọ̀n òtútù tó burú ní Somalia jẹ́ ọ̀kan tí ó ga jùlọ ní àgbáyé. Àwọn ipò gbígbóná borí ní gbogbo ọdún, pàápàá ní gúúsù iwọ̀-oòrùn nítòsí ààlà sí orílẹ̀-èdè Ethiopia, níbi tí àwọn ìwọ̀n òtútù àpapọ̀ lọ́dọọdún kọjá 29 °C. Àkókò òjò àkọ́kọ́ jẹ́ láti Oṣù Kẹrin sí kẹfà, àti àkókò òjò kejì láti Oṣù Kẹwàá sí Kejìlá. Òjòrírọ̀ ọlọ́dọọdún ní àgbègbè gbígbóná àti ọ̀gbẹlẹ ní àríwá kò tó 250 mm ó sì dínkù sí ohun tí kò tó 100 mm ní àríwá ilà-oòrùn náà. Ìlú-òkè ti àárín gba láàárin 200 sí 300 mm ti òjòrírọ̀, nígbà tí ó pọ̀ si ní apá Gúsù sí ìwọ̀n 400 sí 500 mm ti òjò ọlódọọdún. Gúsù ìwọ̀-oòrùn àti àwọn ẹkùn àríwá iwọ̀-oòrùn gba òjòrírọ̀ púpọ̀ jùlọ, pẹ̀lu àròpin láàárin 500 àti 700 mm. [4]

Ojú-ọjọ́ ti yípadà ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn: [5]

  • Ìdàgbàsókè ìwọ̀ntúnwọ̀nsí ti wà láti 1 sí 1.5°C láti ọdún 1991,
  • Ojú ojó tó burú jù ní ipa lórí orílẹ̀-èdè náà, pẹ̀lú ọ̀gbẹlẹ̀ ńlá ní ọdún 2011 àti 2017.
  • Àwọn ọ̀gbelè tí ó gbòòrò, àwọn ìṣàn omi ṣíṣàn àti àwọn ìjì líle, ti di lóòrèkóòrè ní ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sẹ́hìn. [6]

Àwọn awòṣe àsọtẹ́lẹ̀ fihàn pé [7]

  • Ọ̀gbẹlẹ̀ àti àwọn ìṣàn omi ṣeé ṣe láti pọ̀ si ní agbára àti lóòrèkóòrè.
  • Láì sí ìdánilójú, àwọn awòṣe ṣe akànṣe pé òjò oṣòòṣù yóò pọ̀ si díẹ̀ láti Oṣù Kẹsàn-án sí Oṣù kejìlá láàárin ọdún 2040-2060.
  • Ìwọ̀n òtútù àpapọ̀ ni a nírètí láti pọ̀ si láàárin 1-1.75°C láàárin 2040-2060, àti ìrètí pípọsi ti 3.2 sí 4.3°C ní 2100.

Ìpele òkun ni a wò pé yíò dìde pẹ̀lú ìdánilójú gíga lábẹ́ àwọn ojú ìṣẹ̀lẹ̀ ìtújáde iwájú. Àwọn awòṣe ojú-ọjọ́ agbedeméjì ní àfojúsùn gígasi òkun ti 12 cm títí di ọdún 2030, 20 cm títí di 2050 àti 36 cm títí di ọdún 2080 lábẹ́ RCP2.6 bí àkàwé sí ti ọdún 2000. Lábẹ́ RCP6.0 (àwọn ìtújáde gòkè si ní 2080, lẹ́hìn náà ó wálẹ̀), ìrètí wà pé ìpele òkun máa ga si nípa 11 cm títí di ọdún 2030, 21 cm títí di ọdún 2050 àti 42 cm títí di ọdun 2080.[8][9]

Ìwọ̀n ìpele òkun tí a sọtẹ́lẹ̀ ṣe ìdẹ́rùbà àwọn ìgbésí ayé ti àwọn agbègbè etí òkun, pàápàá ní gúsù Somalia, pẹ̀lú olú-ìlú Mogadishu ti orílẹ̀-èdè, àti pé ó lè fa kí iyọ̀ wọ àwọn ọ̀nà omi etí òkun àti àwọn ibi ìfomipamọ́. [10]

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wíwà omi jẹ́ aìdánilójú gán-an lákòókò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtújáde. Láìsí ìṣàrò ìdàgbàsókè àwọn olùgbé, àwọn awoṣé ṣe àfihàn ìlosókè díẹ̀ ní ìlà pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ òjò ọjọ́ ́iwájú. Tí a bá gbèrò ìdàgbàsókè olùgbé tí à ń retí, àpapọ̀ wíwà omi fún ènìyàn kọ̀ọ̀kan lè já sí ìdajì ní 2080 lábẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtújáde RCP2.6 àti RCP6.0, bótilẹ̀jẹ́pé aìdánilójú ní àyíká ìsín-ìn àti ọjọ́-iwájú wíwà omi ga púpọ̀jù. [11]

Ipa lórí ènìyàn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orílẹ̀-èdè Somalia ti ní ìfojúsọ́nà láti kó ipa púpọ̀ nípasẹ̀ àwọn ipa tí ìyípadà ojú-ọjọ́ àti ojú ọjọ́ tó burújù. ND Gain index rẹ̀ jẹ́ ti 172 ní ọdún 2020, [12]èyí tó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè kejì tó ní ìpalára jùlọ sí ìyípadà ojú-ọjọ́ àti ìpèníjà àgbáyé mìíràn, àti orílẹ̀-èdè ọgọ́fà tí ó ṣetán jùlọ fún ìgbaradì ìdojúkọ.

Àwọn ipa ìyípadà ojú-ọjọ́ ní Ìlà-oòrùn Áfíríkà ni ìfojúsọ́nà láti já sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipa tààrà àti aìṣe-tààrà tí ó kan ààbò oúnjẹ nítorí aápọn ìwọ̀n òtútù gíga àti àwọn ìyípadà nínú ṣíṣẹlẹ̀ àti agbára ti àwọn ògbelè.[13][14]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Vulnerability rankings | ND-GAIN Index". gain-new.crc.nd.edu. Retrieved 2023-03-21. 
  2. "The best 'glimmers of hope' against climate change in Somalia". 2022. 
  3. ISSAfrica.org (2018-04-06). "Climate change is feeding armed conflict in Somalia". ISS Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-03-22. 
  4. "Climate Risk Profile Somalia" (PDF). 
  5. "USAID/SOMALIA COUNTRY DEVELOPMENT COOPERATION STRATEGY CLIMATE ANALYSIS" (PDF). 
  6. "The Impact of Climate Change on Peace and Security in Somalia: Implications for AMISOM". ACCORD (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-03-21. 
  7. "World Bank Climate Change Knowledge Portal". climateknowledgeportal.worldbank.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-03-22. 
  8. "Climate Risk Profile Somalia" (PDF). 
  9. "World Bank Climate Change Knowledge Portal". climateknowledgeportal.worldbank.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-03-22. 
  10. El-Shahat, S., El-Zafarany, A. M., El Seoud, T.A. & Ghoniem, S.A., “Vulnerability assessment of African coasts to sea level rise using GIS and remote sensing,” Environmentl, Development and Sustainability, vol. 23, pp. 2827-2845, 2021.
  11. "Climate Risk Profile Somalia" (PDF). 
  12. "Somalia | ND-GAIN Index". gain-new.crc.nd.edu. Retrieved 2023-03-21. 
  13. "Climate Change Adaptation in EAST AFRICA" (PDF). USAID. 
  14. "World Bank Climate Change Knowledge Portal". climateknowledgeportal.worldbank.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-03-22.